Ètò ìdìbò sípò ààrẹ̀ ńlọ lọ́wọ́ lórílẹ̀èdè Zimbabwe

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awọn ara orilẹede Zimbabwe ti bẹrẹ si ni di ibo lati yan aarẹ tuntun .

Eyi n waye pẹlu bi ọwọngogo ṣe gbode kan ni orilẹede naa, ti wọn si fi ẹsun kan ijọba pe wọn gbogun ti awọn alatako.

Iroyin sọ pe ọdun 2017 ni wọn ditẹ gba ijọba lọwọ Aarẹ Robert Mugabe, amọ ọpọ ni nkan ko tii yipada.

Aarẹ orilẹede Zimbabwe, Emmerson Mnangagwa n koju awọn mẹwaa miran ti wọn n dije du ipo aarẹ.

Ohun ti ofin sọ ni pe wọn gbọdọ kede ẹni to jawe olubori laarin ọjọ marun un ti wọn ba dibo tan.

Bakan naa ni ẹni ti yoo di ipo aarẹ mu gbọdọ ti bori pẹlu ida aadọta esi idibo naa.

Awọn wo lo n dije du ipo aarẹ?

Ajọ eleto idibo ni Zimbabwe buwọlu eniyan mọkanla lati dije du ipo aarẹ lorilẹede naa.

Amọ awọn meji to je gbooji ninu awọn oludije naa ni aarẹ Emmerson Mnangagwa lati ẹgbẹ oselu Zanu-PF Party.

Ẹnikeji ti yoo maa gbena woju aarẹ nibi idibo naa ni Nelson Chamisa lati ẹgbẹ osẹlu Citizen’s Coalition for Change(CCC).

Lati ọdun 2017 ni Mnangagwa to jẹ ẹni ọdun ọgọrin ti n dari orilẹede naa.

Korikosun Mugabe ni tẹlẹ ki ija to bẹ silẹ ni aarin wọn, to si fa ki wọn tuka.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn oludije yooku ni ;

  • Joseph Makamba Busha: FREEZIM Congress
  • Trust Tapiwa Chikohora: ZCPD
  • Blessing Kasiyamhuru: ZIPP
  • Lovemore Madhuku: NCA
  • Wilbert Archbald Mubaiwa: NPC
  • Gwinyai Henry Muzorewa: The UANC
  • Harry Peter Wilson: DOP

Tani yoo bori ninu idibo naa?

Ẹgbẹ oselu Zanu-PF ni anfaani lati bori nitori agbara ti wọn ni nitori awọn ni wọn wa ni ijọba, ti wọn si ni agbara ati aṣẹ lori awọn ohun ini orilẹede naa.

Amọ pẹlu eto ọrọ aje to dẹnukọlẹ, awọn ọdọ ti fariga ni awọn ilu ti wọn si n pe fun ayipada.

Kini ohun to gbomi ni ọkan awọn araalu?

Awọn araalu n ke irora lori bi ọwọngogo ṣe gbode kan, ti ohun gbogbo si nira fun awọn araalu.

Amọ awọn ile itaja n koju ina ọba ti ko muna doko ati owo ni abẹle ti ko ṣee mu yangan lori atẹ.

Bakan naa ni owo wọn ti ja wale ni ida mẹrinlelaadọrun laarin Osu Kini si Osu Kẹfa.

Wọn fi ẹsun kan awọn oṣiṣẹ ijọba fun ẹsun iwa ajẹbanu, eleyii to ti mu ki eto ọrọ aje dẹnukọlẹ.

Njẹ eto idibo naa ko ni ni magomago ninu?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ajọ ati ẹgbẹ alatako fi ero wọn han pe ko seese ki eto idibo naa lọ lai si magomago ninu rẹ.

Wọn ni ijọba n gbogun ti awọn ti wọn sọrọ tako wọn ni awujọ.

Wọn ni o kere tan ijọba ti fi ofin de awọn ọmọ ẹgbẹ alatako to le ni ọgọta, ti awọn ọlọpaa si ti se ikọlu si wọn.

Kilo ṣẹlẹ ni idibo ọdun 2018?

Eyi ni igbakeji ti Mnangagwa ati Chamisa yoo maa koju ara wọn lasiko idibo sipo aarẹ.

Ni ọdun marun un ṣẹyin ni wọn koju ara wọn ti wọn si ni ida 50.8 ninu idibo naa.

O kere tan eniyan mẹfa lo ku ninu iṣẹlẹ naa, ti awọn Ajọ awoye EU si ni ijọba n lo ohun alumọni orilẹede naa basubasu.