Mo ní láti ta dúkìá mi nítorí sinimá mi tó ń mi ìgboro tìtì -Femi Adebayo

Aworan Femi Adebayo

Oríṣun àwòrán, Instagram/Femi Adebayo

Gbajugbaju oṣere tiata, Femi Adebayo ti fi idi rẹ mule pe oun ni lati ta awọn dukia oun lati ṣe sinima tuntun to sẹsẹ gbe sita, Jagunjagun.

Adebayo sọ eyi lasiko to n kopa ninu ifọrọwerọ kan to se.

Fẹmi Adebayọ jẹ ko di mimọ pe ọpọlọpọ owo ni oun na lati ṣe sinima naa.

O ni oun ko fi bẹ lowo lọwọ lasiko ti oun ṣe sinima naa, ti oun ko si ni fẹ lati lọ ya owo.

“Mo ni igbagbọ pe sinima naa yoo di ilumọka, to mo se gbe awọn dukia mi diẹ ta lati fiowo rẹ gbe sinima naa sita.”

Lateef Adedimeji

Oríṣun àwòrán, Jagunjagun

Lati igba to ti jade, sinima Jagunjagun ti Fẹmi Adebayọ gbe jade ti di ilumọọka ti ọpọ kaakiri Naijiria ati agbaye si ti n kan sara si gbogbo awọn eekan oṣere to kopa ninu sinima naa.

Lara awọn eekan to wa ninu sinima naa ni Fẹmi Adebayọ, Lateef Adedimeji, Fathia Balogun, Ọdunlade Adekọla, Bukunmi Oluwaṣina, Bimbọ Ademoye, Kọla Ajeyẹmi, Ibrahim Yẹkini, Ibrahim Chatta, Aisha Lawal ati bẹẹbẹẹ lọ.

Bakan naa lawọn agba oṣere bii Muyiwa Ademọla, Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn, Binta Ayọ-Mọgaji, Dele Odule, Adebayọ Salami, Yinka Quadri, Peju Ogunmọla, Rasaq Ọlayiwọla (Ojopagogo) atawọn eekan oṣere miran.

O ku diẹ ki awọn ọmọ onilẹ da ile ti mo kọ lati fi se sinima naa wo – Fẹmi Adebayọ

Fẹmi Adebayọ

Oríṣun àwòrán, jagunjagun

Femi Adebayo tẹsiwaju pe ọpọlọpọ idiwọ lo waye lasiko ti oun ati awọn akẹgbẹ fẹ gbe sinima naa sita

Adebayo ni erongba oun ni lati san owo fun ilẹ ti awọn fẹ fi se ere naa sugbọn awọn ọmọ onilẹ yari

.”Wọn setan lati da gbogbo nnkan ti akọ wo, ti wọn si da wa duro fun odidi ọsẹ kan.

“A bẹre si ni lọ Ileeṣẹ Ọlọpaa ati ọdọ awọn lọbalọba pe ki wọn ba wa bẹ awọn eeyan yii lati fun wa laye lati se isẹ wa.

“Wọn sọ fun wa pe a le lo ilẹ naa sugbọn a ko le ra ilẹ naa.”

Taa ni Femi Adebayo?

Femi Adebayo jẹ gbajugbaja oṣere tiata Yollyhood, o si tun jẹ ọkọ lara ọmọ agba oṣere, Adebayo Salami.

Ọdun 1978, ọjọ Kọkanlelọgbọ oṣu kejila ni wọn bi Femi Adebayo.

Ilu Ilorin si Adebayoi ti wa, to si ti fi igba kan jẹ oludamọran fun ijọba ipinlẹ naa.

O bẹrẹ ere tiata lọdun 1985, to si kopa ninu sinima akọkọ ti Baba rẹ lọdan kan naa.