Binta Ayo-Mogaji, Fathia Balogun, Sola Kosoko ṣèdárò ‘Bufallo’, àgbà òṣèré tó kú

Aworan Musiliu Ajikanle ati Ayo Mogaji

Oríṣun àwòrán, Instagram

Agba oṣerebinrin, Ayo Mogaji ti banujé lori ipapoda gbajumọ osere tiata, Musilu Ajikanle,, ti ọpọ mọ si Buffalo ẹni to jade laye ni ana ode yii.

Mogaji ninu ọrọ to kọ sabẹ iroyin to kede iku oṣere ni ko ti pe ọsẹ meji sẹyin ti oun kese Bufallo pe ko fi nọmba akanti rẹ ransẹ sugbọn ko pada se bẹẹ.

“Mo ba sọrọ ni ko ti pe ọsẹ meji, ti mo ni ko fi nọmba akanti rẹ ransẹ si mi sugbọn ko fi ransẹ,”

Bakan naa ni awọn agba oṣere miiran bi FaIthia William Balogun ati Sola Kosoko ti ramsẹ ibanikẹdun si awọn mọlẹbi oloogbe naa.

Iroyin ni oju oorun ni Musilu Ajikanlẹ gba jade laye ni alẹ ọjọ Aiku, ti iroyin si n waye lẹyin ti Pasitọ Gabriel gbe owo toto milọnu mẹta kalẹ fun eto ilera rẹ.

Musilu Ajikanlẹ ti pẹlu awọn osere miiran bi Murphy Afolabi, Fadeyi Oloro, Iyabo Oko ati awọn mii to ti jade laye lọdun 2023.

Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, Musiliu Ajikanle jáde láyé

Musiliu Ajikanle

Oríṣun àwòrán, Agbala Gabriel

Ní ọjọ́ Ajé ni ikú tún ṣọṣẹ́ ní agboolé tíátà bí Musiliu Ajikanle tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Buffalo ṣe dágbére fáyé lẹ́yìn ọdún méje tó ti ń bá àìsàn rọmọlápá rọmọlẹ́sẹ̀ fínra.

Òṣèré tíátà mìíràn, Saliu Gbolagade tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí, Ogboluke ló fi ìròyìn náà sórí Instagram rẹ̀.

Ogboluke nígbà tó fi àwòrán òṣèré náà sórí Instagram rẹ̀ kọ ọ́ sábẹ́ rẹ̀ pé ọ̀dọ̀ ọlọ́run láti wá, ọ̀dọ̀ rẹ̀ náà sì ni a máa padà sí.

Ó ní ipa Musiliu Ajikanle lórí ilẹ̀ ayé yìí kò ṣe fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn rárá àti pé ìfẹ́ rẹ̀ kìí ṣe ohun tí òun le gbàgbé láéláé.

Ó gbàdúrà kí Ọlọ́run tẹ Ajikanle sí afẹ́fẹ́ rere.

Ẹ ó rántí pé ní bí ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn ni Agbala Gabriel fi àwòrán àgbà òṣèré yìí sórí ayélujára tó sì ń bèèrè fún ẹni tó bá nímọ̀ nípa òṣèré náà.

Agbala Gabriel padà fi sórí ẹ̀rọ Facebook rẹ̀ pé Ajikanle padà kàn sí òhun àti pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní gba owó jọ fún òṣèré náà láti ṣe ìtọ́jú àìlèra tó ń ba fínra.

Ó ní nígbà tí òun dé ilé Ajikanle ní Oje, ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo, ó sọ fún òun pé láti ọdún kèje sẹ́yìn ni àìsàn rọmọlápá rọmọlẹ́sẹ̀ ti dá òun dùbúlẹ̀.

Ní ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù Keje ni Agbala Gabriel kéde pé mílíọ̀nù mẹ́ta náírà ni àwọn ti rí gbà fún òṣèré ọ̀hún.

Àmọ́ gbogbo ìgbìyànjú yìí ti dòfo báyìí bí àgbà òṣèré náà ṣe ti jẹ́ Ọlọ́run nípè.

Musiliu Ajikanle gbajúmọ̀ pẹ̀lú eré Mufu Olosha Oko tó ṣe pẹ̀lú Odunlade Adekola.