O.Y.O ni Tinubu wa o, a kò ní ṣ’àtìlẹ̀yìn fún un ní 2023 àyàfi … – Afenifere, Ilana Omo Oodua

Pa Ayo Adebanjo ati Ọjọgbọn Banji Akintoye

Oríṣun àwòrán, OTHERS

“Tinubu àti àwọn mìíràn tó ń wá ipò Ààrẹ lọ́dún 2023 kò lé rí àtìlẹyìn ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re àyàfi…”

Adarí ẹgbẹ́ Afenifere ilẹ̀ Yorùbá, Olóyè Ayo Adebanjo ti ní àwọn kò ní ṣe àtìlẹyìn fún Tinubu lórí èròńgbà rẹ̀ láti díje dupò Ààrẹ lọ́dún 2023.

Adebanjo ní Tinubu nìkan kọ́ ni àwọn kò ní ṣe àtìlẹyìn fùn àti gbogbo àwọn tó ń wá láti di Ààrẹ lọ́dún 2023 àyàfi tí ìjọba bá ṣe àtúntò orílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Tinubu ni ẹ̀tọ́ láti gbé’gbá ìbò, tó sì ti fi èròńgbà rẹ̀ hàn sí Ààrẹ Buhari, ó tẹpẹlẹ mọ́ọ pé ẹgbẹ́ kò ṣetán láti juwọ́ àtìlẹyìn rẹ̀ kalẹ̀ fún olóṣèlú kankan lọ́dún 2023.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nígbà tí ó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ Ọjọ́rú, Adebanjo làá mọ́lẹ̀ pé ìwé òfin tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ń ṣàmúlò lọ́wọ́ yìí nílò àyípadà gidi tó sì gbọdọ̀ wáyé ṣaájú eto ìdìbò ọdún 2023.

Ó ní lọ́gán tí àtúnṣe bá ti bá ìwé òfin orílẹ̀ èdè yìí ni àwọn yóò sọ ẹ̀yìn ẹni tí àwọn yóò pọ̀n sí níbi ètò ìdìbò náà.

Bákan náà ló fi kun pé ènìyàn gbọ́dọ̀ ni ìgbàgbọ́ nínú nǹkan kí ó tó le kópa nínú rẹ̀, ó ní òun kò ní ìfọkàntán nínú ìwé òfin ológun tí Nàìjíríà ń ṣàmúlò.

Adebanjo ni Ààrẹ Muhammadu Buhari gan kò jiyàn rẹ̀ pé ìwé òfin ológun ni Nàìjíríà ń ṣàmúlò èyí tó sì gbọdọ̀ yípadà tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà bá fẹ́ ní ìlọsíwájú.

Ó ní gbogbo ìpèníjà tí orílẹ̀ èdè yìí ń kojú kò ṣẹ̀yìn àwọn kùdìẹ̀kudiẹ tó wà nínú ìwé òfin wa.

Ki ni Ilana Ọmọ Oodua sọ?

Lorukọ ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, akọwe ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Marxwell Adeleye ni kolobo ni Tinubu da wa o, awọn o gbe lẹyin rẹ.

Gẹgẹ bi awọn ẹgbẹ Afenifere naa ṣe sọ, ilana Ọmọ Oodua bakan naa ni awọn o le ti Tinubu lẹyin toripe awọn ti sọ tẹlẹ pe awọn o gbagbọ ninu ofin ọdun 1999.

“A dẹ ti sọ pe ki wọn jẹ ka lọ ṣe ipade apero ki awọn eeyan yan boya wọn ṣi fẹ wa lorilẹede Naijiria tabi wọn ko fẹ. Ti wọn ba si fẹ wa lorilẹede Naijiria wọn a wa sọ iru ofin ti wọn fẹ lati maa lo”.

O ni Tinubu funrarẹ tako ofin ọdun 1999 nigba to fi wa ni ẹgbẹ alatako “torinaa bi Tinubu ba wa lohun fẹ jade dupo aarẹ labẹ ofin ọdun 1999 yii kan naa, ọwọ ara rẹ lo wa o”.

