“Lẹ́tà tí wọn fi rán Post Office bíi ọgbọ́n ọdún sẹ́yìn, ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ilé mi”

John Rainbow

Oríṣun àwòrán, John Rainbow

John Rainbow, olugbe Wylam Northumberland ni ile Gẹẹsi sọ iyalẹnu rẹ, nigba ti lẹta kan ti wọn kọ si lati ọgbọn ọdun sẹyin de si ile rẹ.

Lẹta naa ni wọn fi ransẹ sii lati agbegbe Bridgewater, Somerset.

Rainbow, ọmọ ọgọta ọdun ni, igba ti oun ṣi Lẹta naa, o ya oun lẹnu.

O ni lẹta naa jẹ ti awọn eeyan to ti jẹ olugbe ile awọn tẹlẹ ṣugbọn ti wọn ti ko kuro lati bii ọdun mejila si ọdun marundinlogun sẹyin.

Lẹta naa ni o ni amin ijọba lara, ti o jẹ ti agbegbe Bridgewater lati ọdun 1995.

Rainbow ni lẹta naa ni ko faya rara, ti o si wa ni ipo to dara.

Nigba ti wọn ka oun ti wọn kọ ransẹ, Rainbow ni koko lẹta naa da lori itan idile naa lati ọdun 1880 ati awọn iriri igba ewe ẹniti o fi lẹta naa ransẹ pẹlu ẹniti wọn kọ si.

Rainbow ni Valerie Jarvis-Read ni olugbe akọkọ ile oun, ti o si je wi pe oun ni wọn kọ lẹta naa si ṣugbọn lati ọdun 2010 ni o ti ta ile naa, kí oun to ra.

Ọmọ Patrick Daniel, ẹni ti o fi lẹta naa ransẹ, nigba to n ba BBC sọrọ ni pipẹ ti lẹta naa pẹ ko to de ọdọ ẹni ti wọn kọ si, yà oun lẹnu pupọ.

O wa sisọ loju rẹ pe Baba oun ti di oloogbe lati ọjọ pipe.

John Rainbow

Oríṣun àwòrán, John Rainbow

Ile ifiweransẹ ko le sọ pato ohun to mu ki lẹta lo bii ọgbọn ọdun, ki wọn to fi jisẹ

O ni Baba oun fẹran lati ma kọ lẹta si awọn ibatan rẹ, to si seese ki lẹta yii je ọkan lara irufẹ lẹta Baba oun.

Agbẹnusọ fun ile iṣe ijọba ti o wa lẹka ifiwe ransẹ ni awọn isẹlẹ bí eleyii ko ṣẹṣẹ máa waye.

Bo tilẹ je wi pe ile iṣe to risi ifiwe ransẹ ko le sọ pato oun ti o faa.

O wa tọrọ aforijin fun isẹlẹ naa.