Awọn obìnrin South Korea ń kọ̀ láti bímọ, kí ló fà á?

Yejin atawon ore re ninu ile

Oríṣun àwòrán, Jean Chung

  • Author, Jean Mackenzie
  • Role, Seoul correspondent

Ní ọ̀sán ọjọ́ Ìṣẹ́gun kan, Yejin ń dáná oúnjẹ fún àwọn ọ̀rẹ́ ní ilé rẹ̀ níbi tí ó ń dágbé ní ẹ̀bá Seoul.

Bí wọ́n ṣe ń jẹun lọ́wọ́ ni ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rẹ́ Yejin mú ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde tó sì fi àwòrán ẹranko “dinosaur” han àwọn yòókù rẹ̀ tí gbogbo wọn sì bú sẹ́rìn-ín.

Ohun tí dinosaur náà ń sọ ni pé “ṣọ́ra o, má jẹ̀ ẹ́ kí ìwọ náà lọ sókun ìgbàgbé bíi tèmi báyìí.”

Yejin, ẹni ọdún ọgbọ̀n tó jẹ́ òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ amóhùnmáwòrán ní ọ̀rọ̀ náà panilẹ́rìn-ín lóòótọ́ àmọ́ ó jìnlẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ nítorí ó ṣeéṣe kí àwọn máa fi ọwọ́ ara àwọn kọ ìparun àwọn ní tòótọ́.

Yejin àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kò gbèrò láti bí ọmọ kankan. Wọ́n wà lára ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin tí wọ́n ní àwọn kò fẹ́ bí ọmọ láyé.

Orílẹ̀ èdè South Korea ni iye àwọn ènìyàn tó ń bímọ ti kéré jùlọ ní àgbàyé, tí èyí sì ń peléke si ní ọdọọdún.

Tí èyí bá sì ń tẹ̀síwájú, ìrètí wà pé àwọn ènìyàn tí yóò wà ní South Korea tó ba fi máa di ọdún 2100 kò ní ju ìdajì iye àwọn ènìyàn tó wà níbẹ̀ báyìí lọ.

Ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì

Káàkìrì àgbàyé, àwọn orílẹ̀ èdè tó ti gòkè àgbà ti ń rí àdínkù ní bí àwọn ènìyàn ṣe ń bimọ́ àmọ́ kò pọ̀ tó ti South Korea yìí.

Tó bá fi máa tó àádọ́ta ọdún sí àsìkò tí a wà yìí, àwọn ènìyàn tó máa wà ní ọjọ́ orí tó lè ṣe iṣẹ́ kò ní ju ìdajì àwọn tó ń ṣiṣẹ́ báyìí lọ.

Iye àwọn tó ma lè ṣe iṣẹ́ ológun ní Korea ma ti dínkù pẹ̀lú ìdá méjìdínlọ́gọ́ta, tí ìdajì àwọn tó wàn ní orílẹ̀ èdè náà má ti lé ní ọdún márùndínláàdọ́rin.

Èyí jẹ́ ohun ìpèníjà fún ètò ọrẹ̀ ajé àti ètò ààbò orílẹ̀ náà tí àwọn olóṣèlú sì ti kéde “ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì” lórí rẹ̀.

Láti bí ogun ọdún sẹ́yìn ni ìjọba South Korea ti ń ná owó ribiribi tí iye rẹ̀ tó $286bn láti ri pé wọ́n kojú ìṣòro náà.

Àwọn tọkọtaya tí wọ́n bá bímọ ni ìjọba máa ń fún ní owó àtàwọn ẹ̀bùn lóríṣiríṣi ní oṣooṣù.

Bákan náàni wọ́n máa ń mú àdínkù bá owó ilé tí wọ́n máa san yàtọ̀ sí àwọn tí kò bímọ, tí wọ́n sì tún máa ń wọ ọkọ̀ ọ̀fẹ́ káàkiri ibi tí wọ́n bá ń lọ.

Bẹ́ẹ̀ náà ni wọn kìí san owó nílé ìwòsàn, tí wọ́n bá sì tún nílò iṣẹ́ abẹ láti fi bímọ ìjọba ni yóò ṣètò rẹ̀ àmọ́ àwọn tọkọtaya tó bá ṣe ìgbéyàwó nìkan ni àwọn àǹfàní yìí wà fún.

Àmọ́ pẹ̀lú gbogbo ìgbésẹ̀ ìjọba yìí síbẹ̀ àwọn ènìyàn Korea kọ̀ láti máa bímọ tí èyí sì ti ń mú kí ìjọba tún máa ronú àwọn ọ̀nà láti túnbọ̀ pèsè ìdẹ̀kùn fún wọn láti fẹ́ tún bímọ si bíi gbígba àwọn olùtọ́jú ọmọdé láti gúúsù ìlà oòrùn Asia tí wọ́n máa san owó fún láti bá àwọn ènìyàn tọ́jú ọmọ.

