Iná ń yọ látara òkúta, ṣé iná yìí lè pèsè iná ọba bí?

  • Author, Chiagozie Nwonwu ati Peter Mwai
  • Role, SBJ
Okuta to n mu ina jade

Awọn fidio to n ṣafihan okuta to n pese ina mọnamọna ni South Africa ti gba ori ayelujara, awọn eeyan si ti wo awọn fidio naa ni ọkẹ aimọye igba.

Awọn eeyan kan si ti n sọ pe okuta naa ni yoo tan iṣoro ina mọnamọna ti ko ṣe dede nilẹ adulawọ.

Wayi o, ileeṣẹ iroyin BBC fi awọn fidio naa han awọn onimọ nipa okuta lati ṣe iwadii boya lootọ ni ina mọnamọna le jade lati ara okuta.

bulb

Ina to n ṣeyọ lati ara okuta

Ọkan lara awọn fidio ọhun to milẹ titi julọ ni eyii ti ina ti n ṣẹyọ laarin okuta kekeke meji ti wọn ba kan ara wọn.

Lara awọn to pin fidion naa ni oniṣowo ilẹ South Africa ti nnkn bii 800,000 eeyan n tẹle loju opo Twitter, Daniel Marven, pin.

Nnkan bii milionunu meji eeyan lo si ti wo fidio ọhun bayii.

Tantalum from coltan mined in DR Congo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Rock

Oríṣun àwòrán, Marven

Ẹlomiran loju opo Twiiter tun pin fidio mii nibi ti ẹnikan ti tan ina mọnamọna lati ara waya meji to fi kan okuta.

Lẹyin eyii ni oju ikanni African Archives pin fidio memeji, eyii ti awọn eeyan ti wo ni igab 35 milọnu bayii.

Nibo ni wọn ti ya awọn fidio ọhun?

Nipa fidio ti ẹnikan ti tan ina mọnamọna lati ara waya meji to fi kan okuta, ede Swahili ni ẹni naa n sọ, o si n sọrọ bii awọn eeyan orilẹ-ede DR Congo.

Lithium

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Iwadii tun fi han pe fidio ti ina ti n ṣẹyọ laarin okuta kekeke meji ti wọn ba kan ara wọn ti kọkọ jade loju opo Facebook ile ẹkọ Mohamed First University to wa ni Moroco lọdun to kọja.

Akọle ti wọn kọ si fidio naa ni “Lithium.”

Njẹ ina mọnamọna le jade lati ara okuta?

Ọjọgbọn kan lati School of GeoSciences ni fasiti Edinburgh, Stuart Haszeldine ni, o ṣoro lati gbagbọ pe ina mọnamọna le ti ara okuta jade.

O  ni “Mi o tii ri irufẹ nnkan bayii ri ninu ẹkọ imọ geology ati pe o ṣeeṣe ki wọn ti so okuta naa mọ ina mọnamọna ṣaaju fidio ọhun, eyii ti ko si ninu fidio naa.”

bulb

Oríṣun àwòrán, screenshot

Gẹgẹ bii ohun to sọ, o ṣeeṣe ki wọn ti fi waya sinu okuta mejeji, eyii to n mu ina jade.

“Ọkunrin to si mu okuta naa dani wọ ibọwọ, eyii ti yoo dabo bo ara rẹ lọwọ ina mọnamọna ọhun.”

Ọmọwe nipa imọ geology nile ẹkọ University of Nigeria, Ikenna Okonkwo, ṣalaye fun BBC lẹyin to wo fidio naa pe okuta naa farajọ ‘zinc’ tabi ‘lead ‘ore,’ eyii ti ko le pese ina mọnamọna funra rẹ.