N100m nìjọba mì ń dà sì ọ̀rọ̀ ajé Igboho lóṣù – Makinde

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook

Gomina Ipinlẹ Oyo, onimoẹrọ Seyi Makinde ti kede pe o le ni ọgọrun milliọnu naira ti ijọba oun dá sori ọrọ aje Igboho labẹ ijọba ibilẹ orelope, lati igba ti ijọba rẹ ti bẹrẹ.

Makinde sọ ọrọ yii nigba to n ṣe ìpolongo ibo rẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP nìlu Igboho to wa ni ijọba ibilẹ Oorelope.

Gomina Oyo wa ṣe apejuwe bi o ti san owo oṣu awọn oṣiṣẹ eleyii to mu ki awọn oniṣowo, oṣiṣẹ ijọba ati awọn oniṣẹ ọwọ rí owo naa ni gbogbo igba nilu naa.

Makinde, lasiko ipolongo ibo naa, tun ba awọn ori ade ati awọn olori ẹlẹsin nijọba ibilẹ Oorelope sọrọ nipa awọn ileri to se lọdun mẹrin sẹyin, ko to de ipo gomina, amọ to ti mu sẹ.

Makinde ni ifẹ ti oun ni si ilu igboho kò dikun, bẹẹ oun ko ni fi ẹtọ ilu naa dun bi o tilẹ jẹ pe igbakeji oun tẹlẹ ti wọn yọ nipo, Rauf Olaniyan, jẹ ọmọ ilu Igboho.

Seyi Makinde, nigba to n ba awọn ọdọ ilu Igboho sọrọ, wa ṣeleri lati ṣe ijọba ti yoo fi aaye gba gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Oyo.