Ìjínigbé di ìṣòro ńlá ní Iwo, wo ìdí tí Oluwo fi ṣèpàdé pẹ̀lú Fulani àti Bororo

Oluwo àtàwọn tó bá ṣèpàdé

Oríṣun àwòrán, Oluwo

Lójúnà àti wá ojútùú sí àìsí ètò ààbò tó ń bá ìlú Iwo fínra, Oluwo ti ìlù Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, Telu Kejì ti ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò, àwọn Fulani àtàwọn Bororo tó ń gbé ní ìlú náà.

Èyí kò ṣẹ̀yìn láti wá àtúnṣe sí bí wọ́n ṣe ń jí àwọn ènìyàn gbé ní ìlú náà àti láti fòpin sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.

Àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ọ̀hún tó fi mọ́ àwọn ọlọ́pàá, ẹ̀ṣọ́ ààbò ara ẹni lààbò ìlú àti Amotekun ló péjú síbi ìpàdé náà.

Wọ́n wá rọ àwọn Fulani àtàwọn Bororo náà láti ṣèrànwọ́ nípa sísọ àwọn nǹkan tó yẹ kí wọ́n mọ̀ fún wọn, láti lè kojú àwọn òṣìkà tó ń da ìlú rú.

Oluwo àtàwọn tó bá ṣèpàdé

Oríṣun àwòrán, Oluwo

Fulani àti Bororo, ẹ tú àṣìrí àwọn àjojì tẹ bá rí nínú igbó, ka le fopin si ijinigbe – Oluwo

Oluwo atawọn agbofinro naa ní àwọn nílò àwọn Fulani àtàwọn Bororo náà láti máa ṣàlàyé àwọn àjojì tí wọ́n bá ń bá pàdé nínú igbó lásìkò tí wọn bá ń ṣiṣẹ́ wọn, kí wọn le tọwọ́ wọn bọṣọ.

Oluwo wa sapejúwe ààbò gẹ́gẹ́ bí okùn ẹ̀mí ìlú tí yóò bá ní ìdàgbàsókè, o si pè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ gbogbo ènìyàn láti fi kojú ìjínigbé ní Iwo.

Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá agbègbè náà, ACP Omololu rọ gbogbo ènìyàn láti wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọ́rí kí wọ́n sì máa ṣe ìrànwọ́ fún àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti ṣe iṣẹ́ wọn bó ṣetọ́.

Ààrẹ ẹgbẹ́ Iwo Board of Trustees (IBOT), Ọ̀jọ̀gbọ́n Lai Olurode jẹ́jẹ̀ẹ́ àtìlẹyìn tó péye fún àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò gbogbo.

Lára àwọn tó péjú síbi ìpàdé náà ni àwọn ọmọ oyè àtàwọn olóyè lọ́kan-ò-jọ̀kan.

Oluwo tilu Iwo

Oríṣun àwòrán, Oluwo