Pásítọ̀ David Ibiyeomie, adarí ìjọ Salvation Ministry tò dàwó sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Pasitọ David Ibiyeome

Oríṣun àwòrán, David Ibiyeome

Awọn adari ṣọọṣi to wa loke ile to dawo ni ipinlẹ Delta, Salvation Ministries ti sọrọ lori iṣẹlẹ naa.

Pasitọ ati oludasilẹ ijọ naa, David Ibiyeome lo fi atẹjade kan sita loju opo Instagram rẹ eyi ti awọn adari ijọ naa fọwọ si.

Atẹjade ọhun sọ pe ijọ Salvation Ministries gbọ si iṣẹlẹ ile to dawo lọjọ ikkanla oṣu kini ọdun 2022 ni agbegbe Okpanam, Asaba ni ipinlẹ Delta ninu ile alaja kan ti ẹka ijọ naa ti jẹ ayalegbe ni ile to wa loke patapata.

“Ijọ wa ti n ṣiṣẹ pẹlu awọn alaṣẹ ti ọrọ kan lati ṣewadii ohun to fa iṣẹlẹ ile didawo yii”.

Ile alaja to dawo

Oríṣun àwòrán, Channels TV

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ijọ Salvation Ministries ni ọkan awọn ati adura awọn lọ sọdọ awọn eeyan to ku atawọn idile to fara gba ninu iṣẹlẹ naa ati pe awọn yoo ṣe gbogbo atilẹyin to ba tọ lasiko ti wọn n ṣe iwadii yii.

Ohun ti Ọlọpaa ipinlẹ Delta ti fi sita ni pe ni titi di alẹ ana ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, wọn ti ri eeyan mejidinlogun yọ kuro labẹ ile naa ti eeyan mẹta si farapa gidi gan.

Nigba to fi di owurọ yii, agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Delta, DSP Bright Edafe sọ fun BBC pe eeyan mẹta lo ti ku nibi iṣẹlẹ naa ti wọn lee fi aridaju rẹ han.

DSP Bright sọ pe kii ṣe ootọ pe eeyan mẹwaa lo ku gẹgẹ bi awọn oniroyin kan ṣe n sọ ọ o si fi kun un pe akitiyan ṣi n lọ lati doola awọn eeyan nibi iṣẹlẹ ọhun tori awọn oṣiṣẹ pajawiri ṣi wa nibẹ ti wọn n ṣiṣẹ.

O ṣalaye wipe ijọ naa n ṣe isin lọwọ loke ile naa ni nigba ti ile naa dede dawo amọ o ni ile naa ko dawo taara lori gbogbo awọn eeyan naa tori naa awọn kan ribi jade ninu ile naa.

Ọwọ irọlẹ ọjọ Iṣẹgun ti ijọ naa n ṣe eto awẹ ati adura ọlọjọ mọkanlelogun.

Ile iṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Delta, ile iṣẹ panapana ati ọlọpaa lo wa nibi iṣẹlẹ naa ti wọn si n wadii lati mọ boya awọn eeyan ṣi ha si abẹ ile naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