Mo ṣetán láti sin àwọn ará ìpínlẹ̀ Osun fún sáà kejì báyìí  – Oyetola

Gboyega Oyetola

Lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò ìpínlẹ̀ Osun gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ pé gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ náà Gboyega Oyetola ló jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò tó wáyé lọ́jọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Keje ọdún 2022, Gboyega Oyetola ti bá àwọn ọmọ ìpínlẹ̀ náà sọ̀rọ̀.

Oyetola nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ilé rẹ̀ tó wà ní Iragbiji ní oríire náà kì í ṣe fún òun nìkan bíkòṣe fún gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ APC.

Ó ní ó jẹ́ ìmúgbòòrò ètò ìṣèjọba àwaarawa láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun ni òun jáwé olúborí ètò ìdìbò tó kọjá.

Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC fún àdúrótì wọn lásìkò tí gbogbo ìgbẹ́jọ́ náà fi wáyé àti pé ayọ̀ wọn ni bí ìgbìmọ̀ Tribunal ṣe dá ògo àwọn padà.

Bákan náà ló rọ̀ wọ́n láti ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kí wọ́n má bàá ẹnikẹ́ni fa wàhálà tàbí hùwà jàgídíjàgan lórí ìdájọ́ náà.

Oyetola tún yin àwọn agbẹjọ́rò tó ṣiṣẹ́ fun lákin fún ipa ribiribi tí wan kó láti lè jẹ́ kí ọjọ́ òní wá sí ìmúṣẹ.

Ó tẹ̀síwájú pé ìdájọ́ yìí yóò jẹ́ ìwúrí fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn láti gbájúmọ́ ètò ìdìbò gbogbogboò tó ń bọ̀ lọ́nà láti fi gbé gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn wọlé.

Ó fi kun pé inú òun dùn gidigidi sí ìdájọ́ náà tí òun sì tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ọjọ́ òní nítorí ó bá òun ní òjijì.

Oyetola ní òun ti ṣetán láti sin gbogbo àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Osun fún sáà kejì báyìí àti pé ó dá òun lójú pé òun ni òun gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò tó wáyé ọ̀hún.

INEC nílò láti fi ètò ìdìbò yìí kọ́gbọ́n

Oyetola nigba to n ba awọn akọrọyin sọrọ

Oyetola tẹ̀síwájú pé àjọ elétò ìdìbò ilẹ̀ Nàìjíríà ló ní ọgbọ́n láti kọ́ jùlọ lórí ìdájọ́ náà pàápàá bí ètò ìdìbò gbogbogboò ṣe ń súnmọ́ etilé.

Ó ní ó pọn dandan fún INEC láti ṣàgbéyẹ̀wó gbogbo àwọn ibi tí kùdìẹ̀kudiẹ wà nínú ètò ìdìbò náà kí wọ́n sì ṣàmójútó rẹ̀ kí irúfẹ́ rẹ̀ má wàyé níbi ètò ìdìbò gbogbogboò.

Ìdájọ́ mọ̀dàrú ni Tribunal gbé kalẹ̀, à ń lọ tako wọ́n nílé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn – Adeleke

Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke

Gomina Ademola Adeleke ti ipinlẹ Osun ti bu ẹnu atẹ lu idajọ to waye lori eto idibo Osun, eyi to sapejuwe rẹ gẹgẹ bi idajọ mọdaru.

Adeleke wa leri leka pe oun yoo morile ileẹjọ Kotẹmilọrun lati tako idajọ naa.

Adeleke sọ eleyi ni ile rẹ niluu Ede, ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Olawale Rasheed buwọlu, lati fi fesi si idajọ ti igbimọ to n gbọ ẹhonu ibo ni Osun gbe kalẹ lọjọ Ẹti.

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe igbimọ to n gbọ ẹhonu ibo naa kede pe gomina Adegboyega Oyetola lo bori ibo gomina to waye nipinlẹ Osun losu Keje ọdun 2022.

Ninu atẹjade naa, Adeleke ni ọna ati fi iya jẹ awọn araalu ni idajọ naa, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ si ti fariga lori idajọ naa.

Adeleke wa rọ awọn ololufẹ rẹ lati ṣe suuru nitori pe o da oun loju pe oun ni oun bori ninu eto idibo to waye lọjọ Kẹrindinlogun oṣu keje lọdun 2022.

“Mo n rọ awọn eeyan ipinlẹ Osun lati ṣe suuru. A n lọ ileẹjọ Kotẹmilọrun, ti a o si ri pe idajọ ododo waye .

“Mo fẹ fi ọkan awọn araalu balẹ pe gbogbo ọna ni a o lo lati wa ni iṣejọba nipinlẹ Osun nitori a wa laa bori eto idibo.”

Adegboyega and Ademola

INEC ló gbé èsì ìbò tó tako ara wọn kalẹ̀ l‘Osun, ominú ń kọ wá pé wọn kò ṣetán fétò ìdìbò tó yanranti – Tribunal

Ile  ẹjọ to n gbọ ẹhonu esi ibo gomina nipinlẹ Osun ti kede pe gomina ana nipinlẹ Osun, Adegboyega Oyetola lo bori ibo gomina naa.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Tertsea Kume to n lewaju igbimọ olugbẹjọ naa ni idibo gomina ọhun ko ba ilana ofin idibo ilẹ wa mu.

