Sotitobire pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ẹ̀wọ̀n gbére

Sotitobire

Ile ẹjọ kotẹmilọrun to wa niluu Akure ti sun ọjọ idajọ rẹ siwaju lori ẹjọ kotẹmilọrun ti pasitọ ijọ Sotitobire, Alfah Babatunde pe.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 ni ile ẹjọ giga kan niluu Akure sọ pasitọ ọhun, atawọn marun un mii si ẹwọn gbere lori ẹsun pe wọn lọwọ ninu bi ọmọ ọdun kan, Gold Kolawole ṣe poora ninu ṣọọṣi pasitọ ọhun.

Sotitobire pe ẹjọ kotẹmilọrun naa tako idajọ ile ẹjọ giga naa, o si ni ki ile ẹjọ kotẹmilọrun da idajọ ẹwọn gbere ti ile ẹjọ akọkọ da fun oun nu.

Agbẹjọro Sotitobire, Gboyega Awomolo mu iwe ẹbẹ mẹta wa siwaju ile ẹjọ kotẹmilọrun naa, to fi mọ koko marun run ti wọn fi gbọdọ da idajọ naa nu, ati pe ajọ ọtẹmuyẹ DSS ko lagbara lati ṣe iwadii ẹsun ijọmọgbe ọhun.

Awomolo sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti n ṣiṣẹ takun-takun lori iwadii ẹsun naa, ko to di pe ajọ ọtẹmuyẹ DSS ṣadede ja iwadii ọhun gba lọwọ ọlọpaa.

Agbẹjọro Sotitobire ọhun tun sọ siwaju pe, DSS ko lagbara labẹ ofin lati ṣe iwadii ẹsun naa niwọn igba to ti jẹ ẹsun iwa ọdaran.

O ni nitori naa, gbogbo ohun ti DSS ṣe lori ẹjọ naa, to fi mọ idajọ ẹwọn gbere ti wọn da fun Sotitobire ko tọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awomolo tun sọ pe ẹri ti ko lẹsẹ nilẹ ti wọn fi ṣedajọ ẹwọn gbere fun pasitọ Sotitobire ko tọ, o si bẹbẹ pe ki ile ẹjọ kotẹmilọrun naa da ẹjọ ọhun nu, ko si tu onibara oun silẹ lẹsẹkẹṣẹ.

Ẹwẹ, agbẹjọro ijọba, to tun jẹ kọmiṣọna eto idajọ ni ipinlẹ Ondo, Charles Titiloye sọ pe DSS lagbara lati ja iwadii naa gba lọwọ ọlọpaa nitori ọrọ ọhun ti n di iṣu ata yan-yan.

O ṣalaye pe eto idajọ ipinlẹ Ondo ko lodi si ki ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ja iwadii gba lọwọ ọlọpaa, ko si tun gbe irufẹ ọrọ bẹẹ lọ sile ẹjọ.

Lẹyin naa lo rọ ile ẹjọ kotẹmilọrun ọhun lati kin idajọ ẹwọn gbere ti ile ẹjọ giga ilu Akure da fun wolii naa ṣaaju lẹyin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Lẹyin atotonu awọn agbẹjọro mejeji, adajọ to n gbọ ẹjọ ọhun, Rita Nosakhare fi ọjọ idajọ rẹ siwaju.

Bo tilẹ jẹ pe o kọ lati kede ọjọ idajọ naa, o sọ pe oun yoo fi to gbogbo awọn ti ọrọ naa kan leti ti akoko ba to.

Ẹwẹ, igbejọ kotẹmilọrun awọn olukọ ewe marun un ti wọn wa ninu ẹwọn pẹlu wolii Sotitobire yoo waye laarin ọjọ diẹ si asiko yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