Wo ìdí tí CAN fi fún Imaamu kan l’ami ẹyẹ níbi ayẹyẹ ńlá ọdún 45 ti CAN pé

Imaamu gba ami ẹyẹ

Oríṣun àwòrán, Channels TV

Ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi Naijiria ti fi ami ẹyẹ da Imaamu ẹlẹsin Islam kan, Abdullahi Abubakar to jẹ kawọn ẹlẹsin Kristẹni sa pamọ sinu mọṣalasi rẹ nigba ti ogun de nipinlẹ Plateau.

Awọn ọmọlẹyin Kristi to le ni igba ni Imam yii gba silẹ ni ijba ibilẹ Barkin Ladi.

Ẹgbẹ CAN ṣe idanilọla pẹlu ami ẹyẹ yii lọjọ Abamẹta nilu Abuja nibi ayẹyẹ ọdun marundinlaadọta ti ẹgbẹ CAN pe.

Imaamu Abubakar gba awọn Kristẹni to le ni igba la lọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹfa, ọdun 2019 nigba ti awọn afurasi ya wọ awọn ilu ni ijọba ibilẹ Barkin Ladi.

Ninu oṣu keje ọdun 2019, ijọba ilẹ Amẹrika da Imaamu ẹni ọdun mẹtalelọgọrin yii lọla pẹlu awọn adari sin mẹrin mii lati orilẹede Sudan, Iraq, Brazil ati Cyprus gẹgẹ bi ajijagbara fun alafia ẹsin kaakiri orilẹede wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Igbakeji aarẹ naa to wa nibẹ, Yemi Oṣinbajo rọ awn Kristẹni atawọn olori lati jẹ ololufẹ ṣiṣe ẹsin ni alafia ati titẹle alakalẹ ofin.

Lara awọn to gba ami ẹyẹ nibẹ naa ni igbakeji aarẹ, Yemi Oṣinbajo, o jiṣẹ aarẹ Muhammadu Buhari gẹgẹ bo ṣe ba ẹgbẹ CAN yọ.

“Bi a ba n wa irẹpọ ati alafia lorilẹede Naijiria, awọn gbẹ ẹsin Kristẹni atawọn adari ẹsin ni Naijiria gbudọ maa waasu ibadọgba ni gbogbo igba ki wọn si ma kaarẹ ninu jija fun ẹsin alafia, idajọ ododo ati titẹle ofin”.

Oṣinbajo ni “a gbudọ maa jẹ ki otitọ jade pe Kristi ko wa lati ṣagbekalẹ ẹsin tabi ba ẹnikẹni jẹ bi ko ṣe fifi ododo rẹ han fun gbogbo eniyan eyi to le mu eeyan jogun iye ainipẹkun”.

Igbakeji aarẹ tun gboriyin fun iṣẹ takuntakun ti awọn adari CAN n ṣe lati mu ilọsiwaju ba ẹsin to sin CAN ti di ohun elo pataki fun alafia ati irẹpọ niluu paapaa labẹ idari rẹ.

Koda o mnu ba ifọwọsowọpọ to wa laarin wọn atawọn atawn adari ti sin Islam atawọn ẹsin mii fun ipẹtu saawọ.