Àdúrà Saga gbà, òun pẹ̀lú Nini jáde lọ́jọ́ kan náà

Awọn olukopa BBNaija

Oríṣun àwòrán, BBNaija

Adura Saga gba nile ẹlẹgbọn agba bayii o pẹlu bi oun ati Ninu, korikosun rẹ ninu idije naa ṣe jade kuro nile ẹlẹgbọn agba BBNaija lọjọ Aiku.

Ṣaaju lọsẹ diẹ sẹyin ni Saga ti kọkọ sọ pe bi wọn ba lee le Nini kuro ṣiwaju oun, oun funra oun yoo pe fun iyọkuro ni o lati lee lọ ba korikosun oun nita ile ẹlẹgbọn agba.

Saga ko nilo igbesẹ yi mọ bayii nitori oun ati Nini ni wọn jọ le kuro nile ẹlẹgbọn agba lọjọ Aiku.

Amọṣa, awọn mejeeji nikan kọ ni wọn yọ. Ẹlẹgbọn agba tun le Queen naa pẹlu.

ṣaaju ninu eto naa ni Ebuka ti pe Pere niwaju gbogbo awọn olugbe naa to si ni oun ti yọ ọ kuro ni ile naa.

Awọn olukopa BBNaija

Oríṣun àwòrán, BBnaija

Bakan naa lo tun pe Angel pẹlu jade, ṣugbọn o ni oun ko yọ awọn mejeeji yii, ara idan ere eto naa ni gẹgẹ bi Ebuka to jẹ atọkun eto naa ṣe sọ. O ni aṣiri ni yoo jẹ laarin awọn oluworan eto naa ati Ẹlẹgbọn agba funrarẹ.

Ko tii han si ẹnikẹni ohun ti ẹlẹgbọn agba n pete rẹ ṣugbọn gbogbo awọn eeyan to n woo naa lo n fọwọleran wo ohun ti yoo ba ti ẹyin rẹ yọ.