“Àrọwà Makinde ni kò jẹ́ kí Ibadan ti gbóná fún ìwọ́de, àìsì owó ti ṣàkóbá fún okoòwò wa”

Ile ifowopamọ

Isoro ọwọn gogo Naira to n ba ọpọ ọmọ Naijiria finra ko yọ awọn olugbwe ilu Ibadan, tii se olu ilu ipinlẹ Oyo silẹ.

Ikọ iroyin BBC Yoruba jade si igboro lati mọ bi awọn Ile ifowopamọ ṣe n ṣiṣẹ si ni awọn agbegbe bii Iwo road, Challenge, Dugbe, Mokola ati Awolowo Avenue ni Bodija.

Akọroyin wa jabọ wi pe Ile ifowopamọ First Bank nikan ni ko sise ni awọn agbegbe naa.

Ni gbogbo Ile ifowopamọ ti a ṣe abẹwo si, ni ẹrọ to n pọ owo, ATM ko ti ṣiṣe rara, sugbọn ti wọn fun awọn eniyan ni nọmba lati to wọ Ile ifowopamọ nitori ọpọ ero to wa nibẹ.

“ATM to n pọ ẹgbẹrun mẹwaa tẹlẹri, ko fun ẹnikẹni ju ẹgbẹrun marun un Naira lọ mọ”

Ọkan lara awọn eeyan to ba wa sọrọ, Arakunrin Michael Oluṣesan to je ontaja nilu Ibadan ṣe alaye wi pe ọwọngogo owo ti se ipalara fun okoowo oun, ti ko si yẹ ki o ri bẹẹ rara.

O ni odidi ọjọ mẹta ni oun fi n paara ile ifowopamọ lati le gba kaadi tuntun ti wọn fi n gba owo lẹnu ẹrọ, ṣugbọn pabo ni gbogbo igbiyanju rẹ ja si.

O fi kun ọrọ rẹ wi pe arọwa ti Gomina Ṣeyi Makinde pa si awọn araalu lo mu ki wahala rọlẹ diẹ.

Oluṣẹsan ni ohun iyalẹnu lo jẹ wi pe ẹrọ ATM to n pọ ẹgbẹrun mẹwaa tẹlẹri, ko fun ẹnikẹni ju ẹgbẹrun marun un Naira lọ mọ.

Wahala to si n bẹ ninu ki a wọle gba owo nile ifowopamọ ko ni jẹ ki enikẹni tiẹ gbiyanju ẹ wo.

Ẹlomii ti o ba wa sọrọ, Itunu Raji naa ṣe alaye ohun ti oju rẹ ri nile ifowopamọ gẹgẹ bi o ṣe n ji de ibẹ lati aago mẹfa idaji lai gba ju ẹgbẹrun mẹwaa Naira lọ.

O wa ke si ijọba ati awọn to n bẹ ni ibi iṣakoso owo lati wa ojutuu si ipenija naa.

Ìwọ́de ńlá ń bọ̀ bí kò bá sí ojútùú sí ọ̀wọ́n gógó epo àti Naira – Àwọn ọdọ́ Akure yarí

Ifehonuhan Akure

Leyin ifẹhonuhan to ti n waye kaakiri awọn ipinlẹ ni orilẹ-ede yii.

Awọn ọdọ ilu Akure lonii ọjọ kẹjọ oṣu keji ṣe iwọde lati fi aidunnu wọn han si owongogo epo bẹntiro ati aisi owo naira tuntun

Awọn akẹkọọ, ọdọ ati awọn oniṣe ọwọ ni wọn fi orisirisi nkan di opopona marosẹ to wa ni ilu Akure.

Opopona naa ni awọn arinrin-ajo to n lọ si apa oke Ọya n gba kọja.

Ninu ọrọ rẹ, Ilesanmi Ademola to jẹ ọkan lara awọn akẹkọọ to n sewọde naa ni, bi erongba ijọba apapọ ṣe dara to lori titẹ owo tuntun naa ṣugbọn, ọna ti wọn gbe gba mu inilara ba awọn ara ilu.

Ilesanmi ni banki apapọ orilẹ-ede yii (CBN) ko ṣe idanilẹkọọ to fun awọn to wa ni ẹsẹ kuku eyi to fa inira laarin awọn oni kata kara ni igboro Akure.

IFEHONUHAN AKURE

“Awa akẹkọọ yoo se iwọde alagbara kaakiri Naijiria bi ijọba ko ba wa ojutu si ọwọn epo ati Naira”

Nigba ti wọn bu ẹnu atẹ lu owon gogo epo bẹntiro, Ilesanmi ro ijọba apapọ ati ijọba ibilẹ lati gbe ajọ ti yoo fofin de awọn ile epo aladani lati maṣe tá epo bẹntiro kọja ala silẹ ijọba apapọ.

