Háà, nǹkan ṣe mí! Ikú pa ọ̀kan lára àwọn aláànú mi – Yinka Ayefele

Ilumọọka akọrin Tungba nni, Yinka Ayefele, ti sapejuwe iku gomina tẹ́lẹ̀ ni ipinlẹ Oyo, Otunba Adebayo Alao Akala, gẹgẹ bi adanu nla fun oun gẹgẹ bi ẹnikan ati idile oun.

“Ko si bi mo ṣe le kọ nipa itan igbesi aye mi laye ti mi o ni kọ nipa Otunba Adebayo Christopher Alao Akala”.

Ninu atẹjade kan to fi sita, Ayefele sọ pe lara awọn oluranlọwọ kadara oun ni Alao Akala wa, to si tun jẹ ẹ̀bùn Ọlọrun fun ipinlẹ Oyo ati Naijiria lapapọ.

Ọgbẹni Ayefele sọ pe oun dupẹ fun bi oloogbe naa ṣe ṣe atọna bi oun se n kọrin fun àwọn olokiki ati awọn eniyan nla, to fi mọ ileesẹ aarẹ, paapaa igbakeji aarẹ tẹlẹ, Atiku Abubakar ati awọn mii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ni “ko si bi ma a ṣe kọ ìtàn igbe aye mi, ti mi o ni kọ ọpọlọpọ nkan nipa àwọn oore ti Otunba Alao Akala ṣe fun mi.

O salaye pe Akala jẹ ẹnikan lara awọn ti Ọlọrun lò fun oun. Ati bi oun ṣe di aayo olorin fun Aso Rock, debi pe lati igba naa ni oun ti n kọrin fun ẹbi Atiku ni gbogbo igba ti wọn ba n ṣe ayẹyẹ.

Bakan ni Ayefele sọ pe o ṣòro fun oun lati gbagbọ pe Akala ti ku.

“Afunni ma wo ibẹ ni, ti kii ní olódì.”

Ayefele to ba ẹbi oloogbe kẹdun tun sọ pe titi lai ni iranti Alao Akala yoo wa ni ọkàn gbogbo àwọn to ran lọwọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