Ìyá àgbà dáná sun ọmọ ara rẹ̀ ọkùnrin, ìyàwó àtawọn ọmọ wọn méjì mọ́lé l’Ondo

Oloro Victor

Oríṣun àwòrán, Comrd Lucky Franca Ijeoma

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti fi ṣikun ofin mu iya ẹni ọdun márùndínlọ́gọ́rin kan lori ẹsun pe o dana sun ọmọ rẹ ọkunrin, iyawo ọmọ rẹ naa atawọn ọmọ wọn meji mọle.

Iya agba naa, Iforiti Oloro, n gbe pẹlu ọmọ rẹ ọhun ati ẹbi rẹ niluu Aponmu, to wa lopona ilu Akure si Ondo.

Iroyin ni asiko ti awọn oloogbe naa n sun ni afurasi ọhun lọ dana sun ile tin wọn wa.

Aago meji oru ni iṣẹlẹ maa waye

Ẹnikan ti ọrọ naa ṣoju rẹ, Korede Michael sọ pe ṣadede lawọn ri ile awọn eeyan naa to n jo ni nnkan bii aago meji oru, ki wọn to ja ferese ile naa lati yọ awọn to wa ninu rẹ.

O ni “Iya agba naa, ọmọ rẹ to n jẹ Victor Oloro, iyawo rẹ Rachael atawọn ọmọ wọn, Toluwani ati Blessing lo wa ninu ile nigba to sọ ina sibẹ.”

Oloro Micheal

Oríṣun àwòrán, Andrew Jerry

“O wa awọn imọ ọpẹ kan, o da epo bẹntiro si, o fi yi ile naa ka, o si sọ ina si.”

“Emi ni ẹni akọkọ to ri ina ọhun, ti mo si lọ sibẹ ki awọn eeyan to wa layika to darapọ mọ mi lati doola wọn.”

“Wọn ti jona kọja ala”

“Lẹsẹ kan naa ni a ko wọn sinu ọkọ ti a si gbe wọn lọ sile iwosan ijọba to wa niluu Akure.”

Korede sọ siwaju si pe nigba ti wọn yoo fi dele iwosan ijọba, UNIMED niluu Akure, wọn ni ki awọn gbe wọn lọ sile iwosan ijọba apapọ, FMC, to wa niluu Ọwọ nitori ina ọhun ti jo wọn kọja ala.

O ṣalaye siweaju si pe “O ṣeni laanu pe ọmọ abikẹyin ku ni kete ti a de ilu Ọwọ.”

“Lọjọ Isinmi, ọmọ iya agba naa ati iyawo rẹ jade laye nigba ti ọmọ kan ṣoṣo to ku wa ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun.”

Iya agba ọhun, Iforiti ko farapa ninu ina naa rara.

Amọ awọn eeyan adugbo ni iya agba naa ti kọkọ gbiyanju lati gbẹmi ara rẹ lọdun 2022 nigba to ko sinu kọnga.

Korede ni “Awọn ọmọ rẹ ko le ni ko kuro ninu ile naa lẹyin to bẹrẹ si n ṣiwa wu nitori ọkọ rẹ to ti di oloogbe lo kọ ile naa.”

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami to fidi iroyin naa mulẹ fawọn akọroyin sọ pe awọn ti tare ẹjọ naa si ẹkọ to n ṣewadii iwa ọdaran, SCID.