Wo àwọn obìnrin tó wọlé sílé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní Kwara, Ondo, àti Ekiti

Elections 2023

Oríṣun àwòrán, others

Lẹyin ti esi idibo gomina bẹrẹ si jade, ọp awọn obinrin lo pegede ninu idibo naa, nigba ti awọn mii lulẹ.

Lara awọn obinrin to pegede ni Rukayat Motunrayo Shittu, lati ẹkun idibo Owode/Onire, nipinlẹ Kwara.

BBC ṣe akojọpọ awọn obinrin to yege ninu idibo sipo aṣofin ipinlẹ ni Ondo, Ekiti ati Kwara.

Obírin mẹ́ta wọlé sípò aṣòfin l’Ondo fún ìgbà àkọ́kọ́

Esi ibo ti ajọ INEC fi lede ninu idibo ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ondo lo ti fihan pe obirin mẹta ni wọn jawe olubori ninu idibo to waye nipinlẹ naa.

Eyi ni yoo jẹ igba akọkọ ti obirin yoo pe mẹta nile igbimọ ẹlẹni mẹrindinlogun to n ṣofin nipinlẹ ọun.

Awọn obirin naa ni Morenike Witherspoon (Owo 2), Oluwatosin Ogunlowo (Idanre) ati Olawunmi Fayemi (Ilaje 2) ti gbogbo wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Awọn obirin mẹtẹẹta ni wọn wa lara awọn mejilelogun ti yoo jẹ ọmọ-ile fun igba akọkọ ti saa wọn ba bẹrẹ loṣu kẹfa ọdun yi.

Ninu awọn mẹrindinlọgbọn yi wọn yoo jọ maa ṣe ofun fun ipinlẹ Ondo fun ọdun mẹrin, awọn mẹrin pere ni yoo pada ba wọn joko ninu awọn ọmọ-ile to wa nibẹ lọwọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bo tilẹ jẹ pe awọn mẹjọ ni wọn dije lati pada, Oluwole Ogunmolasuyi (Owo 1), Olamide Oladiji (Ondo East), Ololade Gbegudu (Okitipupa 2) ati Abayomi Akinruntan (Ilaje 1) nikan lo jawe olubori ti gbogbo wọn si wa lẹgbẹ APC.

Taofeeq Muhammed (Akoko Northwest 2) ati Toluwani Borokini (Akure South 1) ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ APC, to fi mọ Tomide Akinrinbido ti ẹgbẹ PDP (Ondo West 1) pẹlu Favour Tomomewo ẹgbẹ ADC (Ilaje 1) ni wọn kuna lati ri ibo to le dawọn pada sile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa.

Ẹgbẹ oṣelu APC lo ni ọmọ-ile to pọju lọ pẹlu ijoko mejilelogun ti ẹgbẹ oṣelu PDP si ko ijoko mẹrin to ku.

Igba-le-mẹjọ ni awọn to dije lẹgbẹ oṣelu metadinlogun fun ijoko mẹrindinlọgbọn to wa nile igbimọ naa.

Obninrin mẹrin jawe olubori ni Kwara

others

Oríṣun àwòrán, others

Obinrin mẹrin lo jawe olubori nibi esi ibo ijọba ipinlẹ ti ajọ INEC fi lede ni ipinlẹ Kwara.

Awọn obinrin yi ni, Olatundun Alanamu, Ilorin North/West, Arinola Lawal, Ilorin East, Mariam Yusuf Aladi, Ilorin South) ati Rukayat Shitu, Owode/Onire) ti osi jẹ ọmọ ile to kere julọ ni orilẹ-ede Naijiria

Eyi kọ ni igba akọkọ ti obinrin yoo wa ni Ile Igbimo Asofin ipinle Kwara ṣugbọn eyii ni akọkọ ti obinrin yoo wa lati ẹkun aringbugbu ipinlẹ naa.

Ẹsin Musulumi ni lo gbajumọ julọ ni ẹkun aringbugbu ipinlẹ naa ti ko si fi taratara gba ki obinrin jẹ olori, ṣugbọn ijawe olubori awọn mẹrin yii jẹ ara ọtọ ati iyalẹnu.

Gbgbo awon obinrin yii lo jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, wọn si maa darapọ mọ awọn akẹgbẹ wọn fun saa akọkọ.

Gbogbo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ ni Kwara jẹ mẹrinlelogun, ẹgbẹ oṣelu APC ni ọmọ ile mẹtalelogun ti PDP si ni ijoko kan pere.

Ipinlẹ Ekiti

Ekiti election

Oríṣun àwòrán, others

Awọn obinrin to jaweo olubori sipo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ekiti ree:

  • Ado 11 Constituency: Olagbaju Bolaji
  • Aiyekire/gbonyin: Okuyiga Eyitayo Adeteju
  • Efon Constituency: Olowookere Bosede Yinka
  • Emure Constituency: Ogunlade Mariam Bimbola Funmilola
  • Ilejemeje Constituency: Okiemen Fakunle Iyabode Lydia
  • Moba I: Solanke Christiana Abimbola

Osun

Nipinlẹ Osun, ko si obinrin kankan to jawe olubori sipo aṣofin nibẹ.