NÍ YÀJÓYÀJÓ Abdulrasheed Bawa ti wà ní àhámọ́ wa fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò – DSS

Copyright: PRESIDENCY

Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kejìlá oṣù Kẹfà ọdún 2023 ni Ààrẹ Bola
Ahmed Tinubu buwọ́lu àbá ẹ̀yáwó fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ dòfin.

Òfin yìí ti fi ààyè gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Nàìjíríà tó bá wà
nílé ẹ̀kọ́ gíga Yunifásitì, ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe (polytechnic) tàbí ilé ẹ̀kọ́
olùkọ́ni láti yá owó láì ní san èlé kankan lórí rẹ̀.

Abẹnugan ilé aṣojúṣòfin, Femi Gbajabiamila ló tẹ pẹpẹ àbá
náà síwájú ilé, tí ilé sì buwọ́lù ú nínú oṣù karùn-ún.

Pẹ̀lú ìbuwọ́lù Ààrẹ, òfin yìí ti fàyè gba ìdásílẹ̀ ilé
ìfowópamọ́ ètò ẹ̀kọ́ Nàìjíríà.

Ilé ìfowópamọ́ yìí ni yóò máa ṣe àmójútó bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́
yóò ṣe máa gba owó náà.

Akẹ́kọ̀ọ́ tó bá fẹ́ yá owó yìí máa lọ fún àyẹ̀wò láti fìdí rẹ̀
múlẹ̀ pé ó lẹ́tọ̀ọ́ láti yá owó náà.

Gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ tó bá wà ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ní Nàìjíríà ló
ní àǹfàní láti yá owó yìí láti fi san owó ilé ẹ̀kọ́, ra ìwé tàbí láti fi ṣe iṣẹ́
ìwádìí.

Ọmọ Nàìjíríà tó bá fẹ́ lọ kẹ́kọ̀ọ́ nílẹ̀ òkèrè kò ní àǹfàní
sí ètò yìí.

Kí ènìyàn tó lè ní àǹfàní láti gba owó yìí, owó tó ń wọlé
fún ẹbí ẹni náà gbọ́dọ̀ dín ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà.

Ẹnikẹ́ni tó bá ti jẹ ilé ìfowópamọ́ náà lówó tẹ́lẹ̀ kò ní ní
àǹfàní láti gba owó mìíràn àyàfi tó bá san tilẹ̀ tó bá gbà.

Akẹ́kọ̀ọ́ tó bá tún ti lọ́wọ́ nínú ṣíṣe èrú ìdánwò kò ní ní
àǹfàní sí owó yìí.

Lẹ́yìn ọdún méjì tí ènìyàn bá ti sin ìjọba tán ni òfin là
kalẹ̀ pé yóò san owó náà padà.

Nínú owó oṣù tí ẹni náà bá ń gbà lẹ́yìn tó bá parí àgùnbánirọ̀
ni wọ́n yóò ti máa yọ ìdá mẹ́wàá títí tí owó ọ̀hún máa fi pé.

Ẹni tó bá kọ̀ láti san owó rẹ̀ tó bá yá le fi ẹ̀wọ̀n ọdún
méjì gbára tàbí kí ó san owó ìtanràn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà tàbí kí
ó ṣe méjéèjì.