Igbimọ olupẹjọ naa wa yẹ aga mọ Ademola Adeleke nidi gẹgẹ bii gomina Osun

Nigba to n yẹ igi mọ gomina Ademola Adeleke nidii, igibmọ olugbẹjọ naa ni gomina Adegboyega Oyetola lo jawe olubori ninu ibo gomina to kọja nipinlẹ Osun naa.

Adajọ meji ninu mẹta to joko gbọ ẹjọ ẹhonu esi ibo naa, to fi mọ adajọ Kume funra rẹ lo fara mọ idajọ naa.

Awọn adajọ naa si lo fara mọ pe ki ajọ eleto idibo gba iwe Mo yege ibo ti wn fun Ademola Adeleke, ko si gbe fun Oyetola.

INEC gbé èsì ìbò tó tako ara wọn kalẹ̀, wọn kò ṣetán láti ṣètò ìdìbò tó yanranti – Tribunal

Adajọ naa wa yọ awọn ibo to woye pe o le ju awọn iye eeyan to dibo lọ, kuro ninu ibo awọn oludije mejeeji, to si kede pe Oyetola lo bori ibo gomina naa.

Lẹyin to yọ awọn ibo to le kuro ninu apapọ ibo wọn, Adajọ naa na ni ibo 314,921 ni Oyetola ni ninu esi ibo naa.

O si ni Ademola Adeleke lo ni apapọ ibo to jẹ 290,266

Ó ní ẹ̀rí tí ẹni tó ń jẹ́jọ́ náà fara mọ pé lóòtọọ́ ni àlékún wà lórí ìbò tí àwọn ènìyàn dì.

O sì ní àwíjàre rẹ̀ kò múná dóko rárá, tó sì di ẹ̀bi ru INEC fún pípésè àwọn èsì ìbò tó tako ara wọn.

Ó fi kun pé èyí ṣàfihàn pé INEC kò ì tíì ṣetán láti ṣètò ìdìbò tó yanranti.

Ilé ẹjọ́ náà wá pàṣẹ kí INEC gba ìwé ẹ̀rí ó yege tí wọ́n fún Adeleke padà.

Ẹ̀wẹ̀, ọ̀kan nínú àwọn adájọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta faramọ́ ìdájọ́ àwọn yòókù lórí bóyá Adeleke yẹ lẹ́ni tó lè díje àmọ́ kò gba ẹ̀rí tí àwọn ẹlẹ́rìí tó tako Adeleke múwá.

Ẹhonu mẹta ni APC ati Oyetola gbe wa siwaju wa, Adeleke yege ẹyọ kan nibẹ

Ninu alaye wọn lori igbẹjọ naa, igbimọ to n gbọ ẹhonu ibo naa ni ẹhonu mẹta lo wa niwaju ohun lori ẹjọ naa.

Akọkọ ni pa Adeleke ko lẹtọ lati gbe igba ibo gomina nitori pe iwe ẹri rẹ ko mu ko yege lati dije fun ipo gomina naa.

Ẹsun keji ni pe esi ibo ti Adeleke ni ko se afihan pe ida awọn oludibo to pọ julọ lo dibo fun.

Nigba ti ẹsun kẹta si ni ajọ INEC ko tẹle ilana ofin eto idibo gẹgẹ bi iwe ofin to de idibo nilẹ yii se laa kalẹ.

Amọ Adajọ Kume ni awọn olupẹjọ ọhun lo n tako esi ibo gomina to jade nijọba ibilẹ mẹwa nipinlẹ Osun.

Awọn ijọba ibilẹ naa ni Ede North, Ede South, Egbedore, Ejigbo, Ila, Ilesa west, Irepodun, Obokun, Olorunda ati Osogbo.

Adajọ naa wa salaye pe Adeleke ti sẹ lori awọn ẹsun naa ti ẹgbẹ oselu APC ati Oyetola fi kan na,  lọjọ kẹtalelogun osu Kẹjọ ọdun 2022.

Ademola Adeleke

Bí ìwé ẹ̀rí WAEC Adeleke tilẹ̀ jẹ́ 1981 tí ìpínlẹ̀ Osun kò tíì sí, síbẹ̀ , àwọn ìwé ẹrí yókù tó fún-un láti díje dupò gómìnà – Tribunal

Wayi o, Nigba to n gbe idajọ kalẹ lori ẹsun pe Ademola Adeleke ko ni ẹtọ lati dibo gomina naa, igbimọ olugbẹjọ naa ni eyi to ri bẹẹ.

Igbimọ naa wa kede pe Adeleke lẹtọ lati dije dupo gomina naa.

O ni awọn olupẹjọ naa lo wa pe akiyesi igbimọ naa si iwe ẹri oniwe mẹwa ti Adeleke gbe kalẹ lati dibo, eyi to ni o pari iwe mẹwa ldun 1981 nigba ti wọn ko tii da ipinlẹ Osun silẹ.

Nigba to wa n gbe idajọ kalẹ lori ẹsun iwe yiyi ti wọn fi kan Adeleke, igbimọ olugbẹjọ naa ni awọn iwe ẹri yoku ti Adeleke ko jọ yatọ siwe ẹri oniwe mẹwa gan to fun lati yege pe ko kopa ninu idibo gomina