‘Àwọn ọ̀rẹ́ ìyàwó mi, tí a jọ ṣe ‘Hook Up’ rí, ló ń gbà á nímọ̀ràn láti kọ̀ mí sílẹ̀’

Portable ati Ashabi Simple

Oríṣun àwòrán, Others

Gbajumọ olorin, Habeeb Okikiola, ti ọpọ mọ si Portable ti sọrọ lori obinrin to tun ṣẹṣẹ bimọ fun.

Ọsẹ to kọja ni Portable ati ọrẹbinrin rẹ, to tun jẹ oṣere, Ashabi Simple kede pe wọn bi ọmọ wọn akọbi.

Ọmọ Ashabi Simple kọ ni akọbi fun Portable, nitori pe o ti bi ọmọ mẹrin tẹlẹ lati ọdọ obinrin mẹta.

Lati igba ti ikede ọmọ tuntun naa ti jade si ni awọn eeyan kan ti n bu ẹnu atẹ lu baba ati iya ọmọ tuntun.

Bi awọn kan ṣe n bu Portable pe o n bimọ kaakiri, ni awọn kan n bu iya ọmọ tuntun naa ni pataki, wi pe o loyun fun ọkọ ọlọkọ.

Awọn kan ti ẹ n gba iyawo ile Portable, Omobewaji, ni imọran lori ayelujara pe, ko kọ ọkọ rẹ silẹ nitori bo sẹ n fun awọn obinrin mii loyun.

Ṣugbọn ninu fidio kan to fi si ori ayelujara Instagram rẹ ni Ọjọru, Portable sọ pe pupọ ninu awọn to n fi imọran ranṣẹ si iyawo oun lori ayelujara Whatsapp, lo jẹ ara awọn ọrẹ rẹ ti oun ti fẹ ri.

O ni iyawo oun n ri itọju to peye gba, eyi ti ko le mu ko fi igbeyawo rẹ silẹ.

Òṣèrè tíátà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ fún Portable ní àyípadà rere ti bá àyé òun torí pé òun fẹ́ Were Olorin

Ninu fidio mii ti wọn yà nibi ayẹyẹ isọmọlorukọ fun ọmọ tuntun ti Portable ati Ashabi bi, ni olorin naa ti kede pe oṣerebinrin ọhun ti di iyawo oun.

“Ọmọ lile ti pada di iyawo ile. O ti di iyawo ile, ọpẹ fun Allah.”

Ashabi Simple sọ pe lati igba ti oun ti n fẹ Portable ni .

O ni lootọ ni oun kọkọ n bẹru nnkan ti awọn eeyan yoo sọ lori ibaṣepọ oun pẹlu akọrin naa, o ni ṣugbọn oun pinnu lati fẹ́ẹ nitori pe oun n mu inu oun dun.

Ashabi ni oun ko gbero lati fẹ oṣere bii t’oun tabi akọrin, “ṣugbọn nigba ti ọ̀rọ̀ mi ti ja si ibi to ja si, mi o ro pe o le ṣe idiwọ fun iṣẹ mi gẹgẹ bi oṣere”.

“Mo ri fifẹ Portable gẹgẹ bi ibẹrẹ ọtun fun igbesi aye mi ati iṣẹ mi.”

Taa ni Ashabi Simple?

Ashabi Simple

Oríṣun àwòrán, Ashabi simple/Instagram

Oṣere Yoruba ni Omobolarinde Akinyanju, ti ọpọ ololufẹ rẹ mọ si Ashabi Simpla.

Yatọ si pe o jẹ oṣere, o tun ma n kọ sinima ati alamojuto ere.

O ti gbe fiimu kan jade ri, to pe akọle rẹ ni ‘Omo Lile’.