Lizzy Jay Omo Ibadan àti Baba Alariya, Adẹ́rinpòsónú méjì, ṣe ìgbéyàwó

Aworan

Ilumọka adẹrinposonu ati oṣere tiata obinrin, Adeyela Adebola, ti ọpọ mọ si Lizzy Jay/Ọmọ Ibadan ni o ti kede igbeyawo rẹ pẹlu Adẹrinposonu miiran, Adeyemo Adelere ti ọpọ mọ si, Baba Alariya.

Igbeyawo naa lo waye niluu Ibadan, ti awọn ololufẹ tọkọtaya naa si tu sori ayelujara lati ransẹ ikini ku orire si awọn ololufẹ mejeeji.

Lizzy Jay, lori opo ayelujara Instagram rẹ ni, “Irinajo ti bẹrẹ” pẹlu aworan bi igbeyawo naa ṣe waye .

Ọpọ awọn akẹgbẹ awọn adẹrinposonu naa lo ti tu si ori ayeluajara lati ki awọn ololufẹ mejeeji ku oriire igbeyawo, ti wọn si gba adura pe ki ọrọ wọn dalẹ.

Ta ni Lizzy Jay Omo Ibadan?

Gbajugbaja adẹrinposonu nì, Adebola Adeyela, ti gbogbo eeyan mọ si Lizzy Jay ọmọ Ibadan tí salaye nipa ọpọ ohun ti oju rẹ n ri ni agbo iṣẹ amuludun.

Adebola, tii ṣe ọmọ bibi ilu Ile-Ife ni oun n ṣe awada naa, nigba ti ọwọ oun dilẹ ni, lai mọ pe o lee di nkan nla, ti awọn eeyan kii si jẹ ki oun gbadun, ti oun ko ba ṣe.

Lizzy, ẹni to sọrọ nipa ipenija to n koju ninu iṣẹ to yan laayo naa nibi ọdun meji ni,

“Oju obinrin tó wa lagbo amuludun n ri to, nitori ọpọ ilọkulọ ti wọn n fi lọ obinrin, to si jẹ pe obinrin ko le wọ awujọ kan, lai jẹ pe ọkunrin ni yoo mu lọ sibẹ.”