Iléẹjọ́ tó ga jùlọ pàṣẹ pé kí CBN àti ìjọba àpapọ̀ dẹ́kun àtúnṣe Naira

Owo Naira tuntun ati ti atijọ

Oríṣun àwòrán, CBN

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo ti fidi rẹ mulẹ pe ile ẹjọ to ga jul nilẹ wa ti pasẹ fun ijọba apapọ lati dẹkun sise atunse owo Naira ilẹ wa si tuntun

Bẹẹ́ ba gbagbe, awọn gomina mẹta to wa latinu ẹgbẹ oselu APC ti gomina Mallam El-Rufai ko sodi lo gbe ẹjọ naa lọ siwaju ile ẹjọ lọjọ kẹta osu keji ọdun yii.

Awọn gomina naa ni gomina ipinlẹ Kaduna, Kogi ati Zamfara, ti wọn si tọ ile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa lọ pe ko pasẹ pe ki banki apapọ ilẹ CBN jawọ ninu atunse owo naira.

Igbimọ adajọ ẹlẹnimeje nile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa, eyi ti adajọ John Okoro ko sodi lo panupọ pasẹ bẹẹ.

Awọn adajọ naa lo si sọ fun ijọba apapọ ilẹ wa, banki CBN atawọn banki olookoowo lati wọgile gbedeke ọjọ kẹwa osu Keji ọdun yii ti wọn pasẹ pe owo Naira atijọ ko ni jẹ itẹwọgba mọ.

Ile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa naa ni asẹ ọhun gbọdọ fidi mulẹ titi ti oun yoo fi pari igbẹjọ lori ẹjọ ti awọn gomina naa gbe wa siwaju rẹ.