Àwọn tálákà ló gbọ́dọ̀ jẹ àǹfàní ₦5bn tí ìjọba àpapọ̀ fẹ́ fún àwọn gómìnà jùlọ – àwọn onímọ̀

Owó náírà àti epo bẹntiróòlù

Oríṣun àwòrán, NNPC

Ní ọjọ́bọ̀ ni ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà kéde láti fún àwọn ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní bílíọ̀nù márùn-ún náírà láti fi pèsè ohun ìdẹ̀kùn fún àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ wọn nítorí bí ìjọba ṣe yọ ìrànwọ́ orí epo.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Borno, BabangaNA Zulum ló gbé ìkéde náà jáde lkyìn ìpàdé ìgbìmọ̀ tó ń mójútó ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Láti ìgbà tí ìjọba ti kéde yìí ni àwọn ènìyàn ti ń bèèrè pé ọ̀nà wo ni ìjọba fẹ́ gbà láti ri pé gbogbo àwọn ènìyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ló jẹ àǹfání owó yìí.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Gbade Ojo, tó jẹ́ onímọ̀ nípa ètò òṣèlú nígbà tó ń bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀ ní ó yẹ kí ìjọba ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan wo nǹkan tó bá jẹ́ ìpèníjà ní ìpínlẹ̀ wọn, kí wọ́n sì mójúto kí ó le jẹ́ ìgbádùn fún gbogbo ènìyàn.

“Bí ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ṣe máa pín owó rẹ̀ máa yàtọ̀ síra wọn nítorí pé ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra wọn, ohun tí ará Eko ń fẹ́, ó yàtọ̀ sí ti ará Oyo, ó yàtọ̀ sí ti ará Kwara.”

Ọ̀jọ̀gbọ́n Ojo ní tí àwọn ìjọba bá fẹ́ kí owó náà kan gbogbo àwọn ará ìlú ni láti ri pé àwọn òṣìṣẹ́, àwọn òṣìṣẹ́-fẹ̀yìntì àtàwọn ọlọ́jà ló jẹ́ àǹfàní nínú owó náà.

Ó ní tí wọ́n bá fẹ́ kí àwọn ará ìlú jẹ́ àǹfàní náà dáradára, ó yẹ kí ìjọba wo àwọn lẹ́gbẹ́lẹ́gbẹ́ láti lo owó náà fún nǹkan tó máa jẹ́ àǹfàní àpapọ̀ ẹgbẹ́ náà.

“Àwọn ẹgbẹ́ alájẹṣẹ́kù, ẹgbẹ́ ránṣọránṣọ, ẹgbẹ́ mọkálíìkì, àwọn ẹgbẹ́jẹgbẹ́ lọ máa rọrùn jù torí kò sí bí wọ́n ṣe fẹ́ na owó sí ará ìlú, iye ènìyàn tó ń gbé ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan pọ̀ ju owó náà lọ.”

Ọ̀jọ̀gbọ́n Dhikirulahi Yagboyaju tí òun náà jẹ́ onímọ̀ nípa ètò òṣèlú ní níṣe ló yẹ kí ìjọba Nàìjíríà wo àwòkọ́ṣe àwọn orílẹ̀ èdè tó ti ìgbésẹ̀ báyìí ṣáájú bíi Indonesia àti Mexico.

Ó ní níṣe lọ yẹ kí àwọn ìjọba dojú owó náà kọ àwọn tó jẹ́ tálákà paraku, tí wọn kò rí oúnjẹ oòjọ́ jẹ lásìkò kí ìdẹ̀kùn lè báwọn.

Àwọn gómìnà nílò láti ná owó sí ìgbèríko

Nígbà tó ń tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ojo ní àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ gbọ́dọ̀ ná nínú owó náà láti fi mójútó àwọn ìgbèríkò.

Ó ṣàlàyé pé ohun tó fa ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ ni bí àwọn àgbẹ̀ kò ṣe máa rí èrè oko wọn dé ìgboro lásìkò àti pàápàá pé ọ̀wọ́n gógó tó ti bá owó epo ti fà á kí àwọn ọkọ̀ gbówó lórí.”

Ọ̀jọ̀gbọ́n Ojo fi kun pé ọ̀pọ̀ àwọn ìlú tó wà ní ìgbèríko yìí ni nǹkan tí wọ́n nílò yàtọ̀ síra, tó jẹ́ wí pé nǹkan tí oníkálùkù wọn ń fẹ́ kò jọ ara wọn.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Yagboyaju ní ó yẹ kí ìjọba wá ọ̀nà láti kàn sí irú àwọn ènìyàn ní ìgbèríko nípa lílo àwọn ẹgbẹ́ tàbí ilé ìjọsìn láti ṣe àwárí àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀.

Ó fi kun pé ìjọba yẹ kó ní ọ̀nà láti fi gba orúkọ àwọn ènìyàn sílẹ̀ láti ara ilé ìjọsìn wọn tàbí àwọn ẹgbẹ́ tí wọ́n bá wà.

