Ààrẹ Bọla Tinubu kéde ọjọ́ keje, oṣù kẹrin ọdún gẹ́gẹ́ bí àyájọ́ ọjọ́ àwọn ọlọ́pàá

Aworan Aare Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu/Facebook

Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu ti kede sita wi pe gbogbo ọjọ keje ninu oṣu kẹrin ọdun ni yoo maa jẹ ayajọ ọjọ awọn ọlọpaa lorilede Naijiria, lati fi mọ riri iṣẹ ti wọn n ṣe lori eto aabo.

Tinubu lo kede eyi nibi akanṣe eto awọọdu ti awọn ọlọpaa ṣagbekalẹ rẹ ni Trancorp Hilton to wa niluu Abuja lọjọ Aje to kọja yii.

Igbakeji Aarẹ, Kashim Shettima to ṣoju Aarẹ Tinubu sọ pe latigba toun ti gba ijọba lọdun 2023 ni iṣakoso oun ti bẹrẹ igbesẹ lori atunto ninu iṣẹ ọlọpaa.

O ni ijọba oun fẹ ki iṣẹ ọlọpaa Naijiria maa figagbaga pẹlu ti awọn orileede to ti laju daadaa.

Siwaju sii lo ni o ṣe pataki lati maa ṣe idanilẹkọọ loore-koore fun awọn ọkunrin ati obinrin lati le mọ ọna ti wọn yoo gba lati ṣiṣẹ eto aabo lọna igbalode.

Bẹẹ lo ni ijọba apapọ ti buwọ lu gbogbo ọsẹ akọkọ ninu oṣu kẹrin ọdọọdun gẹgẹ ọsẹ awọn ọlọpaa, ti ọjọ to kẹyin ninu ọsẹ naa yoo si jẹ ayajọ ọjọ awọn ọlọpaa, iyẹn ‘National Police Day’.

Ninu ọrọ rẹ, o ni “Ẹyin okunrin ati obinrin ti ẹ wa nibi, ninu ilana wa lati maa bọwọ fun iṣẹ ọlọpaa ninu igbesi aye orilede yii, a ti buwọ lu ọsẹ akọkọ ninu oṣu kẹrin ni yoo maa jẹ ọsẹ awọn ọlọpaa.

“Siwaju sii, ọjọ to kẹyin ninu ọsẹ akọkọ naa to jẹ ọjọ keje, oṣu kẹrin ti wa ni ayajọ ọjọ awọn ọlọpaa ni Naijiria.

“Ni aṣalẹ yii, mo ni lati ran yin leti wi pe kii ṣe pe a kan n rii yin gẹgẹ bi aabo fun ilẹ yii, a ko rii yin bii rọbọọti. Idi ree ti a fi wa nibi; a wa lati ma ṣe jẹ ki orukọ yin parẹ lailai ni.”