Ìfẹ̀hónúhàn bẹ́ sílẹ̀ nílùú Osogbo lẹ́yìn ìdájọ́ ‘Tribunal’ tó gba ipò gómìnà lọ́wọ́ Ademola Adeleke

Ademola Adeleke

Awọn eeyan kan niluu Osogbo ti bẹrẹ ifẹhonuhan lodi si idajọ ile ẹjọ to gbọ ẹsun magomago to waye lẹyin idibo gomina ipinlẹ Osun lọdun to kọja.

Agbegbe Olaiya, niluu Osogbo ni iwọde naa ti waye lọsan ọjọ Abameta.

Lara awọn olufẹhonuhan naa to ba BBC Yoruba sọrọ sọ pe inu awọn ko dun si idajọ ọhun, awọn si n fẹ ki wọn gbe ipo gomina pada fun Ademola Adeleke.

Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, wọn ni ijọba ẹgbẹ oṣelu APC ti su awọn, ati pe ẹgbẹ oṣelu PDP ni awọn dibo fun.

Ọkan lara awọ eeyan naa, Afeez Adebayo Mukaila, sọ fun BBC pe “Ohun ti a n pe fun ni ki ajọ, National Judicial Council, NJC yẹ idajọ ti igbimọ naa da yẹwo lati mọ boya idajọ ọhun ni magomago ninu.”

“Gbogbo aye lo mọ pe Ademola Adeleke ni gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Osun dibo fun, a si n fẹ ki wọn gbe ijọba naa pada fun.”

Ẹlomiran to tun ba BBC Yoruba sọrọ, Sikiru ti apẹle rẹ n jẹ ‘Burnvita’ tun sọ pe ijọba Oyetola n fi iya jẹ awọn eeyan nipinlẹ Osun, Ademola Adeleke si ni awọn n fẹ.

Sikiru sọ pe ẹjọ ‘Buga’ ni ile ẹjọ naa da wọn si ti gbe are fun ẹni ti ko tọ si. 

Osogbo

Ti ẹ ko ba gbagbe, inu oṣu Keje, ọdun 2022 to kọja ni idibo gomina naa waye nibi ti ajọ eleto idibo, INEC, ti kede pe Ademola Adelek, ti ẹgbẹ oṣelu PDP lo jawe olubori.

Lẹyin ikede yii ni ikọ agbẹjọro gomina Gboyega Oyetola gba ile ẹjọ lọ lati pe esi ibo naa nija.

Amọ nigba ti yoo fi di ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kini, ọdun 2023 yii, ile ẹjọ sọ pe Gboyega Oyetola lo gbegba oroke ninu eto dibo naa, o si paṣẹ ki INMEC gbe agbara pada fun fún sáà keji.

Ẹwẹ, gomina Ademola Adeleke ti wa ke si awọn ololufẹ rẹ ki wọn ma ṣe kopa ninu jagidijagan kankan lẹyin idajọ ọhun nitori oun yoo gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ.