“Láí fábàdà, a kò pín ipò ààrẹ sẹ́kùn gúúsù ní 2023”

Awọn gomina ẹkun ariwa Naijiria

Oríṣun àwòrán, Simon Lalong

Awọn gomina to wa lawọn ipinlẹ mọkandinlogun to wa lẹkun ariwa Naijiria ti yari pe ipo aarẹ ko ni wa si ẹkun guusu lọdun 2023.

Ipinnu wọn yii lo tako adehun ti awọn gomina lẹkun guusu Naijiria se lasiko ipade wọn to waye laipẹ yii pe ẹkun guusu Naijiria ni ipo aarẹ gbọdọ wa lọdun 2023.

Eyi si lo wa lara ohun ti awọn gomina ẹkun ariwa Naijiria fi ohun sọkan le lori nibi ipade ti wọn se pẹlu awọn ọba alaye lọjọ Aje eyi to waye nile ijọba nilu Kaduna.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Alaga ẹgbẹ awọn gomina naa, tii tun se gomina ipinlẹ Plateau, Simon Lalong si lo ka atẹjade ti wọn fisita lopin ipade wọn ọhun lorukọ awọn akẹẹgbẹ rẹ.

Gẹgẹ bi awọn gomina naa ti wi, pinpin ipo aarẹ, gẹgẹ bi awọn gomina ẹkun guuusu se n beere fun, tako ofin ilẹ wa tọdun 1999 ti wọn se atunse rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Wọn ni aarẹ ti wọn ba dibo yan gbọdọ ba ilana ti ofin ilẹ wa la kalẹ mu, lara rẹ si ni ko ni ibo to pọ julọ.

Bakan naa ni wn lo gbọdọ ni ida mẹẹdọgbọn ninu ọgọrun gbogbo ibo, ko si tun ni ida meji ninu mẹta ibo yika ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa lorilẹede wa.

Gomina Lalong tọkasi pe bi o tilẹ jẹ pe awọn gomina kan lati ẹkun ariwa Naijiria ti fontẹ lu ibeere awọn gomina guusu pe ki ipo aarẹ bọ si ẹkun guusu lọdun 2023.

Amọ o ni apapọ awọn gomina lẹkun ariwa koro oju si ipe yii patapata.

Lori ọrọ owo ori ọja VAT to n fa awuyewuye laarin awọn ipinlẹ kan ati ijọba, awọn gomina ariwa fẹnuko pe niwọn igba ti ẹjọ naa ti wa nile ẹjọ, awọn ko ni sọrọ nipa rẹ.

Amọ Lalong salaye pe ko yẹ ki awọn gomina naa si owo ori ọja mu si owo ọja tita.

O ni bi ipinlẹ kọọkan ba gbe ofin owo ofin ọja kalẹ nipinlẹ rẹ, ọrọ naa yoo di gbigba owo ori ọja lọna pupọ eyi ti yoo mu ki ọja gbe owo lori, ti okoowo lati ipinlẹ kan si ekeji yoo si dẹnu kọlẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nipa aifararọ eto aabo lẹkun ariwa ilẹ yii, awọn gomina lẹkun naa gbosuba sileesẹ ologun lori aayan lati gbogun ti awọn agbebọn ati idaluru lẹkun naa.

Amọ awọn gomina yii wa fi oju laifi wo bi awọn osisẹ eleto idajọ kan se n lẹdi apo pọ pẹlu awọn onisẹ ibi naa, ti wọn i n tu awọn ọdaran ti wọn ba mu silẹ.