Ìdájọ́ Tribunal Osun kò ní dá wa dúró láti lo BVAS ní ìdìbò 2023 – INEC

Adegboyega Oyetola

Oríṣun àwòrán, Gboyega Oyetola

Gomina tẹlẹri nipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola ni idajọ ileẹjọ to n gbọ ẹjọ idibo Tribunal duro daadaa.

Oyetola ni INEC ni ọpọ ẹkọ lati kọ lara idajọ naa

O ni INEC lo ni ọpọlọpọ ọgbọn lati kọ ninu esi idibo naa nitori awọn magomago to waye lasiko idibo naa ti wọn si tọka si lasiko idajọ Tribunal.

Bakan naa lo dupẹ lọwọ awọn araalu fun aduroti wọn, to si ni oun yoo sin ilu daradara.

Ìdájọ́ Tribunal Osun kò ní dá wa dúró láti lo BVAS ní ìdìbò 2023 – INEC

Ẹrọ BVAS ti wọn fi n dibo

Ajọ eleto idibo INEC ti kede pe gbogbo ilana ati alakalẹ ti awọn ni fun eto idibo ọdun 2023 ko ni yipada

INEC ni eto ilana, Biomodal Voters Accreditation System (BVAS) naa ni awọn yoo ṣi lo fun eto idibo naa.

Bakan naa ni wọn fi lede pe awọn ko tii le sọ ohunkohun nipa idajọ ileẹjọ lori eto idibo to waye ni ipinlẹ Osun nitori awọn ko i tii di idajọ tribunal ọhun.

Ninu ọrọ rẹ, kọmiṣọnna fun eto iroyin fun ajọ INEC, Festus Okoye sọ fun BBC pe awọn gbọdọ ri idajọ naa ki awọn to lee sọrọ lori rẹ.

Ẹri ti ajọ Tribunal gbe jade lori eto idibo to waye ni ipinlẹ Osun jẹ ki awọn ọmọ eniyan bẹrẹ si ni sọrọ nipa eto ilana BVAS ti INEC fẹ lọ fun idibo gbogboogbo to n bọ lọna naa.

BVAS ọhun ni INEC lo lati fi se idibo sipo gomina ipinlẹ Osun, ti wọn si kede Ademola Adeleke gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ni idibo naa.

Amọ Tribunal ni gomina tẹlẹri, Gboyega Oyetola lo wọle ninu eto idibo naa.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

BVAS kii jẹ ki wọn ji ami idanimọ ẹlomiran lasiko idibo – INEC

Ajọ INEC kede Ademola Adeleke pe oun lo jawe olubori ninu idibo naa pẹlu idibo 403, 271, nigba ti Oyetola ni 375, 027.

Oyetola ni ki ileẹjọ wọgile idibo naa nitori ọpọlọpọ magomago lo waye ni asiko idibo naa.

Ninu idajọ rẹ, Tribunal ni lootọ ni magomago waye ti awọn eniyan si dibo ju bi oṣe yẹlọ.

Lẹyin ti wọn yọ awọn idibo to ni eburu ninu, Oyetola naa pẹlu 314,931. Nigba ti Adeleke ni 290,266.

Amọ ajọ INEC ni iṣẹ BVAS nii lati safihan awọn to ṣe eru lasiko idibo naa.

Bakan naa ni wọn kede pe gomina Adeleke ni ọjọ mọkanlelogun lati pem ẹjọ kotẹmiolọrun lati fin ejo dun.

Lẹyin naa ni ileẹjọ kotẹmilọrun yoo lo ọgọta ọjọ lati fi da ẹjọ lori ẹsun naa.

Amọ ti ko ba tẹẹ lorun, o tun le gbe ẹjọ ọhun lọ si ileẹjọ to gajulọ ni Naijiria.

Bakan naa ni Adeleke ti ni oun yoo gbe ejọlọ si ileẹjọ kotẹmilọrun.

Eyi tunmọ si pe INEC ko ni lee sọrọ lori eto ilana BVAS ni saa yii.