Kò sí ọ̀nà nínú kí Nàìjíríà pín, àtúntò ló lè mú àlááfíà àti ìṣọ̀kan wá – Alaafin

Alaafin Oyo

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oba Adeyemi III

Alaafin Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi kẹta ti rọ awọn ọmọ Naijiria atunto orilẹede yii lo le mu iṣọkan ati ilọsiwaju wa kii ṣe pinpin Naijiria.

Alaafin rọ awọn eeyan lati kọ eti ikun si awọn to n pe fun iyapa kuro lara orilẹede Naijiria.

Oba Adeyemi sọrọ yii nibi ayẹyẹ ifilọlẹ yara ikẹkọọ marunlelọgbọn ile ẹkọ Royal Gold Model ati fifi ipilẹ mọṣalaaṣi kan lelẹ niluu Ibadan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Alaafin ni ọpọ nkan to ṣẹlẹ sẹyin lo ṣe okunfa iwa ẹlẹyamẹya ati idẹyẹsi laarin awọn ọmọ Naijiria.

Amọ, o rọ awọn ọmọ Naijiria lati wa ọna ti wọn le fi yanju awọn ohun to ti ṣẹlẹ sẹyin ni itubi inubi ki orilẹede Naijiria le tẹsiwaju.

”Mi o lero pe pinpin Naijiria ni ojutuu si iṣoro to n koju Naijiria.

Ṣugbọn a le ṣe atunto orilẹede yii lọna ti alaafia yoo fi jọba ti a o si maa gbe pọ ni alaafia.

A nilo lati wa ni iṣọkan ni Naijiria ki orilẹede yii maa baa pin yẹlẹ yẹlẹ,” Alaafin lo sọ bẹẹ.

Oba Adeyemi ko ṣai lu adari ile ẹkọ naa, Alhaji Taofeek Akewugbagold, lọgọ ẹnu lori bi o ti n pe fun iṣọkan laarin awọn ọmọ Naijiria.

Ninu ọrọ tiẹ, Akewugbagold naa rọ awọn musulumi lati ma dẹyẹ si awọn ẹlẹsin miran.

Alhaji Akewugbagold ni ”ko yẹ ki awọn ẹlẹsin kan maa doju ibọn kọ awọn ẹlẹsin miran.

Onikaluku lo lẹtọọ lati ṣe ẹsin ti wọn ba fẹ tori ojiṣẹ Ọlọrun ni Jesu ati Anọbi Muhammad.”

Almufty Ilorin, Sheikh Sulaimon Onikijipa to sọrọ apilẹkọ nibi ayẹyẹ naa kepe awọn musulumi lati maa tẹle awọn ẹkọ iwe mimọ Quran, ki wọn si ye wa iṣẹ iyanu nibi ti ko si.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