Kí ló n ṣẹlẹ̀ láàrin Sunday Igboho àti Gani Adams tí wọ́n fi n fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kan ara wọn?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Instagram

Ọrọ kan to ti n ja kiri lori ayelujara ti fa ede aiyede laarin Aarẹ Ọnakakanfo Iba Gani Adams, Oloye Sunday Igboho ati Olori osisẹ ijọba nipinlẹ Eko, Tayo Ayinde.

Saaju ni Sunday Igboho ati Tayo Ayinde ti kọwe ẹjọ ransẹ si Iba Gani Adams lati wa wi tẹnu rẹ lori ohun kan to jade nibi to ti n fẹsun kan awọn mejeeji pe wọn ti gba owo lati ṣeku oun.

Fọ́nrán ohun naa ni BBC ko le fidi rẹ mulẹ, sugbọn atẹjade awọn agbẹjọro olupẹjọ mejeeji ti ni ti Aarẹ Gani Adams ko ba ko ọrọ rẹ jẹ pada, awọn yoo pade ni ile ẹjọ.

Agbẹjọro fun Ọ̀gbẹ́ni Ayinde, Adeyinka Olumide -Fusika (SAN) ni ohun naa fẹsun kan onibaara oun lọna aitọ.

O ni Gani Adams sọ ninu fọ́nrán naa pe, Tayo Ayinde fun Sunday Igboho ni N45m lati ṣekupa ohun.”

Gani Adams ti wa fesi jade lori ọrọ naa, to si rọ awọn mejeeji lati ma ri idakẹjẹ oun gẹgẹ bi ti ojo.

‘Didakẹ mi ko ṣe bii ti ojo’

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ fun Gani Adam, Kehinde Aderemi fi lede, o sapejuwe fọ́nrán ohun gẹgẹ bii àdọ́gbọ́n si.

Bakan naa lo ni ẹjọ ti Igboho ati Ayinde pe lo jẹ eyi ti wọn lẹdi apo pọ lati fi ja irawọ Adams ni igboro aye.

“O ti han gbangba pe Igboho ati Ayinde ko fẹ ki alaafia jọba lẹyin ti Ooni, Ọba Adeyeye Ogunwusi ti ba wa sọrọ.”

“Idi ti mo fi dakẹ ninu gbogbo rogbodiyan yii ti Igboho ati Ayinde gbe kalẹ kii ṣe nitori mo jẹ ojo sugbọn nitori ọwọ ti mo ni fun Ooni ti ile-ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi ati awọn oriade mii ni ilẹ Yoruba ti wọn dasi ọrọ yii.

“Sugbọn pẹlu bi irọ ṣe n jade lori ọrọ mi, mo ro pe asiko ti to lati jade sita sọ bii nnkan ṣe jẹ.

“Botilẹ jẹ pe awọn agbẹjọro mi ti ṣe ohun to tọ, mo tun ni lati tan imọlẹ si ohun ti wọn ka silẹ nitori irọ lasan ni, to si jẹ ọrọ kan to waye laarin emi ati aburo ọrẹ mi kan to wa ni America, lọ̀dún 2021..

“Ọmọkunrin ọhun lo da ọrọ naa silẹ pe oun fẹ ki alaafia jọba laarin emi, Igboho ati awọn eeyan kan.

Lasiko ti ijiroro ipẹtu sija ọhun si n lọ lọwọ, ni darukọ awọn eeyan meji naa ninu alaye rẹ.”

Aarẹ Gani Adams fikun pe gbogbo ọrọ nipa Tayo Ayinde to wa ninu ohun naa lo jẹ irọ.