Fáṣítì Unical ní kí Ọjọgbọn Ndifon lọ fìdímọ́lé lórí ẹ̀sùn fífipá bá àwọn kẹ́kọ̀ọ́ lòpò

Aworan Fásítì Calabar

Oríṣun àwòrán, Google

Awọn alasẹ faṣiti Calabar nipinlẹ Cross Rivers, tí kede pe awọn ti ki Ọjọgbọn Cyril Ndifon, ti ẹka ofin lọ rọkun nile lori ẹsun pe o n fi ibalopọ lọ awọn akẹkọọ.

Fasiti ọhun ni Ọjọgbọn Ndifon ko gbọdọ lọ si agbegbe ikọwe ni fasiti naa lẹyin ipade pajawiri ti wọn ṣe.

Ijiya yìí lo waye lọjọbọ ọsẹ yìí lẹyin ti igbimọ iwadi bẹrẹ isẹ lori ẹsun ti awọn akẹkọọ obìnrin fi kan Ọjọgbọn naa lọjọ Aje

Ninu fọnran kan to gba ori ayelujara lọjọ Aje níbi ti awọn akẹkọọ tí yabo ọfisi Ọga agba fun fasiti naa, Ọjọgbọn Florence Obi ti wọn si n kigbe fita fita o ti su awọn.

“Ndifon gbọdọ lọ”, “O ti su wa bí àwọn olukọ ko se wa si kilasi “,”O ti suwa lati ma ra iwe”, ” Awọn akẹkọọ obinrin kii se ohun ọfẹ; Kí Ọjọgbọn Ndifon ye mu wa sọwọ ati awọn yooku.”

Ninu ọrọ rẹ, Ọjọgbọn Ndifon ni irọ ni awọn akẹkọọ naa n pa, to si ni ìwọde to waye ko sẹyin awọn eeyan kan ni ile ẹkọ naa to fẹ rí ẹyin ohun.

Ninu atẹjade tí Agbẹnusọ ile ẹkọ ọhun, Eyo Bassy fi lede ni esi Ọjọgbọn Ndifon ko tẹ Ọga agba fasiti lọrun to si palasẹ pe ko yẹra kuro ni ile ẹkọ naa, ko si fi ipo rẹ silẹ.

“O ko gbọdọ wa si fasiti, ayafi ti igbimọ iwadi ba ransẹ si ẹ pe ko wa.”

Irufẹ iṣẹlẹ yìí to ti waye tẹ́lẹ̀rí

Lọdun 2019, awọn alasẹ faṣiti Eko kede pe ki Omowe Boniface lọ rọọkun nile.

Lẹyin ti ile iṣẹ BBC gbe iwadii wọn sita lori awọn olukọ kan nile iwe giga iwọ oorun ilẹ Adulawọ ti wọn n beere fun ibalopọ ṣaaju maaki ni oriṣiiriṣii nkan ti n ṣẹlẹ.

Iṣẹ iwadii BBC yii ṣafihan olukọ ni fasiti ijọba apapọ ni Eko ati ni Ghana ni eyi to ti n tu aṣiri oriṣiiriṣii sita.

Bakan naa ni fasiti Obafemi Awolowo ti Ile Ife lọdun 2021, Olukọ Olabisi Olaleye ni isẹ bọ lọwọ rẹ lẹyin ti akẹkọọ ipele kẹrin International Relations fẹsun kan pe o gbero lati ba òun ni ajọsepọ.

Akẹkọọ ọhun ni Olukọ Olaleye kọ lati fun oun ni maaki ninu ọkan lara ẹkọ to n kọ akẹkọọ naa.

Fasiti orilẹede Naijiria gba isẹ lọwọ Olukọ Chigozie Odum lẹyin ti akẹkọọ obìnrin kan fẹsun kan lori ifipanilopọ.