Ọ̀pọ̀ òṣèré tíátà ń bá Tinubu polongo ìbò, akẹẹgbẹ́ wọn sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí wọn

Awọn osere tiata

Oríṣun àwòrán, @APC

Awọn gbajugbaja oṣere tiata Yoruba ni wọn n tu sita lati kopa ninu ipolongo ibo aarẹ tẹgbẹ oṣelu APC ń ṣe fún Asiwaju Bola Tinubu

Awọn gbajumọ osere naa lo n foju han nibi ipolongo ibo Tinubu, paapaa awọn eyi to n waye kaakiri ilẹ Kaarọ oojire.

Lara awọn oṣere to wa nibẹ ni Eniola Badmus, Jide Kosoko, Yinka Quadri, Taiwo Hassan Ogogo, Fatia Balogun, Saheed Balogun, Olaiya Igwe ati awọn miiran ninu isẹ tiata.

Ni gbogbo awọn ode ipolongo ibo Bola Tinubu ti wọn n lọ, lawọn osere tiata yii ti n kọrin, jo, sun rara tabi kewi.

Bakan naa ni wọn n fi awọn fidio nipa ipolongo ibo wọn naa soju opo ayelujara wọn fawọn eeyan lati wo.

Igbesẹ wọn yii lo ti n mu awuyewuye lọwọ, bawọn eeyan kan si se n kan saara si wọn, ni awọn miran n foju laifi wo wọn.

Awọn osere tiata to wọ asọ APC

Oríṣun àwòrán, @APC

Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, Kunle Adegbite sọ̀kò ọ̀rọ̀ sáwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ tó ń polongo ìbò fáwọn olóṣèlú

Kunle Adegbite

Oríṣun àwòrán, Others

Gbajúgbajà òṣèré tíátà, Kunle Adegbite ti ṣèkìlọ̀ fún àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ nídìí eré tíátà láti jáwọ́ nínú ṣíṣe ìpolongo fún ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC níbi ètò ìdìbò sípò ààrẹ tó ń bọ̀ lọ́nà.

Adegbite, nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sórí Instagram rẹ̀ ní láti ọdún 2015, ni òun ti mọ̀ wí pé ẹgbẹ́ òṣèlú APC kò ní àǹfàní kan tí wọ́n yóò ṣe fún àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ti ń ránṣẹ́ sí òun, pé ṣé òun bá nífẹ̀ẹ́ láti polongo fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC.

Àmọ́ ó ní, òun ń fi àsìkò náà sọ fún àwọn ènìyàn pé kí wọ́n yé fi irú rẹ̀ lọ òun mọ́.

Aworan

Oríṣun àwòrán, @EniolaBadmus

Òṣèré tíátà náà ní ipa tí ààrẹ Muhammadu Buhari kó nígbà tó ń ṣe olórí orílẹ̀ èdè yìí lábẹ́ ìṣèjọba ológun, ní kò jẹ́ kí òun ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ nígbà tó gbégbá ààrẹ lọ́dún 2015.

Ó ní ìpalára ńlá ni ẹgbẹ́ òṣèlú APC, lẹ́nu ọdún tí wọ́n lò nípò, ti mú bá Nàìjíríà.

O ni nítorí náà, kò yẹ kí àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí tún dìbò fún ẹgbẹ́ náà mọ́ níbi ètò ìdìbò gbogbogboò tí yóò wáyé nínú oṣù kejì yìí.

Ó fi kun pé gbogbo ìlérí tí ẹgbẹ́ APC ṣe fún àwọn ọmọ Nàìjíríà ni wọn kò múṣẹ, fún ìdí èyí wọn kò nílò láti tún de ipò ààrẹ Nàìjíríà mọ́.

“Ẹ̀yin akẹgbẹ́ mi ẹ yé tan àwọn olólùfẹ́ yín jẹ mọ́ nítorí owó”

Adegbite tún sọ fún àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ tó ń polongo fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC láti bojú àánú wo àwọn olólùfẹ́ tó ń tẹ̀lé wọn, kí wọ́n yé parọ́ fún wọn mọ́.

Ó ní òun mọ́ wí pé nítorí owó ni púpọ̀ nínú wọn fi ń tẹ̀lé APC, kìí ṣe nítorí ìfẹ́ ìlú ṣùgbọ́n òun rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n gba owó náà láì ṣi àwọn ènìyàn lọ́kàn.

Àgbà òṣèré náà ní kò yẹ kí àwọn òṣèré gbàgbé ọjọ́ ọ̀la wọn nítorí olóṣèlú tó jẹ́ wí pé lẹ́yìn tí wọ́n bá wọlé tán, wọn kò ní rántí wọn mọ́ di ọdún mẹ́rin mìíràn.

Ó fi kun pé, àwọn olólùfẹ́ onítíátà ni yóò wà níbẹ̀ fún wọn láti máa wo sinimá àti láti bá wọn wo gbogbo eré tí wọ́n bá ń gbé jáde.

Bákan náà ló tẹ̀síwájú láti gba àwọn ènìyàn nímọ̀ràn, láti lọ gba káàdì ìdìbò wọn, kí wọ́n sì lò ó láti fi yan ẹni tó bá wù wọ́n sorí ipò dípò ẹgbẹ́ òṣèlú APC.

Ta ni Kunle Adegbite?

Kunle Adegbite

Oríṣun àwòrán, officialkunleadegbite/Instagram

Gbajúmọ̀ òṣèré, olóòtú eré àti adarí eré sinimá Yorùbá ni Kunle Adegbite.

Ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù Kẹwàá ni wọ́n bí sí ìpínlẹ̀ Eko.

Ìlú Eko ló ti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama kó tó tẹ̀síwájú lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ìpínlẹ̀ Ogun.

Kunle Adegbite ní ìyàwó kan tí Ọlọ́run sì fi ọmọbìnrin méjì dá ìgbéyàwó wọn lọ́lá.