NÍ YÀJÓYÀJÓ Òṣìṣẹ́ tàbí àlejò tí kò bá gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 kò ní wọ ọ́fíìsì lọ́jọ́ Ajé tó ń bọ̀ – FCTA

Copyright: Getty Images

Iroyin kan n sọ pe awọn alaṣẹ ijọba agbegbe Derbyshire
County lorilẹede Gẹẹsi ko ni yọ awọn ẹgbẹrun mẹwaa agadagodo ifẹ to wa lori irin afara Weir bridge lọwọ yii.

Wọn ni bi igbesẹ bẹẹ yoo ba tilẹ waye, yoo fẹrẹẹ to ọdun kan
si asiko yii, eleyi si ti n mu inu ọpọ awọn eeyan dun si igbesẹ ijọba agbegbe
Derbyshire county naa.

Lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin lawọn eeyan ti gba aṣa fifi
agadagodo kọ afara naa to wa lagbegbe Bakewell ni Derbyshire, yala lati ṣajọyọ
awọn ololufẹ wọn tabi awọn eeyan wọn to jade laye.

Amọṣa ni ibẹrẹ ọdun yii ni igbimọ iṣakoso ijọba agbegbe
Derbyshire County ti n jẹ ọrọ naa lẹnu pe awọn fẹ yọ awọn agadagodo naa kuro
lara afara fun iṣẹ atunṣe ti wọn fẹ ṣe lori afara ọhun.

Amọṣa, wọn ti wa yi ohun pada bayii pe awọn ti da ọwọ igbesẹ
naa duro na ti ọpọlọpọ awọn eeyan to ti ti agadagodo ifẹ mọ afara naa n
sọ pe o n mu ki okan awọn damu to si tun jẹ ijakulẹ ọkan fun awọn.

Arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Richard Young; to jẹ ọkan
lara awọn to n fọn rere lori igbesẹ ijọba lori afara naa ṣalaye pe iroyin gbaa ni fun wọn.

Ọgbẹni Young to jẹ ilumọọka oniṣowo to ti fẹyin ti lagbegbe Bakewell pẹlu ti ṣi oju opo
ayelujara Facebook kan lati maa fọnrere ki wọn lee fi awọn agadagodo naa silẹ bi o ṣe wa.

O ni isunsiwaju naa yoo fun un ni asiko to to lati mọ oun to kan lati ṣe.

O ni lootọ awọn mọ
pataki atunṣe afara naa, ṣugbọn ifẹ ati oniruuru itan ati iṣẹlẹ ti muni lọkan
gidi lo so rọ mọ awọn agadagodo naa.

O tun ni igbagbọ oun ni pe awọn agadagodo to wa nibẹ yooti to ẹgbẹrun mewaa nitoripe kaakiri agbaye
lawọn eeyan ti n wa sibẹ wa fi agadagodo ifẹ tiwọn naa ha afara ọhun.