Èèyàn 160 ni agbébọn ti pa lásìkò ìjọba Tinubu, èyí burú jáì – Amnesty

Aworan

Oríṣun àwòrán, Amnesty International

Ajọ ajafẹtọ ọmọniyan, Amnesty International ti fi aidunnu wọn lori bi awọn agbebọn ṣe n ṣekupa awọn eniyan, ti ijọba ko si ri ọna abayọ si.

Ajọ naa ni laarin ọjọ diẹ ti wọn burawọle fun aarẹ tuntun, Bola Ahmed Tinubu, eniyan ọgọjọ ni ẹmi wọn ti sọnu ninu iṣẹlẹ naa.

Amnesty International ni se ni awọn agbebọn n pa awọn eniyan si, ti iye awọn eniyan to n ku latari iṣẹlẹ naa si n peleke si.

Ninu ọrọ rẹ, adari ajọ naa lorilẹede Naijiria, Isa Sanusi ni kede ti wọn bura wọle fun aarẹ Tinubu ni May 29, ni awọn agbebọn ṣekọlu si awọn eniyan ni igberiko ti wọn si pa eniyan mẹtalelọgọfa kaakiri Naijiria.

Sanusi fikun un pe awọn eniyan wọnyii ti sọ ireti nu nitori pe ko si ohun ti wọn le ṣee si awọn to n ṣekọlu si wọn.

Nitori naa ni ajọ naa sẹ kesi ijọba tuntun naa lati ji giri lati da abo bo awọn araalu lọwọ awọn agbebọn to n ṣekọlu si wọn.

Ajọ naa ni ijọba gbọdọ wa opin si iṣẹlẹ naa nitori wọn ti kuna lati da abo bo awọn araalu.

Wọn ni titi da asiko yii, ko i tii si ọna abayọ si eto aabo to dẹnukọlẹ.

Lara ohun to fa ifaṣẹyin ni pe wọn ni ijọba kọ lati ṣe iwadii finifini lori awọn iṣẹlẹ naa lọna ati da abo bo awọn araalu.

Bakan naa ni ajọ Amnesty International ṣalaye bi awọn agbebọn yii ṣe n ṣọṣẹ wọn.

Ni Ọjọ Kọkanla, Osu Kẹfa ni awọn agbebọn pa eniyan mọkanlelogun ni ipinlẹ Plateau.

Bakan naa ni ajọ naa ni saaju ọjọ naa ni awọn agbebọn pa eniyan marunlelọgbọn ni ilu Katako, ki wọn to wa pa eniyan mẹtala ni agbegbe Kushrki ni Ọjọ Kẹwaa, Osu Kẹfa.

O ni eniyan ọgọrun lo ku ninu osu karun un nikan ni ipinlẹ Benue.

Ajọ Amnesty International ni laarin Ọjọ Karundinlogun si ikẹtadinlogun, eniyan to le ni ọgọrun ni wọn pa ni agbegbe Mangu ni ipinlẹ Plateau.

Laarin Oṣu Kejila si Osu Kẹrin, ọdun yii naa ni wọn ni awọn agbegbọn pa eniyan to le ni ọgọrun ni Guusu agbegbe ipinlẹ Kaduna.