PDP ló wà nídìí ọ̀wọ́ngogo epo, àwọn ni pẹ̀tẹ̀-pẹ́tẹ̀ ọ̀rọ̀ mi ń ta bá – Tinubu

PDP ló wà nídìí ọ̀wọ́ngogo epo, àwọn ni pẹ̀tẹ̀-pẹ́tẹ̀ ọ̀rọ̀ mi ń ta bá – Tinubu

bola tinubu

Oríṣun àwòrán, AsiowajuBolaAhmedTinubu/Facebook

Oludije sipo  aarẹ fun ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu ti fẹsun kan ẹgbẹ oṣelu PDP pe oun lo wa lẹyin iwa ibajẹ to pada di owongogo epo.

 Tinubu sisọ loju ọrọ yii nigba to n ba awọn eniyan sọrọ ni bi ipolongo ibo rẹ ni papa iṣere Aper Aku, ni Makurdi.

Bola Tinubu sọ pe PDP sọ ọrọ aje Naijiria di kumọkumọ fọdun mẹrindinlogun nigba to n fun awọn alatilẹyin rẹ ni iwe-aṣẹ lati ni ọpa  epo.

Asiwaju sọrọ yii lati ran awọn atilẹyin rẹ leti tan imọlẹ si ọrọ to sọ nibi eto ipolongo rẹ to waye nilu Abeokuta.

“Maa mu ireti ọtun pada wa fawọn ọmọ Naijiria to ti sọ ireti nu”

Tinubu ni ẹgbẹ oṣelu PDP lo ba orilẹ-ede yii jẹ, eyi to mu ki ọwọn epo fi ń da wahala silẹ kaakiri orilẹ-ede yii.

 Ẹ ranti pe Tinubu sọ pe ọwọn gogo epo rọbi ati pasipaarọ Naira ni  wọn fẹ lo lati doju ibo to n bọ bolẹ pẹlu erongba oun lati di aarẹ Naijiria.

Ninu ipolongo Abeokuta ni oludije aare labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ti so pe,”e gbe epo pamo, e gbe naira pamo, a maa dibo, a ma wole”.

O sọ pe, “Fun ọdun mẹrindinlogun ni ẹgbẹ oṣelu PDP fi ba ọrọ aje Naijiria je, papa julọ nipa fifi aṣẹ ati ni Ọpa epo rọbi fun awọn ọrẹ won ati awọn ọmọ ẹgbẹ won ni Abuja.

Tinubu wa seleri lati pese owo iranwo fun awọn akẹkọọ, to si ni oun yoo mu ireti pada wa fun awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria.

O tun seleri pe aye yoo tubọ dẹrun fawọn eeyan ti ogun le ni Benue ati awọn oṣiṣẹ ọba ti ijọba ipinlẹ Benue ko sanwo oṣu won.

Ọ̀wọ́n èpo àti Náírà tuntun ni wọ́n fẹ́ fi dènà ìbò 2023 – Tinubu

Tinubu laarin ero nibi ipolongo ibo

Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ti pariwo sita wi pe gbogbo igbesẹ ti ijọba orileede yii n gbe ni lati dabaru eto idibo apapọ ọdun 2023 ti a wa yii.

Oludije naa tii se ọmọ ẹgbẹ oselu kannaa pẹlu aarẹ Muhammadu Buhari to n se ijọba lọwọ ni Naijiria wa salaye pe owo Naira tuntun ati ọwọngogo epo bẹntiroolu to wa nita lasiko yii ni wọn fẹ ẹ lo.

 Tinubu lo sọrọ naa sita lasiko eto ipolongo idibo to ṣe niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, l’Ọjọru, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kinni, ọdun 2023.

 Ipolongo idibo naa to waye ni Papa Iṣere MKO Abiola to wa lagbegbe Kutọ niluu Abẹokuta, lo kun fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC kaakiri ipinlẹ Ogun, to fi mọ awọn ololufẹ agba oloṣelu naa.

Tinubu laarin awọn agba oloselu ninu mọto

“Bi ko ba si epo bẹntiro ninu ọkọ, gbogbo wa yoo fi ẹsẹ rin lati dibo wa”

Asiwaju ni Naira tuntun ti wọn ṣẹṣẹ gbe jade ko si nita f’awọn araalu lati na, bẹẹ si ni awọn araalu tun n jiya fun epo bẹntiroolu.

O ni ijọba apapọ ṣe bi ẹni pe wọn ko mọ ohun to n lọ nipa awọn ipenija mejeeji yii, nitori pe gbogbo ipinnu wọn ni lati dabaru eto idibo apapọ.

Amọ Tinubu wa fọwọ sọya pe ohun to da oun loju ni pe awọn ọmọ Naijiria ko nii gba, wọn yoo jade lati dibo lọpọ yanturu, nitori pe ayipada rere ni wọn n fẹ.

“Wọn ko fẹ ki idibo yii waye. Wọn fẹẹ dabaru ẹ ni. N jẹ ẹ maa gba wọn laaye bii?

Wọn ti bẹrẹ sii gbe ọrọ aisi epo rọbii dide. Ẹ ma mikan, ti ko ba si epo bẹntiroolu, a maa fi ẹsẹ wa rin lọ sibi ti a ti maa dibo, a si maa dibo wa.”

Tinubu laarin awọn agba oselu nibi ipolongo ibo

“Onitanjẹ nla ni wọn jẹ, wọn le ni ko si epo, amọ emi Aṣiwaju maa f’opin si ọwọngogo epo” 

Oludije sipo aarẹ fẹgbẹ APC naa tẹsiwaju pe “To ba wu yin, ẹ fi owo kun owo epo, ẹ tọju epo fun wa.

Bo si tun wu yin, ki ẹ tun ọda ara owo naira ṣe, a maa bori ninu eto idibo to n bọ lọna yii.

 A maa fi kaadi idibo wa gba ijọba kuro lọwọ wọn.

Onitanjẹ nla ni wọn jẹ, wọn tun le sọ pe ko si epo mọ, nitori pe wọn ti n sọrọ nipa ọwọngogo epo bayii.

Ẹ gbagbe ẹ jare, ẹ fọkan balẹ. Emi Aṣiwaju maa f’opin si ọwọngogo epo.

 “Ẹ jẹ ki owo epo tubọ maa lọ soke sii, awọn ni wọn mọ ibi ti wọn n ko epo pamọ si.

Wọn n tọju owo naira tuntun, wọn tun n tọju epo, a maa dibo, a si maa bori wọn.”

Asiwaju Bola Tinubu wa pari ọrọ rẹ pe ilana isejọba toun yoo setọju awọn ọdọ, ti oun yoo si pese owoya fun wọn.