Fídíò, Èmi ò tíì sọ̀rọ̀ àfikún owó oṣù òṣìṣẹ́ báyìí o, gbèsè táwọn ìjọba tó kọjá jẹ ni mo ṣì ń sàn – Gómìnà Ademola Adeleke, Duration 5,03

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Èmi ò tíì sọ̀rọ̀ àfikún owó oṣù òṣìṣẹ́ báyìí o, gbèsè táwọn ìjọba tó kọjá jẹ ni mo ṣì ń sàn – Gómìnà Ademola Adeleke

Gomina Ademọla Adeleke ni ko si ojuṣe meji ti oun gba ju lati dẹrin pẹrẹkẹ awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun.

Ninu alaye rẹ pẹlu BBC News Yoruba, Gomina Adeleke ṣalaye pe lati igba ti oun ti de si ori oye oun ko tii ya owo kankan lorukọ ijọba ipinlẹ naa.

Adeleke ni gbogbo igbesẹ ti oun ṣi n gbe lọwọ bayii ni lati di awọn ibi ti owo n gba jo danu lapo ijọba ti oun si n fi awọn ere to n ti ibẹ jade san awọn ajẹẹlẹ owo oṣu ati owo ifẹyinti ti awọn ijọba tẹlẹ ti jẹ.

‘Emi o fi owo kun owo oṣu oṣiṣẹ o’

‘Emi o tii fi owo kun owo oṣu oṣiṣẹ, ohun ti mo n ṣe bayii ni lati san awọn owo ti ijọba to kọja jẹ. Boya bi owo yii ṣe pọ si lo jẹ ki awọn eeyan maa ro pe mo fi kun owo oṣu.”

Eyi ni ọrọ ti Gomina Adeleke sọ nigba ti a beere boya afikun ti de owo oṣu awọn oṣiṣẹ ni ipinlẹ rẹ.

O ni gbese to wa nilẹ ti ijọba oun ṣi n san pada fun awọn oṣiṣẹ yala lori abọ owo oṣu ti awọn ijọba to kọja jẹ wa nilẹ babi ti oun ṣi ni lati san fun awọn oṣiṣẹ naa.