Ikú Sylvester Oromoni kò ti ọwọ́ ènìyàn wá ṣùgbọ́n… – Adájọ́

Sylvester Oromoni

Oríṣun àwòrán, RAPID RESPONSE/FACEBOOK/OTHER

Alaga igbimọ oluwadii to n tọpinpin ohun to sọkunfa iku akẹkọọ Dowen College, Sylvester Oromoni, ti sọ pe iku ọmọ ọdun mejila naa ko ti ọwọ eeyan wa.

Adajọ igbimọ ọhun, Mikhail Kadiri, ninu idajọ rẹ to gba odidi wakati mẹfa gbako sọ pe iku oro ni ọmọ naa ku amọ iku ọhun ko ba ma ti waye ti awọn obi ati alagbatọ rẹ ba ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe nipa rẹ ni kankan.

O ni aibikita obi ati alagbatọ ọmọ naa lo papa jẹ ko jade laye.

Ẹlẹrii mẹtalelọgbọn lapapọ lo jẹrii ninu igbẹjọ ati iwadii naa to bẹrẹ lati inu oṣu Kinni, ọdun 2022.

Lara awọn ẹlẹrii ọhun ni awọn obi ọmọ naa, awọn alaṣẹ ile ẹkọ Dowen College atawọn olukọ kan nile ẹkọ naa, to fi mọ awọn akẹgbẹ oloogbe ọhun ti wọn fẹsun kan pe wọn dunkoko mọ.

Awọn mii to tun jẹri lasiko igbẹjọ naa ni awọn ọlọpaa to ṣe iwadii iku oloogbe atawọn akọṣẹmọṣẹ eto ilera.

Ohun to pa Sylvester Oromoni

Lara awọn ẹri ti wọn gbe wa sile ẹjọ ni esi iwadii iku Sylvester ti wọn ṣe niluu Eko ati ilu Warri, nipinlẹ Delta.

Wọn ni lara ohun to pa ọmọ na ni “septicaemia” eyii to yẹ ki wọn tete bojuto ṣugbọn ti awọn obi rẹ ko ṣe bẹẹ lasiko to yẹ.

A gbọ pe awọn ẹbi oloogbe naa nikan lo wa nibi ayẹwo oku rẹ ti wọn ṣe nile iwosan Central Hospital, niluu Warri, nipinlẹ Delta.

Nigba ti awọn oluṣayẹwo mẹwaa, awọn mọlẹbi, ijọba ipinle Eko atawọn alaṣẹ Dowen College peju sibi ayẹwo olu rẹ ti wọn ṣe nile iwosan ijọba Lagos State University Teaching Hospital, to wa niluu Eko.

Adajọ Kadiri sọ pe “ko si ẹri pe wọn lu nnkan mọ oloogbe naa lara rẹ.

“Ayẹwọ ọna ọfun ati ikun rẹ ko fi ẹri kankan han pe o mu kẹmika tabi fin kẹmika kankan simu.

“Nitori naa, iku rẹ ko ti ọwọ eeyan wa.

“Ohun to sọkunfa iku oloogbe ni ‘septicaemia’ lẹyin ti kokoro wọ inu ifun ati ẹdọforo rẹ, eyii to waye latari egbo to wa ni kokosẹ rẹ.”

Ile ẹjọ naa wa rọ awọn obi lati maa fi ọwọ pataki mu eto ilera ọmọ wọn.

Ọgbọn ọjọ, oṣu Kọkanla, ọdun 2021 ni iroyin gbode pe Sylvester Oromi jade laye.