Ganduje di alága tuntun fún APC

Ganduje

Oríṣun àwòrán, apc

Gomina ana ni ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje ti di alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, APC lorilẹede Naijiria.

Ni Ọjọbọ ni igbimọ apapọ ẹgbẹ oṣelu APC dibo yan Ganduje gẹgẹ bii alaga tuntun.

Bakan naa ni wọn tun dibo yan agbẹnusọ tẹlẹ fun ile aṣofin agba, Sẹnetọ Ajibọla Bashiru lati ipinlẹ Ọṣun gẹgẹ bi akọwe agba ẹgbẹ oṣelu naa.

Ipade igbimọ to ga julọ lẹgbẹ oṣelu naa waye nilu Abuja.

Ajibọla Bashiru

Oríṣun àwòrán, ajibola bashiru

Ganduje ṣeleri lati rii daju pe ilana eto tiwantiwa ri ẹsẹ walẹ laarin ẹgbẹ oṣelu naa lasiko oun.

O wa ṣeleri iwe iforukọsilẹ igbalode fun awọn ọmọ ẹgbẹ naa ati pe oun yoo mojuto akoso eto idibo ati binukonu laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa.

Aarẹ Bọla Tinubu ati igbakeji rẹ, Kashim Shettima, awọn gomina labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu naa atawọn igi nla ẹgbẹ oṣelu naa wa nikalẹ lasiko ti wn dibo yan Ganduje.

Aarẹ Bọla Tinubu ninu ọr rẹ ṣalaye pe lootọ ẹgbẹ oṣelu APC ti bori idibo to kọja, ohun to ṣe pataki bayii ni ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe awọn ọmọ Naijiria janfani iṣejọba rere .

Ni oṣu keje ni alaga ẹgbẹ oṣelu naa tẹlẹ, Sẹnetọ Abdullahi Adamu ati akswe ẹgbẹ tẹlẹ, Sẹnetọ Iyiọla Omiṣore kọwefipo wọn silẹ.