Ìgbẹ́jọ́ Saheed Shittu, Alfa tó wọ gàù ẹgbẹ́ Ogo Ilorin lẹ́yìn Tani Olohun, yóò wáyé lòníì

Saheed Shittu

Oríṣun àwòrán, SAVE YOUR SOUL TV

Oni, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2024, ni igbẹjọ Saheed Shittu, gbajugbaja alfa ti awọn kan niluu Ilorin gbe lọ sile ẹjọ, n tẹsiwaju.

Ọjọ kẹrinla, oṣu Keji,ni awọn ọmọ ẹgbẹ Ogo Ilorin, Association of Proud Sons and Daughters of Ilorin, gbe Shittu lọsile ẹjọ fun ẹsun ibanilorukọjẹ.

Gẹgẹ bi iwe ipẹjọ ti wọn ka nile ẹjọ ṣe sọ, wọn ni olujẹjọ ọhun jẹ ilumọọka ọdaju eeyan lori ayelujara ti o si n lo “Save Your Soul TV” ati “Saheed Shittu” bi orukọ rẹ lori Facebook.

Iwe ipẹjọ naa tun fi idi rẹ mulẹ pe, Shittu ti ba awọn eeyan jankan jankan ninu ẹsin Islam niluu Ilorin ati awọn ilu mii lorukọ jẹ.

Awọn wọnyi ni, Sheikh Labeeb Adam Al ILory, Sheikh Sulaiman Faruq Onikijipa (Grand Mufti ilu Ilọrin) Sheikh Muhideen Salman (Chief Imam iluu Offa) Sheikh Amahullah Folorunsho Fagba, Sheikh Adam Abdullah Al ILory, Sheikh Kamaldeen Al Adaby ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Iwe naa salaye pe olujẹjọ yii tun tabuku Alh. Adio Muritada Baban Bariga ti o jẹ Aarẹ ẹgbẹ Ogo Ilorin nipa pi pe e ni awọn orukọ buruku ninu fidio rẹ lori ayelujara, eyi to tabuku rẹ lawujọ.

Ẹgbẹ Ogo Ilorin sọ pe awọn setan lati pese ati ṣafihan awọn ẹri fun ẹsẹ ti olujẹjọ naa ṣẹ fun ile ẹjọ lati se ẹjọ naa.

Botilẹ jẹ pe awọn to n ba a ja wa nile ẹjọ, iyalẹnu lo jẹ pe Alfa Saheed Shittu ko farahan nile ẹjọ, bẹẹ ni awọn agbẹjọro rẹ naa ko yọju lati salaye ohun ti o sokunfa aiyọju rẹ.

E yi lo sokunfa bi Adajọ Agba ile ẹjọ Upper Area ti igbẹjọ naa ti n lọ, Magistrate Sunday Adeniyi ṣe pasẹ pe ki ọlọpaa mu u, ki wọn si wọ wa ile ẹjọ lati fesi si ẹsun ti wọn fi kan-an.

Ile ẹjọ sọ pe igbesẹ Alfa Shittu tapa si ofin.

Ẹgbẹ Ogo Ilorin yii kan naa lo ti kọkọ gbe gbajumọ oniṣẹṣe, Abdulazeez Adegbola, ti ọpọ mọ si Tani Olohun, lọsi ile ẹjọ.

Ẹsun ibanilorukọ jẹ ni wọn fi kan ohun naa, eyi to mu ko lo ọpọlọpọ ọsẹ ninu ọgba ẹwọn niluu Ilorin.

Lẹyin ọpọlọpọ oṣu ni wọn to o ri ọrọ naa yanju, nigba to tọrọ aforiji lọwọ wọn.

Wọn ni koda, Shittu ti n ba awọn l’orukọ jẹ ṣaaju Tani Olohun.