Fídíò, Mo sọ fún Dókítà pé èmi ò lè gé ọyàn mi, pé ṣọ́ọ̀ṣì yóò fi àdúrà ṣẹ́gun àìsàn jẹjẹrẹ ọmú mi – Abisayo Fakiyesi, Duration 8,59

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Abisayo Fakiyesi breast cancer survivor: ‘Gbogbo irun orí, ti abẹ́, abíyá pátá ló fá lọ, ahọ́n àti èékáná mi dúdú!

“Mo sunkun nigba ti mo ji ti mo ri i pe wọn ti ge ọyan mi pẹlu iṣẹ abẹ”.

Bi Abisayo Fakiyesi ṣe bori aisan jẹjẹrẹ ọyan jẹ iyalẹnu toripe ọpọlọpọ ni kii gbagbọ pe awọn le bori rẹ lai pada gba ibẹ ku pẹlu gbogbo owo ti wọn yoo ṣi na fun itọju ati irora ti wọn yoo la kọja.

Ko tún kí n ṣe ẹẹkan ṣoṣo ni Abisayo ni aisan jẹjẹrẹ ọmu o, ẹẹmeji ọtọọtọ̀ tun ni tirẹ.

“Lẹ́ẹ̀kan síi, mo tún rí kókó ọyàn bíi 5 nínú ọyàn tuntun tí wọ́n ṣe fún mi! Ǹkan 14 ni dókítà kó jáde lára mi níléèwòsàn India”.

Ohun tójú rẹ̀ rí kí ọyàn tuntun tí wọ́n ṣe àti ti ẹgbẹ́ kejì tó jọra wọn kii ṣe kekere. Koda o ṣalaye bi ẹni tó ń fẹ́ nígbà náà ṣe kọ̀ ọ́ sílẹ̀, “ọjọ tí mo sọ fún un ni mo gbúròó rẹ̀ mọ”.

“Gbogbo irun orí, abẹ́, abíyá mi pátá ló fá lọ, ahọ́n mi dúdú, èékáná mi dúdú”.

Abisayo Fakiyesi to bori jẹjẹrẹ

O ṣalaye fun BBC Yoruba ninu ifọrọwerọ bi o ṣe jẹ iyalẹnu pe o ri i bori lẹni to ti gbagbọ pe iku ni yoo gbẹyin oun gẹgẹ bo ṣe gbẹyin iya rẹ to ni aisan kan naa.

Bakan naa, nigba ti ọna ati rii daju pe o bori aisan yii lootọ di lyin ti wọn ti ge ọyan apa osi rẹ, o ni lati ya ẹnu sọrọ ni ibi iṣẹ rẹ ti wọn si dide iranwọ fun un ati iranwọ to ri gba lọdọ awọn ẹbi ati ọrẹ rẹ to fi mọ awọn ẹlẹyinju aanu.

Aisan yii kan naa lo pa iya rẹ nigba to wa lẹni ọdun mẹtalelaadọta ti Abisayo si jẹ ọmọ ọdun mẹẹdogun nigba naa.

Ko tilẹ mọ pe bi oun ṣe kere to nigba naa, aisan ọhun le wa oun naa kan ti yoo ko o.

Iranwọ awọn ẹlẹyinju aanu lo fi ribi lọ si orilẹede India to si ba idunu pada bọ tori wọn ba a ṣe to ri ọyan mii gbe si apa osi rẹ nile iwosan to lọ ni India.