‘Mo mọ̀ pé ọmọ mi tí wọ́n ló pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ n mu igbó, ó sì ní àìsàn ọpọlọ’

Jennifer Anthony

Oríṣun àwòrán, others

Àwọn ọlọpaa ti mu afurasi ẹni ogún ọdún to pa ọrẹbinrin rẹ. Baba afurasi ọ̀daràn ti ileesẹ ọlọ́pàá mu pe o pa ọrẹbinrin rẹ nilu Jos, Moses Oko, sọ pe ọmọ naa ma n mu igbo.

Ọjọ́rú ni ileesẹ ọlọ́pàá nipinlẹ Plateau safihan Oko, fun pe o pa ọrẹbinrin rẹ, Jennifer Anthony, to jẹ akẹ́kọ̀ọ́ fasiti ilu Jos. Ẹni ogun ọdún ni Moses Oko.

Agbenusọ ọlọpaa, Ubah Ogaba sọ pe ipinlẹ Benue ni ọwọ ti tẹ afurasi naa.

Ọgbẹni Ogaba sọ pe àwọn yoo gbe afurasi naa lọ sile ẹjọ́ ni kia ti iwadii ba pari.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọjọ́ kọkanlelọgbọn, oṣù Kejila, ọdún 2021, ni Jennifer to wa ni ipele ẹ̀kọ́ kẹta, di awati, ki awọn ọlọpaa to o ri oku rẹ lọjọ kinni, oṣù Kinni ọdun yii.

Koda, ẹ̀yà ara rẹ ko pe mọ nigba ti wọn ri i ni ile itura kan to wa ni opopona ilu Zaria. Oju rẹ kan ko si nibẹ mọ.

Bawo lo ṣe ṣẹlẹ̀?

Ọrẹ oloogbe Jennifer, Jessica Dung, sọ fun BBC Pidgin pe Jennifer múra lọjọ naa, to si dagbere pe oun n wa isẹ lọ.

Nigba ti Jessica ko gburo ọrẹ rẹ, ti ko si ri ko pada sile, lo bẹ̀rẹ̀ si ni pe ẹ̀rọ ibanisọrọ, sugbọn nọmba rẹ ko lọ.

Aworan afurasi ti ileeṣẹ ọlọpaa mu lori iku Jennifer

Oríṣun àwòrán, others

O ni kiakia ni oun mọ pe nkan ti ṣẹlẹ̀ si ọrẹ òun, nitori pe kii pa foonu rẹ, bẹẹni kii sọ̀wọ́n lori ayelujara.

Igba ti Jessica ko ri ọrẹ rẹ titi di ọjọ keji, lo ba gbe aworan rẹ si ori ayelujara pẹlu ikede pe ki ẹnikẹni to ba ri ko pe nọmba ti oun fi sinu ikede naa.

O salaye pe iyalẹnu lo jẹ nigba ti wọn pe oun lati ile itura kan pe ki oun wa a wo oku ọmọbìnrin kan, boya o ṣe e ṣe ko jẹ Jennifer.

Nigba to de ibẹ, o ri awọn aṣọ Jennifer ni ilẹ̀, ati awọn nkan rẹ miran. Inu àgbàrá ẹ̀jẹ̀ si ni wọn ba a ni nkan bí aago mẹjọ ku isẹju mẹẹdogun ni alẹ.

Àwọn aláṣẹ ile itura Domus Pacis Guest House nilu Jos, sọ pe ni nkan bi aago mejila ọsan ni àwọn ri oku Jennifer ninu àgbàrá ẹ̀jẹ̀ ninu yaara.

Ẹ̀yà ara rẹ ko pe, bakan naa ni oju rẹ kan ti di awati.

Wọn fi iṣẹlẹ naa to ileesẹ ọlọpaa leti, ti awọn ọlọpaa si gbe oku naa lọ si ile igboku pamọ si.

Bákan naa ni wọn mú òṣìṣẹ́ ile ìtura naa meji.

Jennifer Anthony

Oríṣun àwòrán, others

Iwadii wọn lo si fihan pe o se e se ko jẹ ọrẹkunrin rẹ to ti sá lọ lo pa a.

Ọjọ́ kọkanla, osu Kinni, ni ọwọ tẹ ọrẹkunrin naa, Moses Oko nipinlẹ Benue nibi to salọ.