Ìdí tí mi ò fi kí ń ṣí ìhòhò ara mi sílẹ̀ tí mo sì yàn láti máà múra bí ọkùnrin ni pé … – Teni the Entertainer

Yoruba bọ wọ́n ni bí fingbáfingbá kò bá fingbá mọ, èyi to tí fin silẹ̀ kò ni parún.

Tení Apata ti gbogbo ènìyàn mọ si Teni Entertainer lo maa n sere ati orin daadaa fun igbadun awọn ololufẹ rẹ sùgbọ́n ǹkan ti ọpọ n sọ nipa Teni ni o bi iroyin yii.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọlólùfẹ́ Teni lórí àtẹjiṣẹ́ twitter lo ti n yin Tẹ́ni pàápàá jùlọ lóri ìmúra rẹ lásikò to ba n ṣe àyẹyẹ orin àti ní gbogbo ìgbà.

Ọ̀rọ̀ yìí wá di gbigbà bi ẹni gba igbá ọti nígba ti @Benita_Fairy kọ pé Teni fí han pé àwọnn obinrin ọlórin lé ṣe àṣeyori lái ṣí ìhòhò wọ́n sílẹ̀

Ní kété to sọ èyí tan ni àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ si ni gbàá bi ẹni gba igbá oti, bi àwọn kan ṣe ni kìí ṣe oun nikan ni kìí ṣí ìhòhò rẹ̀ sílẹ̀ ní àwọn míràn ni iṣe ọkunrin lo n ṣe ni kìí ṣe ṣi ara silẹ̀.