Ìdí rèé tí mo fi ní kí wọ́n gbé àmì ẹ̀yẹ tó n dá wáhàlá sílẹ̀ fún Bobrisky – Eniola Ajao

Eniola Ajao

Oríṣun àwòrán, Eniola Ajao/Facebook

Gbajugbaja oṣere tiata nii, Eniola Ajao ti ṣorọ nipa aweuyewuye to n tẹyin fifi ami ẹyẹ da Bobrisky lọla gẹgẹ bi obinrin to mura julọ nibi afihan sinima Eniola to gbe jade iyiun ‘’Ajanaku: Beast of Two Worlds’’

Eniola Ajao salaye idi ti oun ati awọn akẹgbẹ rẹ fi pinnu lati fun Bobrisky ni ami ẹyẹ gẹgẹ bi obinrin to mura ju wa si bi ifilọlẹ naa.

Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu Arise News, Ajao jẹ ko di mimọ pe tori kawọn baa le ṣe ipolongo ati ipolowo sinima yi lawọn fi mọọmmọ gbe ami ẹyẹ yi fun Bobrisky.

O ni awọn mọ pe Bobrisky jẹ ilumọọka, ti wọn si lero pe fifun ni ami ẹyẹ yoo gbe sinima naa larugẹ.

O ni bi awọn kan ṣe n fi ọrọ buruku ransẹ si Femi Adebayo ko dun mọ oun ninu nitori o wa ran oun lọwọ lati ṣe sọrọsọrọ nibi ayẹyẹ naa ni.

“Awada lasan ni, a fẹ ki awọn eeyan ma sọrọ nipa sinima naa. Ẹmi ati awọn akẹgbẹ mi pinnu pe taa ba fẹ ki awọn eeyan ma sọrọ nipa sinima yii, a ni lati fun Bobrisky ni ami ẹyẹ nitori iru eeyan to jẹ.

“Ni igbẹyin, awọn eeyan n sọrọ nipa rẹ sugbọn wọn sọrọ si Femi Adebayo to jẹ ọga mi. Koda ko mọ nkankan nipa isẹlẹ yii, emi ni mo ransẹ pe ko wa bami kede ẹni to gba ami ẹyẹ naa.”

Ajao wa tọrọ aforijin lọwọ Femi Adebayo pe ko ma binu si bi ọrọ naa ṣe da, to si rọ Dayo Amusa ati awọn yooku pe ki wọn ma ṣe fi ọrọ naa ṣe ibinu mọ.

Ki lo fa ija gan an?

Ọjọ Aiku ọsẹ yii nibi ifilọlẹ sinima naa, ni Bobrisky la gbajumọ oṣere bi Toyin Abraham, Mercy Aigbe, , Sola Sobowale ti wọn ro dẹdẹ nibi afihan sinima yii mọlẹ lati gba ẹbun owo miliọnu kan Naira.

Lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹta ni eto yi waye ni Circle Mall lagbegbe Lekki nilu Eko.

Aṣọ dudu rẹ to n tana yẹriyẹri ti Bobrisky ko si lo mu ki awọn adajọ idije ranpẹ naa gbade fun.

Sugbọn ọrọ yii ko dun mọ ọpọ ninu, ti wọn si bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa pe, ko yẹ ki ọkunrin to n mura bi obinrin le gba ami ẹyẹ naa.

Awọn oṣere bi i Toyin Abraham, Dayo Amusa ati awọm mii lo koro oju si igbesẹ naa.

Kaakiri loju opo ayelujara si ni awọn eeyan ti n tẹnu bọ ọrọ Bobrsiky yi tawọn oṣere ati gbajumọ oju opo ayeluajara naa si ti n da si.

“Bẹẹ ni mo gbọ pe wọn gbe ami ẹyẹ fun Bobrisky pe oun ni obinrin ti imura rẹ ta lẹnu julọ.Ṣe obinrin tootọ abi ayederu obinrin ni?”

