Ìyá Olórìṣà dèrò àtìmọ́lé ní Ilorin lẹ́yìn tó fi ẹ̀sùn kan Alfa Okutagidi pé òrìṣà òhun ló gbẹ̀bí ìyàwó rẹ̀

Aworan Alfa Okutagidi ati Olorisa ti wọn ko ara wọn lọ si ile ẹjọ

Ile ẹjọ Majisireti kan ni Ilọrin, ti paṣẹ pe ki wọn fi arabinrin, Abẹbi Ẹfunsetan Yakubu ti inagijẹ rẹ n jẹ Olorisa si atimọle lori ẹsun ibanikorukọjẹ ti won fi kan an.

Ẹsun ibanilorukọ jẹ yi niiṣe pẹlu fidio kan to ṣe nibi to ti tabuku Alfa Tonile Okutagidi ati baba rẹ oloogbe Sheikh Awwal Okutagidi to ni wọn wa ṣe iṣẹ aajo lọdọ ohun.

Abẹbi Efunsetan nikan kọ ni adajọ ni ko wa latimọle fun igba diẹ naa.

Arakunrin Obalowu Jimoh to jẹ ẹni to ya fọnran fidio naa to si ṣe alabapin rẹ soju opo ayelujara yoo wa ni atimọle fun igba diẹ titi ti adajọ yoo fi gbẹjọ wọn ni pẹrẹwu.

Ọrọ yi lohun ṣe pẹlu fakinfa to n waye laarin awọn ẹlẹsin ibilẹ ati awọn kan ninu awọn musulumi ni ilu Ilorin.

Bi a ko ba gbagbe ọrọ to fẹ jọ mọ ija ẹsin yi ti n fẹ maa da omi alaafia ru nilu Ilorin nigba tawọn ẹlẹsin Islam lawọn ko fẹ ẹbọ ṣiṣe ni Ilu Ilorin tawọn ẹlẹsin ibilẹ si sọ pe awọn lẹtọ labẹ ofin Naijiri lati ṣe eyikeyi ẹsin to wu awọn

Olori ki ni ẹsun ti wọn fi kan Abebi Efunṣetan

Gẹgẹ bi o se wa ni inu iwe ipẹjọ, (FIR), awọn olupẹjọ, Alfa Tonile Okutagidi sọ pe ohun rii fidio kan lori ayelujara nibi ti arabinrin Abebi ti n ba ohun lorukọ jẹ.

O sọ pe Efunsetan n sọ lori ayelujara pe ohun ṣe iranlọwọ fun iyawo akọkọ Alfa Okutagidi agba to di oloogbe nipa sise etutu ṣaaju ati lẹyin to bimọ tan ni nkan bi ọdun diẹ sẹyin.

Ọrọ yi to tun ta ba baba to bi Khalifa Okutagidi lagbẹjọro fun olupẹjọ sọ pe awọn tori rẹ kesi awọn agbofinro lati wa wọ arabinrin naa lọ siwaju ile ẹjọ majistereeti ni Ilorin.

Nigba ti wọn yoo de iwaju adajọ ti ifọrọwanilẹnuwo si waye, niṣe lo han sita pe arabinrin naa ko mọ Alfa Tonile Okutagidi ri tabi Baba rẹ to tabuku awọn mejeeji papọ.

ASP Samuel Mayowa to gbe ẹjọ yi wa lorukọ awọn agbofinro sọ pe ko si ootọ ninu ọrọ ti olorisa naa sọ pe ọmọ ẹgbẹ olorisa ni baba to bi ohun jẹ.

Nitori idi eyi, o beere pe ki adajọ fi obinrin naa si atimọle nitori pe o n gbero lati da omi alaafia ilu ru ni.

O sọpe ọrọ naa jẹ ọrọ ibanilorukọ ati idarogbodiyan silẹ ti o lodi si section 97, 392 ati 114 ofin pẹna koodi..

Majisireti Muhammed Adams ti o dari igbẹjọ naa gba sii lẹnu tosi sun igbejọ naa si ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹjọ ọdun taa wa yi.

Se lootọ ni pe musulumi ni Abebi tẹlẹ ko to pada di Olorisa

Ni lu Ilorin pupọ lo n ṣe ẹsin Islaamu amọ awọn kan naa wa to jẹ ẹlẹsin Kristẹni ati Oloriṣa amọ wọn ko wọpọ.

Ohun taa gbọ lẹnu ọkan ninu awọn agbẹjọro to ṣoju fun Khalifa Okutagidi ni pe musulumi ni arabinrin Abebi se ko to pada di Olorisa.

A ko ribi fidi ọrọ yi mulẹ lọdọ Abebi Efunṣetan tabi agbẹjọro rẹ.

Alufa Okutagidi to fẹsun kan pe o wa aajo wa si ọdọ rẹ ti ku lati ọdun 2016.

Nigba aye rẹ, o jẹ ilumọọka Alufa Oniwaasi ni Ilorin to maa n tako awọn to pe lẹlẹbọ.

Ipasẹ ti baba Okutagidi agba tọ naa ni ọmọ rẹ Alufa Tonile Okutagidi sọ pe oun n tẹle.

Idi ree ti ọpọ fi n ṣe eemọ nigba ti fidio Efunṣetan jade sita pe awọn to n tako Oniṣẹṣe ni ilu Ilorin wa lara awọn onibara to n wa aajo wa si ọdọ oun.

Majisireti Muhammed Adams ti o dari igbẹjọ naa sun igbejọ naa si ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu ti a wa yii.