Ọmọ ìlú ni àwọn olọṣèlú náà, tí ìjọba bá fún àwọn náà lówó kìí ṣe èèwọ̀

Ojo tẹ̀síwájú pé ìbẹ̀rù àwọn ènìyàn pé owó yìí kò ní tẹ gbogbo àwọn ará ìlú lọ́wọ́, pé àwọn olóṣèlú ló máa pín owó náà mọ́ ara wọn lọ́wọ́ tó sì ní kò léèwọ̀ tí àwọn náà bá gbà níbẹ̀ nítorí ará ìlú ni àwọn náà.

Ó ní ohun tó yẹ kí ìjọba mójútó ni pé kìí ṣe gbogbo owó yìí ló bọ sọ́wọ́ àwọn olọṣèlú àti pé gbogbo àwọn ará ìlú lo jẹ àǹfàní rẹ̀.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Yagboyaju ní ọ̀pọ̀ àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú ló mọ gbogbo ẹsẹ̀ kùkú tí wọ́n máa ń polongo ìbò lọ lásìkò ètò ìdìbò nítorí náà wọ́n ní ìmọ̀ kíkún nípa àwọn ènìyàn tó nílò owó náà jùlọ.

Ó ṣàlàyé pé ewu tó wà nínú lílo ẹgbẹ́ òṣèlú ni pé wọ́n lè má fẹ̀ ẹ́ fún àwọn tí kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ́ wọn àmọ́ tí ìjọba bá ti jẹ́ kó di mímọ̀ pé gbogbo ènìyàn ló ní ẹ̀tọ́ sí owó náà, kò ní sí wàhálà.

Bákan náà ló ní ṣíṣe àmúlò àwọn ìjọba ìbílẹ̀ yóò jẹ́ ọ̀nà gbòógì láti lè jẹ́ kí àwọn ènìyàn jẹ àǹfàní ètò náà.

Ó rọ àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ láti má kò ó owó yìí àtàwọn nǹkan mìíràn tí ìjọba àpapọ̀ kó fún wọn lati pin fún ará ìlú pamọ́ kí ọ̀rọ̀ náà má dàbí ti ìgbà COVID – 19 tí àwọn ará ìlú lọ ń já ibi tí àwọn gómìnà yìí kó àwọn nǹkan ìrànwọ́ pamọ́ sí.

“Ohun tí ìjọba àpapọ̀ ṣe nípa gbígbé ètò gba ọ̀dọ̀ àwọn gómìnà dára púpọ̀, níṣe ló yẹ ki àwọn gómìnà yìí gbé gba ọ̀dọ̀ àwọn ìjọba ìbílẹ̀ kí ó lè dé ẹsẹ̀ kùkú lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tó nílò owó yìí jùlọ.” Yagboyaju parí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Ìjọba àpapọ buwọ́lu N5bn gẹ́gẹ́ bí ìrànwọ́ “palliative” fún ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan àti Abuja

Aarẹ Tinubu

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti buwọlu iye owo biliọnu marun naira fun ipinlẹ kọọkan lorilẹede Naijiria to fi mọ olu ilu orilẹede yii iyẹn ilu Abuja.

Ijọba ni ki wọn fi owo yii ra ounjẹ lati pin fun awọn ti ko rọwọ họri ni gbogbo ipinlẹ kowa wọn.

Gomina ipinlẹ Borno, Babangana Zulum lo fi eyi lede ni ile Aarẹ nilu Abuja ni kete ti igbimọ alaṣẹ fun eto ọrọ aje pari ipade nibẹ.

Lafikun si ọrọ owo yii, Zulum ṣalaye pe ijọba apapọ tun ṣe agbekalẹ apo irẹsi to kun ọkọ akẹru marun fun gbogbo awọn gomina ipinlẹ mẹrindinlogoji.

Gomina Zulum ṣe e ni alaye wipe gbogbo gomina kọọkan lo gba aṣẹ lati ra apo irẹsi ẹgbẹrun lọna ọgọrun, apo agbado ẹgbẹrun lọna ogoji ati ajilẹ.

O ni ijọba fún wọn ni ida mejilelaadota gẹgẹ bi ẹ̀bùn owó amọ ida mejidinlaadọta to ku jẹ gẹgẹ bii owoya.

Bakan naa, wọn ti gbe igbimọ kan silẹ laarin awọn gomina lati ṣamojuto biba ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, NLC sọrọ lori igbesẹ tuntun yii eyi to waye latari yiyọ owo iranwọ ori epo bẹntiroo kuro eyi to ti n pa awọn ọmọ Naijiria lara lati ọjọ ti ijọba ti yọ ọ.

Yatọ fun iṣoro ọrọ aje to n koju orilẹede Naijria lasiko ti ọrọ yiyọ owo iranwo epo bẹntiroo ṣẹlẹ, igbimọ alaṣẹ to n ri si ọrọ aje tun ṣe ijiroro lori ipenija abo paapaa awọn ikọlu to waye laipẹ yii ni iha Ariwa orilẹede.

Igbakeji Aarẹ, Kashim Shettima lo dari ipade ọhun pẹlu awọn gomina to fi mọ awọn eeyan mii tọrọ kan.

Ipade yii n waye ni koi tii ju wakati diẹ lọ ti ileeṣẹ ipọnpo NNPC ni awọn ya owo pajawiri biliọnu mẹta Dollar latọdọ Banki AFREXIM fun sisan gbese owo epo rọbi.