Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko yóò ṣí ọjà oúnjẹ ẹ̀dínwó káàkiri ìpínlẹ̀ náà lọ́la ọjọ́ ìsinmi

Aworan Babajide Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu/X

Gbogbo eto ni o ti to bayii fun ijọba ipinlẹ Eko lati ṣi ọja ounjẹ ẹlẹdinwo kaakiri ipinlẹ naa.

Kọmiṣọna eto iroyin ati ọgbọn inu, Gbenga Omotoso lo sọrọ yii loju opo X rẹ pe Gomina Babajide Sanwo-Olu ti paṣẹ pe ki ọja naa eyi ti wọn pe orukọ rẹ ni ‘’Ounjẹ Eko’’ di ṣiṣi lọjọ Aiku ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹta yii kaakiri ẹkun marun un ipinlẹ Eko.

Iru awọn ounjẹ tawọn eeyan ipinlẹ Eko yoo maa ri ra lawọn ọja naa ni ẹwa, irẹsi, burẹdi, ẹyin, timọ ati alubọsa ni owo ti ko gara.

Kọmiṣọna eto iroyin ṣalaye pe lati le jẹ ki eto naa lọ ni irọwọrọsẹ, awọn eeyan to ba fẹ ra nnkan yoo maa gba iwe pelebe tikẹẹti lati ra ọja.

O ni ijọba ti gba awọn ontaja to mọ nipa ounjẹ lati ṣe agbatẹru eto naa.

Iye ti wọn yoo maa ta ounjẹ kọọkan yoo wa lara awọn ounjẹ yii.

Baagi iwọn 5kg irẹsi ni wọn yoo maa ta ni N5,325 nigba ti 1kg rẹ yoo si jẹ N1,065.

N6,225 ni wọn yoo maa ta ẹwa iwọn 5kg nigba ti iwọn 1kg yoo jẹ N1,24.

Iye ti wọn yoo maa ta awọn ounjẹ yoku naa yoo di mimọ fawọn to ba fẹ ra ounjẹ naa.

Ọgbẹni Omotoso ṣalaye pe ọja yoo wa ni ibudo mẹtadinlọgbọn ni Ikeja, nigba ti ọja naa yoo wa ni ọna mẹfa ni agbegbe Lagos Island.

Ibudo mẹsan an ni irufẹ ọja yii yoo wa niluu Ikorodu, marun un niluu Epe, nigba tawọn eeyan yoo maa ri ounjẹ ra ni ibudo mẹwaa niluu Badagry.

Gomina Sanwo-Olu ti wa rọ awọn eeyan ipinlẹ Eko pe lati fọwọ sowọ pọ pẹlu awọn to wa nidi eto naa fun aṣeyọri rẹ.

Skip Twitter post

Allow Twitter content?

This article contains content provided by Twitter. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Twitter cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Twitter post

Content is not available

View content on TwitterBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.