Mọ nípa àwọn obìnrin mẹ́sàn-án tí Tinubu fẹ́ yàn ní Mínísítà

Àkójọ àwòrán àwọn obìnrin tí Tinubu fẹ́ yàn ní Mínísítà

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/INSTAGRAM

Gẹ́gẹ́ bí àkọ́ọ́lẹ̀ àjọ ìṣọ̀kan orílẹ̀ èdè, àwọn obìnrin kìí sábà sí nípò àṣẹ orílẹ̀ èdè ní àgbáyé àti pé yóò ṣòro díẹ̀ láti rí kí àwọn obìnrin máa léwájú nínú ipò òṣèlú.

Láti ọjọ́ pípẹ́ ni àwọn obìnrin ní orílẹ̀ èdè ti ń pariwo pé wọn kìí fún àwọn obìnrin láàyè láti dipò kan gbòógì mú nínú ètò ìṣèjọba.

Láti ọdún 1999 títí di àsìkò yìí, àwọn obìnrin tí iye wọn jẹ́ 157 ló ti ṣojú ẹkùn wọn nílé aṣòfin àpapọ̀ tí àwọn ọkùnrin sì jẹ́ 2,657.

Lásìkò ìṣèjọba ààrẹ àná Muhammadu Buhari, obìnrin méje pérè ló wà nínú àwọn mínísítà mẹ́tàlélógójì tó bá a ṣiṣẹ́.

Ní báyìí ààrẹ Bola Tinubu náà ti forúkọ àwọn tó fẹ̀ yàn ní mínísítà ṣọwọ́ sílé aṣòfin àgbà, tí àpapọ̀ orúkọ gbogbo wọn sì jẹ́ mẹ́tàdínláàdọ́ta (47).

Nínú àwọn mẹ́tàdínláàdọ́ta yìí, mẹ́sàn-án ni àwọn tó jẹ́ obìnrin tí àwọn yòókù sì jẹ́ ọkùnrin.

Mọ̀ nípa àwọn obìnrin mẹ́sàn-án tí Tinubu fẹ́ yàn ọ̀hún:

Lola Ade John

Lola Ade-John

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Onímọ̀ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ ni Lola Ade-John tó sì jẹ́ àgbà òṣìṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ Novateur Business Technology Consultants.

Ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ibadan ni Lola tí kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ Kọ̀mpútà lọ́dún 1984.

Ó júwe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó nípa ṣíṣe àkóso ìmọ̀ ẹ̀rọ láti fi ṣètò àwọn ilé ìfowópamọ́ káàkiri àgbáyé àti láti mú okoòwò gbèrú.

Betta Edu

Betta Edu

Oríṣun àwòrán, Betta Edu/FACEBOOK

Ní ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹwàá, ọdún 1986 ni wọ́n bí Dókítà Betta Chimaobim Edu ní ìpínlẹ̀ Cross River.

Ọdún 2001 ló parí ẹ̀kọ́ girama rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ Federal Government Girls College, Calabar.

Lẹ́yìn náà lọ tẹ̀síwájú láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbó ní ilé ẹ̀kọ́ gíga University of Calabar, ìpínlẹ̀ Cross River tó sì parí lọ́dún 2009.

Betta tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ lọ sí orílẹ̀ èdè UK àti USA níbi tó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè kejì “Masters” mẹ́ta.

Lọ́dún 2013 ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí dókítà pẹ̀lú iléeṣẹ́ ètò ìlera ìpínlẹ̀ Cross Rivers kó tó di wí pé gómìnà àná ní Cross River, Ben Ayade yàn -án ní olùbádámọ̀ràn lórí ètò ìlera lábẹ́lé láàárín ọdún 2015 sí 2016.

Ayade tún yan Edu bíi kọmíṣọ́nà fétò ìlera láàárín ọdún 2019 sí 2022.

Doris Uzoka Anite

Doris Uzoka Anite

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Ọmọ bíbí ìjọba ìbílẹ̀ Oguta ní ìpínlẹ̀ Imo ni Dókítà Doris Uzoka.

Ní ọdún 2021 ni gómìnà ìpínlẹ̀ Imo, Hope Uzodinma yan Doris gẹ́gẹ́ bí kọmíṣọ́nà fétò ìsúná ìpínlẹ̀ náà.

Akẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìṣègùn ni Doris kó tó di wí pé ó ta kọ́sọ́ sídìí iṣẹ́ ìsúná.

Ní ọdún 2002 ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nílé ìfowópamọ́ títí tó fi gòkè àgbà lẹ́nu iṣẹ́ di alákòóso àgbà fún ilé ìfowópamọ́ Zenith Bank.

Nkiru Onyejeocha

Nkiru Onyejeocha

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Láti ìpínlẹ̀ Abia, ìlà oòrùn gúúsù Nàìjíríà ni Nkiru Onyejeocha ti wá, tí wọ́n sì bi ní ọjọ́ Kẹtàlélógún oṣù Kọkànlá ọdún 1969.

