Wo iye àwọn olóṣèlú tó ti lọ ṣàbẹ̀wò sí Tinubu ní London

Tinubu

Oríṣun àwòrán, Leadership News

Nnkan bii ọgbọn awọn oloṣelu lo ti lọ ṣabẹwo si eekan ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu niluu London laarin ọsu meji sẹyin.

Oṣu Kẹta ọdun yii ni oloṣelu naa ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mọ́kàndínláàdọ́rin loke eepẹ, tawọn kan si ti n sọ pe o n mura lati dije du ipo Aarẹ Naijiria lọdun 2023.

Amọ Tinubu funra rẹ ko tii mẹnuba tabi kede pe oun fẹ dije fun ipo aarẹ Naijiria rara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara awọn ọrọ ti ọpọ ọmọ Naijiria n sọ lẹnu ọjọ mẹta yii ni pe, agba ọjẹ oloṣelu naa n ṣaarẹ, ṣugbọn agbẹnsuọ rẹ, Tunde Rahman ṣalaye ninu atẹjade kan pe, lootọ ni Tinubu ti tẹkọ leti lọ siluu London, ṣugbọn ko ṣaisan kankan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Lara akitiyan ati jẹ ki awọn araalu mẹnu kuro lori ahesọ ọrọ pe Tinubu n ṣaarẹ ni gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu se sọ lọjọ Kẹrin oṣu Kẹjọ pe oun ṣabẹwo si Tinubu ni London, alaafia si lo wa.

Yatọ si Sanwo-Olu, gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ati ojugba rẹ nipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi, to fi mọ gomina ipinlẹ Kano, Umar Ganduje naa ti ṣabẹwo si Tinubu niluu London.

Tinubu

Oríṣun àwòrán, IBileradio TiwantiwaTv

Lara awọn to tẹle Ganduje lọ si London ni iyawo rẹ, Hafsat Ganduje, ọmọ wọn, Umar Ganduje, awọn aṣofin mẹta ati mọlẹbi Ganduje mẹrin mii.

Awọn oloṣelu mii to tun ṣabẹwo si Tinubu ni London ni agbẹnusọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin l’Abuja, Femi Gbajabiamila, gomina ipinlẹ ogun tẹlẹ, Ibikunle Amosun, gomina Bornu tẹlẹ, Kahsim Shettima ati aṣoju ẹkun idibo Magumeri nile aṣofin agba, Usman Zanna.

Bakan naa ni Aarẹ Muhammadu Buhari naa ti ṣabẹwo si Tinubu ni London.

Ko tan sibẹ, awọn mii to tun lọ ki Tinubu ni London ni:

  • Igbakeji gomina ipinlẹ Eko, Obafemi Hamzat
  • Olori awọn oṣiṣẹ gomina ipinlẹ Eko, Tayo Ayinde
  • Igbakeji olori awọn oṣiṣẹ gomina ipinlẹ Eko, Gboyega Soyannwo
  • Olubadamọran pataki si gomina ipinlẹ Eko lori eto ẹkọ, Tokunbo Wahab
  • Amofin ẹgbẹ APC tẹlẹ, Muiz Banire
  • Agbẹnusọ ile igbimọ aṣofi ipinlẹ Eko, Mudashiru Obasa
  • Alaga igbimọ to n ri si eto irinna nile aṣofin ipinlẹ Eko, Temitope Adewale
  • Alaga igbimọ to n ri si eto idagbasoke awujọ nile aṣofin ipinlẹ Eko, Nureni Akinsanya
  • Alaga igbimọ to n ri si eto ọrọ aje ilẹ okeere nile aṣofin ipinlẹ Eko, Sylvester Ogunkelu
  • Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun ila oorun ati ẹkun iwọ oorun ipinlẹ Eko nile igbimọ aṣofin agba, Adetokunbo Abiru ati Adeola Solomon
  • Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun aringbungbun ipinlẹ Ekiti, Opeyemi Bamidele
  • Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun iwọ oorun ipinlẹ Osun, Adelere Oriolowo
  • Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun ila oorun ipinlẹ Niger, Mohammed Sanni
  • Alaga ijọba ibilẹ Isolo, nipinlẹ Eko, Adebayo Olasoju ati gbajumọ oloṣelu mii, Adekunle Akanbi
  • Gbajugbaja akọrin fuji, Wasui Ayinde ti ọpọ mọ si KWAM1 naa ko gbẹyin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Pẹlu gbogbo bi awọn eeyan ṣe lọ n ki Tinubu niluu London yii, agbẹnusọ rẹ ṣi sọ sibẹ pe, alaafia lo wa ati pe ko ṣaisan kankan.

Wayi o, ibeere ti ọpọ ọmọ Naijiria n beere ni pe, to ba jẹ pe lootọ ni Tinubu ko dubulẹ aisan, eetiri ti awọn eeyan jankan lawujọ, paapaa awọn oloṣelu ṣe lọ n ki ni London?