Ipa tí Dọ́là kan sí Naira jẹ́ báyìí yóò ní lára ọrọ̀-ajé Nàìjíríà

Aworan naira ati dola

Oríṣun àwòrán, Getty

Banki apapọ Naijiria, CBN, ti kede pe oun ti ta ẹgbẹrun mẹwaa owo dọla ($10,000) fun awọn ileeṣẹ abaniṣẹwo (Bureau De Change) to forukọ silẹ lọdọ ijọba.

Bẹẹ ni wọn kilọ pe wọn ko gbọdọ ta a kọja ida kan aabọ (1.5%) iye ti wọn ra dọla naa.

B’awọn abaniṣẹwo ba tẹle ikilọ CBN, o ṣee ṣe ki paṣipaarọ owo Naira si dọla ja walẹ si bii N1,270 si dọla kan.

Ninu iwe ikilọ kan ti CBN fi ranṣẹ si ajọ Abaniṣẹwo, wọn ni ileeṣẹ ti ko ba tẹlẹ aṣẹ yii yoo jiya labẹ ofin.

Wọn yoo gba iwe aṣẹ okoowo lọwọ ileeṣẹ bẹẹ, ko ni i le ṣe Bureau De Change mọ.

Igbesẹ yii jẹ ọkan lara ọna ti CBN n gbe lati ro Naira lagbara lọja agbaye, lẹyin towo naa ti ja walẹ tan l’oṣu keji ọdun 2024, to si ku diẹ ko wọ ẹgbẹrun-un meji Naira si dọla kan.

Awọn igbesẹ miran ti CBN tun n gbe ni yiyẹ iṣẹ awọn olokoowo ayelujara( cryptocurreny traders) wo, awọn yii ni wọn n daamu Naira bi CBN ṣe wi.

Sisan awọn ajẹsilẹ gbese ti CBN jẹ awọn banki onibaara (commercial banks) ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn akọṣẹmọṣẹ lori nnkan yii sọ pe ailagbara Naira lo n fa a ti ọwọngogo ọja fi n ṣẹlẹ ni Naijiria.

Wọn ni paapaa julọ nitori pe nnkan ilẹ okeere rira lawọn eeyan wa gbarale ju.

Ẹkunwo ori ọja loṣu keji ọdun yii le ni ida mẹtalelọgbọn (31.7%) bi ajọ to n ri si akọsilẹ rẹ, National Bureau of Statistics, ṣe sọ.

Bí Náírà ṣe lágbára lásìkò yìí yóó mú ẹ̀dínwó bá owó ọjà- Tope Fasua

Onimo nipa isuna, Tope Fasua

Oríṣun àwòrán, Tope Fasua

Akọṣẹmọṣẹ nipa iṣuna owo,Tope Fasua, sọ pe bi Naira ṣe lagbara lasiko yii dara fun gbogbo eniyan.

Fasua sọ pe, ‘’yoo mu adinku ba ọwọngogo owo ọja, nitori awọn eeyan ti wọn n ko nnkan ilẹ okeere wọluu yoo le ra Dọla wọn lowo ti ko nira.”

Ṣugbọn o, Faṣua sọ pe CBN nikan kọ ni yoo mu ki Dọla ja walẹ ki Naira si gun oke.

” Ọwọ gbogbo wa lo wa, gbogbo wa la maa da si i.

Awọn ọmọ Naijiria gbọdọ panupọ pe kawọn to n ko nnkan wọlu lati ilẹ okeere din owo ọja wọn ku.

“B’awọn ti wọn n ko ọja wọle lati oke okun ba lọọ ra’ja lasiko yii, wọn yoo ra a lẹdinwo ju bo ṣe wa ni nnkan bii oṣu mẹta sẹyin lọ, nitori owo dọla ti ja walẹ ju ti tẹlẹ lọ.

’’Fun idi eyi, ko si idi kankan lati maa gbe owo nla leri ọja .

” Tẹ ẹ ba tun wo o bayii, owo epo disu naa ti ja walẹ diẹ ju ti tẹlẹ lọ.

Lawọn ibi kan l’Ekoo, wọn ti n ta a ni N1,300, lati N1,600 ti wọn n ta a tẹlẹ. Ọpọlọpọ nnkan lowo rẹ ti n ja walẹ ṣugbọn ko ti i to.

“Awọn eeyan n yan ara wọn jẹ lorilẹ-ede yii ni, awọn alarobo atawọn alagbata, titi kan awọn to jẹ ọwọ oloko ni wọn ti n ra ounjẹ lai si gàgá kan, kaluku n yanra wọn jẹ bi wọn ba gbe e de ọja.

Gbogbo wa la gbọdọ jọ fẹnu si i ka jọ tun un sọ.”

Kò jọ pé Náírà yóò maa lágbára lọ bó ṣe wà lásìkò yìí

Owo naira

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ni ti Onimọ nipa iṣuna mi-in, Emmanuel Anoliefo, o ni ko jọ pe agbara ti Naira ni lasiko yii yoo maa tẹsiwaju.

O lo ṣee ṣe ko ma pẹẹ rara ti nnkan yoo tun fi pada si bo ṣe wa tẹlẹ.

” Bi nnkan ṣe wa bayii, o ṣi n da bii pe ko le pẹ rara ti naira yoo fi ja walẹ pada, nitori a ko ti i ri awọn aridaju mi-in to n tọka si pe yoo maa lagbara lọ.

‘’Ṣugbọn ko sohun ti ko le ṣẹlẹ ṣaa, a n nigbagbọ pe yoo maa tẹsiwaju bẹẹ.

To ba si ti n lọ bẹẹ, dajudaju, yoo nipa to daa lori owo awọn ọja wa.”

Iyẹn ni iwoye Emmanuel Anoliefo.

Èló ni dọla kan si Naira lonii?

Owo Naira

Oríṣun àwòrán, Getty

Iwadii BBC fi han pe lonii, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹta 2024, N1,416.13 ni dọla kan jẹ si naira.