Wọ́n tún fi kun pé ọkùnrin tó bá fi lè ti ní ọmọ mẹ́ta kó tó di pé ó pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni kò ní pọn dandan fún-un láti darapọ̀ mọ́ iléeṣẹ́ ológun gẹ́gẹ́ bí òfin orílẹ̀ èdè.

Síbẹ̀ níṣe ni àwọn ènìyàn náà ní ìjọba kò tẹ́tí sí nǹkan tí àwọn ọ̀dọ́ ń fẹ́ pàápàá àwọn obìnrin. Èyí ló mú wa kàn sí àwọn obìnrin orílẹ̀ èdè yìí láti mọ ìdí rẹ̀ gan tí wọn kò fi fẹ́ máa bímọ.

Yejin ninu ile re

Oríṣun àwòrán, Jean Chung

Nígbà tí Yejin pinnu láti máa dá gbé nígbà tó wà ní ọmọ ogun ọdún ó lé díẹ̀, kò bìkítà lórí nǹkan tí àwọn ènìyàn yóò máa sọ nítorí kí obìnrin máa dá gbé kìí ṣe nǹkan tó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà bẹ́ẹ̀ ní Korea.

Ní ọdún márùn-ún sẹ́yìn ló pinnu pé òun kò ní fẹ́ ọkọ àti pè òun kò ní bímọ rárá.

“Ó ṣòro láti rí ọkùnrin tó ṣe é yàn lọ́rẹ̀ẹ́ ní Korea – ẹ máa nílò láti máa pín gbogbo nǹkan déédéé, tó fi dórí ìtọ́jú ọmọ.

“Wọn kìí sì fi ojú ire wo obìnrin tó bá bímọ láì sí nílé ọkọ.” Yejin sọ.

Ní ọdún 2022, àpapọ̀ àwọn ọmọ tí obìnrin tí kò sí nílé ọkọ bí ló jẹ́ ìdá méjì ní South Korea.

Iṣẹ́ ṣíṣe

Dípò ọmọ bíbí, Yejin gbájúmọ́ iṣẹ́ amóhùnmáwòrán tó yàn láàyò, ní èyí tó ní kò fún òun láàyè láti le ṣe ìtọ́jú ọmọ.

Ó ní aago mẹ́sàn-án àárọ̀ sí aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ ni ó yẹ kí òun máa lò lẹ́nu iṣẹ́ ṣùgbọ́n òun le má kúrò ní ibiṣẹ́ títí di aago mẹ́jọ alẹ́ ní ọjọ́ mìíràn àti pé ó ti máa rẹ òun nígbà tí òun bá máa fi délé.

“Mo nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ mi, ó máa ń fún mi ní gbogbo nǹkan tí mo fẹ́ àmọ́ iṣẹ́ ṣíṣe ní Korea le nítorí iṣẹ́ ni mo máa ń fi gbogbo ayé mi ṣe.”

Yejin fi kun pé nígbà tí òun kò bá ṣiṣẹ́, èrò láti kẹ́kọ̀ọ́ si ló máa ń ṣe òun nítorí òun nílò láti kẹ́kọ̀ọ́ si kí òun lè máa tẹ̀síwájú lẹ́nu iṣẹ́ òun àti pé ẹni tí kò bá kẹ̀kọ̀ọ́ si ni ó ṣeéṣe kó máa wà lẹ́yìn àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀.

“Ní òpin ọ̀sẹ̀ nígbà mìíràn mo máa ń lọ gba abẹ́rẹ́ láti lè ní okun láti padà sẹ́nu iṣẹ́ lọ́jọ́ Ajé.”

Ó ṣàlàyé tí òun bá gba ààyè lẹ́nu iṣẹ́ láti lọ bí ọmọ, ó ṣeéṣe kí òun má lè padà sẹ́nu iṣẹ́ mọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin tí BBC bá sọ̀rọ̀ ni àwọn náà ní irú èrò yìí.

“Ọ̀pọ̀ àwọn iléeṣẹ́ ló máa ń ní kí àwọn obìnrin fi iṣẹ́ sílẹ̀ tó bá filè bímọ. Ó ti ṣelẹ̀ sí abúrò mi àtàwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ méjì.”

Mo mọ ọ̀pọ̀ nǹkan

Stella ni kilaasi

Oríṣun àwòrán, Jean Chung

Obìnrin ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n kan tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ìgbanisíṣẹ́ ní òun ti rí bí wọ́n ṣe fi tipátipá mú ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin láti fi iṣẹ́ sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bímọ tán, tí wọn kò sì fún àwọn míì ní ìgbéga lẹ́yìn tí wọ́n gba ìsinmi láti lọ tọ́jú ọmọ.