Ogunmola Mathew alaga awọn ọdọ ni ipinlẹ Ondo nii ifẹhonuhan alafia ni awọn ṣe nitori awọn igbesẹ ijọba ko tẹ awọn lorun.

Babatunde Afeez to jẹ igbakeji alaga ẹgbẹ akẹkọọ ni iṣoro airowo gba ni awọn ile ifowopamọ, bẹẹ ni iya ati ri epo bẹntiro ra lọ sun awọn akẹkọọ lati darapọ mọ ifẹhonuhan naa.

Babatunde ni ti ijọba apapọ ko ba fi opin si hilahilo yii ki ọṣe yii to pari, awọn akẹkọọ yoo tẹsiwaju iwọde alagbara kaakiri orilẹ-ede yii.

Àwọn ọ̀dọ́ fi tírélà dí ọ̀nà, wọn fẹ́ sun báńkì bí ìwọ́de ṣe gbòde kan ní Abeokuta àti Akure

Ifẹhonuhan

Iroyin to n tẹ wa lọwọ lati ọdọ awọn akọroyin wa to wa nilu Abeokuta salaye pe akọtun ifẹhonuhan miran tun ti bẹrẹ ni owurọ oni Ọjọru nilu naa.

Ohun tawọn ọdọ to jade se ifẹhonuhan naa n fariga le lori ni bi ko se si owo beba Naira ni arọwọto, ti epo bẹntirolu si di imi eegun.

Saaju la ti kọkọ mu iroyin wa fun yin nipa irufẹ iwọde naa to waye lọjọ Isẹgun nilu Abeokuta, Benin ati Oyo lori ọwọn owo Naira ati epo naa.

Awọn ọpọ naa, to pọ pupọ, ni wọn n kọrin lati beere fun atunse sawọn isoro yii.

Awọn ọdọ gbiyanju lati jo banki nina ni Sapon amọ awọn agbofinro ko jẹ

Ifẹhonuhan naa to bẹrẹ ni owurọ kutukutu, si lo se akoba nla fawọn akẹ́kọ̀ọ́ to n lọ sile ẹkọ nitori awọn mìíràn ninu wọn padà sílè.

Bakan naa ni awọn ontaja to wa lawọn sọọbu to wa lawọn agbegbe ti iwọde ti n waye, tí ọjà wọn pa.

Àwọn ọdọ náà to n se iwọde ọhun nilu Abeokuta, ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ ifẹhonuhan wọn láti agbegbe Obantoko, Asero, Sapon, Iyana Mutuary títí lọ de Ijaye lọ sì Panseke àti òkè Ilewo.

Awọn ọdọ naa da iná sí ojú pópó kakiri, ti wọn si gbìyànjú láti dáná sún ilé ifowopamo GTB to wa ni Asero amọ ko seese fun wọn tori awọn agbofinro.

Bakanna ni wọn ba opolopo ń kan jẹ́ nílé ifowopamo First Bank tí ó wà ní Ọja Sapon.

Àwọn ọlọpa àti àwọn òṣìṣẹ́ alaabo mii ni wọ́n ti ń dena wàhálà àti iwode náà báyìí.

Eto lílọ bibọ sì ti ń padà bọ sípò báyìí ni àwọn ọjà kakiri ìlú Abẹ́òkúta.

Ẹni ti ọta ibọn ba

Ọkunrin to fara gbọta nibi iwọde Abeokuta ko ku, o n gba itọju nile iwosan

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ibọn ba ọkunrin kan lasiko iwọde iwọde to waye nilu Abeokuta lọjọ Isegun.

Fidio ọkunrin naa to n ja rain kiri lori ayelujara, lo safihan bo se n sare lọ lẹyin ti ibọn ba ni apa.

Se ni ẹjẹ kun gbogbo ara ọkunrin naa, ori lo si ko yọ ti ko ja sinu koto nla kan lasiko to fẹ rekọja koto naa.

Ọpẹlọpẹ awọn eeyan to sugba ọkunrin naa, ti ko jẹ ko subu, to si foju han pe o ti daku l rangbọndan.

Amọ ninu irinajo akọroyin BBC yika ilu Abeokuta, a gbiyanju ọkunrin naa lati mọ boya o ye isẹlẹ naa.

Ọkunrin naa, ti orukọ rẹ n jẹ Mikel naa si lo wa laaye, ti ko si ba ọgbẹ ọta ibọn naa lọ.

Lọwọlọwọ bayii, Mikel ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ ni ile itọju aláìsàn tí Federal medical Centre, FMC to wa ni adugbo Idi Aba Abeokuta.