Ẹgbẹ yii ti Ọjọgbọn Banji Akintoye n dari sọ pe to ba jẹ torii pe awọn jọ jẹ ọmọ Yoruba, ko difa tori kii ṣe Tinubu nikan ni ọmọ Yoruba ti yoo gbe igba ibo aarẹ “amọ ati tinubu ati gbogbo awọn ọmọ Yoruba to ku tawọn naa gbe igba ibo aarẹ, a n sọ fun wọn pe O.Y.O ni wọn wa o!”.

Ni ti awọn ẹya Igbo, o ni ko si nkan to kan ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua amọ gbogbo ọmọ to ba loun fẹ gbe apoti aarẹ, ko ma ka wa mọ ara rẹ rara.

Marxwell ni awọn ọmọ Naijiria to wa loke okun, Naijiria ni ko jẹ ki wọn pada wale to si jẹ pe “ilẹ baba wa leleyii, awọn ọmọ larubawa wa n paṣẹ fun wa nibi bayi lori gboogbo nkan taa ni ati taa n ṣe, iya yii ti to gẹ”.

“Tori rẹ gan la ṣe sọ pe ko ni si idibo kankan ni ilẹ Yoruba, a si ti n ṣe na lati da a duro bo tilẹ jẹ pe a mọ pe wọn yoo fẹ da wa duro amọ ọna rẹ yoo la fun wa”.

O ni ni ibamu pẹlu ofin awọn n wa ọna lati da eto idibo duro lawọn ipinlẹ to wa ni ilẹ Yoruba to si fi mọ ofin ibilẹ ati ti oke okun ni awọn yoo lo lati fi da gbogbo eto idibo duro nilẹ Yoruba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Agba ilẹ Yoruba mii to fi ipinlẹ Ondo ṣe ibugbe, alagba Seinde Arogbofa ni tirẹ sọ pe o yẹ ki ọmọ Yoruba ronu nipa awọn nkan to kan wọn gbọngbọn na.

“Awa o ni ki ẹnikẹni ma gbe apoti idibo o ṣugbọn laarin rukerudo ti a wa yii, njẹ ibo tilẹ maa waye?”.

Bóo baa o paa, boo baa o duu lẹsẹ. Ṣe ni ilẹ wa ti wọn ṣi ọna fawọn alejo “sabarumọ” to wọle ti wọn n pa awọn eeyan wa ni ipakupa, wọn n pa ọmọ sigbo pa awọn eeyan wa danu. Se iru ibẹ la ti fẹ dibo?”.

Alagba Arogbofa ni ti ko ba si alafia, awọn o le sọ pe awọn a dibo tori awọn eeyan o tilẹ ni fẹ jade lọ dibo tori ewu n bẹ loko Longẹ, Longẹ funra rẹ ewu ni.

O ni awọn ẹya Igbo naa lẹtọ lati sọ pe awọn fẹ du ipo aarẹ amọ fun gbogbo wọn pata, ti wọn ba lee mu awọn koko ọrọ ti awọn sọ fun wọn ni ipade apero kan to waye lọdun 2014 ṣe, nkan yoo dara.

“Lara awọn nkan taa sọ fun wọn nigba naa ni pe ọrọ aje, aisi iṣẹ, ọrọ ipinlẹ kọọkan lati jẹ ki awọn gomina ni aaye fọkanbalẹ ṣe eto ilu, kii ṣe pe gbogbo nkan to ba n jade ni ipinlẹ ni wọn a maa ru lọ si Abuja ati bẹẹ bẹẹ lọ”.

O ni nigba ti akoko ba maa fi sunmọ, o le to ọmọ Yoruba mẹwaa ti yoo dide. O ni ki wọn ni suuru lati to ilu tori awọn ẹya Hausa to lugọ to n wo awọn lee gbe igbesẹ ati gba a mọ wọn lọwọ.