Nkiru ti fìgbà kan jẹ́ kọmíṣọ́nà fún iléeṣẹ́ àkóso ohun àlùmọ́nì àti ìdàgbàsókè ọmọnìyàn ní ìpínlẹ̀ Abia lọ́dún 2002 kí wan tó yàn-án sílé aṣojúṣòfin láti ṣojú ẹkùn Isuikwuato àti Umunneochi lọ́dún 2007.

Ọdín méjìlá ni Nkiru lò nílé aṣòfin tó sì máa ń jà fún fífi àwọn obìnrin sípò òṣèlú.

Ní ọdún 2018 ló darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC nígbà tó fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀.

Lọ́dún 2022 ni ààrẹ àná, Muhammadu Buhari fi oyè da lọ́lá pé ó jẹ́ ìwúrí fún àwọn obìnrin.

Stella Okotete

Stella Okotete

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Delta ni Stella Okotete, tó sì parí ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Benson Idahosa University, ní ìlú Benin.

Láàárín ọdún 2011 sí 2015 ló ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ àti olùbádámọ̀ràn pàtàkì sí gómìnà ìpínlẹ̀ Delta lórí ètò Millenium Development Goals (MDGs).

Ní ọdún 2017 ni Buhari Stella ní adarí ẹ̀ka tó ń rí sí ètò káràkátà nílé ìfowópamọ́ kíkó ọjà wọlé láti ilẹ̀ òkèrè, ipò tó ṣì wà di àsìkò yìí.

Ohun náà ló ṣẹ̀ṣẹ̀ kúrò nípò olórí àwọn obìnrin nínú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progress Congress, APC.

Uju Kennedy-Ohanenye

Uju Kennedy-Ohanenye

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Ọmọ bíbí ìlú Akwa ní ìpínlẹ̀ Anambra ni Uju Kennedy-Ohanenye.

Uju wà lára àwọn tó ń wà ipò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú tí wọ́n juwọ́lẹ̀ fún Tinubu níbi ètò ìdìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ náà tó wáyé nínú oṣù Kẹfà ọdún 2022.

Hannatu Musawa

Hannatu Musawa

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Ọmọ ìpínlẹ̀ Katsina ni Hannatu Husawa.

Ní ilẹ́ ẹ̀kọ́ gíga University of Buckingham, orílẹ̀ èdè UK ni Hannatu ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ òfin.

Bákan náà ló tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa epo rọ̀bì àti afẹ́fẹ́ gáàsì láti gboyè onípò kejì ní ilé ẹ̀kọ́ gíga University of Aberdeen.

Ó tún ti parí ìkẹ́kọ̀ọ́ oyè ọ̀mọ̀wé rẹ̀ báyìí.

Ṣaájú ni Tinubu ti kọ́kọ́ yàn-án gẹ́gẹ́ bí olùbádámọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ àṣà kó tó fi orúkọ rẹ̀ ṣọwọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó fẹ́ yàn ní mínísítà.

Iman Suleiman Ibrahim

Iman Suleiman Ibrahim

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Láti ìpínlẹ̀ Nasarawa ni Iman Suleiman Ibrahim ti wá.

Láàárín oṣù Kejìlá ọdún 2020 sí oṣù Karùn-ún ọdún 2021 ni Iman fi ṣe adarí àjọ tó ń gbógunti fífi ọmọ ṣe ẹrú (NAPTIP) lábẹ́ ìṣèjọba Buhari.

Ìmọ̀ ẹ̀kọ́ sociology ni Iman kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga UniAbuja lẹ́yìn tó kúrò ní ilé ẹ̀kọ́ girama Federal Government College, Bwari, Abuja.

Ní ọdún 2019 ni gómìnà ìpínlẹ̀ Nasarawa yàn-án gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ètò ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ náà.

Òun ni kọ́míṣọ́nà àjọ tó ń rí sí àwọn aṣàtìpó àtàwọn àkàndá ènìyàn.

Maryam Shettima

Maryam Shettima

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM

Maryam Shettima jẹ́ olùdásílẹ̀ àjọ kan tí kìí ṣe ti ìjọba tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ We Believe Movement.

Ọmọ ìdílé oyè ọba ní ìpínlẹ̀ Kano ni Maryam tó sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa Physiotheraphy ní ilé ẹ̀kọ́ Bayero University, Kano.

Ilé ẹ̀kọ́ East London University, Stratford, UK ló ti kẹ́kọ̀ọ́ gba oyè ipò kejì nínú ìmọ̀ “Sports Physiotheraphy.”

Ó ti ṣiṣẹ́ ní àwọn ilé ìwòsàn Dala Orthopedic àti Mallam Aminu Kano tẹ́lẹ̀ rí.