Ibeere ree lẹnu olorin nii Portable gẹgẹ bo ṣe wi ninu fọnran fidio kan to fi soju opo ayelujara.

Bawo ni ti Femi Adebayo ati Iyawo rẹ ṣe jẹ ninu ọrọ yii?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Instagram

Gbajugbaja oṣere tiata, Femi Adebayo ni o gbe ami ẹyẹ naa fun Bobrisky, ti ọpọ si ti n bu ẹnu atẹ lu lati igba naa pe ko yẹ ko gbe igbesẹ naa.

Lara wọn ni Oṣere Nollywood ti awọn eeyan mọ bi owo nii, Dayo Amusa to sọ pe inu ohun ko dun pe ọkunrin to mura bi obinrin lo gba ami ẹyẹ naa.

O bu ẹnu atẹ lu awọn adajọ ati awọn to ṣe agbekalẹ ifilọlẹ naa, pe wọn ko ṣe daa.

”Mo maa lọ si ibi afihan sinima akẹgbe mii kan ni lana ti wọn si lawọn fẹ fami ẹyẹ da obinrin ati ọkunrin to mura julọ lọla.Ẹ ma ṣi mi gbọ o, ko si laburu ki wọn fun ẹni to ba pegede lami yi ṣugbọn ọkunrin to n mura bi obinrin ti ṣe jẹ,Ki lo n daamu wa na? Ko ye mi o”

“Mi o gbọdọ ṣo pe awọn adajọ tabuku awọn obinrin to wa nibi yi.Wọn ni kẹ mu ọkunrin kan ti obinrin kan, ẹ wa fọwọ rọ gbogbo wahala awọn agbatẹru eto yi danu pẹlu bi ẹ se gbe ọmọ ọba fọsun.Ki lo n daamu wa gaan?”

Ọrọ yi lo bi Aduke Adebayo to jẹ iyawo Femi Adebayo ninu, ti o si bẹrẹ si ni gbe lẹyin ọkọ rẹ.

Nigba to n fesi, Aduke Adebayo sọko ọrọ si Amusa pe o n gbero lati fi ẹnu ba ti ọkọ oun jẹ.

O sọ di mimọ pe ọkọ oun kan gbe ami ẹyẹ kalẹ, oun kọ lo mu Bobrisky gẹgẹ bii ẹni to mura ju.

Ọrọ yii ni ko dun mọ Dayo Amusa ninu, ti oun naa si bọ sori ayelujara lati fun Aduke lesi ọrọ.

Aworan ọrọ  ti Aduke iyawo Femi Adebayo fọ lesi fun Dayo Amusa

Oríṣun àwòrán, Instagram/Iyaladuke

Aworan ọrọ ti Dao Amusa kọ soju opo rẹ ni Instagram

Oríṣun àwòrán, Instagram/dayoamusa

Nigba to n sọrọ, Femi Adebayo ni oun sẹsẹ ri idi ti Dayo Amusa fi n bu ẹnu atẹ lu oun, eyi ti ko sẹyin pe ko fẹran oriire oun.

O rọ Dayo Amusa lati lo okun rẹ si nnkan miiran nitori ọrọ ẹnu rẹ ko ni nnkan ṣe fun oun.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Instagram

Bakan naa ni ẹgbẹ awọn oṣere Yoruba ti wọn jẹ ọkunrin AFRIMEK ti fi atẹjade sita lati gbe lẹyin Aarẹ ẹgbẹ naa.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Adeniyi Johnson fi lede, wọn salaye pe Femi Adebayo ko ki n ṣe ẹni abuku rara ti ẹnu kan le ma fi kọrọ sọ.

ADRIMEK ni Femi Adebayo ko mọ nipa bi wọn ṣe fun Bobrisky ni ami ẹyẹ nitori Musulumi ododo, ti irufẹ iwa bẹẹ ko si ba ẹsin rẹ mu.

Skip Instagram post

Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Content is not available

View content on InstagramBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.