Ọkùnrin àti obìnrin ló ní àǹfàní láti gba ìsìnmi ọdún kan lẹ́nu iṣẹ́ láti fi tọ́jú ọmọ nígbà tí ọmọ wọn kò bá ì tíì pé ọdún mẹ́jọ. Àmọ́ ní ọdún 2022, ìdá méje àwọn ọkùnrin ló gba ìsìnmi yìí, tí àwọn obìnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ tó gba ìsìnmi náà sì lé ní ìdá àádọ́rin.

Àwọn obìnrin Korea wà lára àwọn obìnrin tó ń kàwé púpọ̀ síbẹ̀ ìyàtọ̀ ńlá sì wà láàárín iye tí àwọn ọkùnrin àti obìnrin ń gbá.

Àwọn tó ń ṣe ìwádìí ní èyí tí ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ṣe máa ń gbájú mọ́ iṣẹ́ ju ọmọ bíbí lọ.

Stella, ẹni ọdún mọ́kàndínlógójì tó jẹ́ olùkọ́ ẹ̀kọ́ ìmọ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní ó wu òun àti ọkọ òun láti bi ọmọ kan péré láti ọdún mẹ́fà tí àwọn ti ṣe ìgbéyàwó àmọ́ iṣẹ́ kò fun òun láàyè láti bímọ.

Ó ní òun ti gbà pé òu kò lè bí ọmọ mọ́ nítorí kò sí àǹfàní fún òun láti bímọ pẹ̀lú iṣẹ́ tí òun ń ṣe.

“Ẹni tó bá fẹ́ bí ọmọ máa nílò láti fi iṣẹ́ sílẹ̀ fún ọdún méjì láti gbájú mọ ọmọ àmọ́ èmi kò lè ṣe èyí nítorí ó máa dá ìrònú sílẹ̀ fún mi nítorí mo nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ tí mò ń ṣe, mo sì fẹ́ tọ́jú ara mi.”

Èrò pé obìnrin máa nílò láti gba ààyè ọdún méjì sí Mẹ́ta kúrò lẹ́nu iṣẹ́ jẹ́ ohun ẹ̀rù fún ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin.

Stella ní tí òun bá ti ẹ̀ gbèrò láti fi iṣẹ́ sílẹ̀, tàbí kí òun máa ṣe méjéèjì papọ̀, òun kò ní lè ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí owó tí àwọn ń san ní owó ilé pọ̀ púpọ̀.

Aworan ilu Seoul

Oríṣun àwòrán, Jean Chung

Ìdajì àwọn èèyàn South Korea ló ń gbé ní Seoul tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀ èdè náà, tí ọ̀wọ́n gógó ilé níbẹ̀. Stella àti ọkọ rẹ̀ ti gbìyànjú láti kúrò láàárín ìgboro lọ máa gbé ètí ìlú síbẹ̀ wọn ò tíì ní àǹfàní láti ra ilé ti wọn.

Iye àwọn tó ń bímọ ní Seoul ló ti já wálẹ̀ sí ìdá 0.59 – èyí tó kéré jùlọ ní orílẹ̀ èdè náà.

Yàtọ̀ sí owó ilé, iye tí àwọn òbí ń ná lórí ẹ̀kọ́ fún àwọn ọmọ kò kéré rárá.

Láti ọdún mẹ́rin ni àwọn ọmọ ti ń kọ àlékún ìmọ̀ lórí ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìṣirò, èdè Gẹ̀ẹ́sì, orin àti Taekwondo tó sì jẹ́ pé àwọn ọmọ tí kò bá kẹ́kọ̀ọ́ yìí kò ní bá ẹgbẹ́ pé lórí ẹ̀kọ́ wọn.

Èyí jẹ́ kí orílẹ̀ èdè South Korea jẹ́ orílẹ̀ èdè tí owó tí àwọn òbí ń ná láti tọ́ ọmọ pọ̀ púpọ̀ jùlọ ní àgbàyé.

Ìwádìí kan níọdún 2022 fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìdá méjì àwọn òbí péré ni kò fi ọmọ wọn sí ilé ẹ̀kọ́ aládàni ní ọ̀pọ̀ wọn sì kọminú lórí iye tí wọ́n ń san fún ètò ẹ̀kọ́ náà.

Gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí, Stella ní gbogbo ipa tí ọmọ títọ́ ní ló yé òun, tí òun sì mọ̀ pé ọ̀pọ̀ òbí ló ń ná ó kéré tán $890 lórí ẹ̀kọ́ ọmọ kan ní oṣù kan èyí tí ọ̀pọ̀ ènìyàn kó lágbára rẹ̀.

Ó ní tí òun bá wà pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ òun ọmọ bíní máa ń wu òun àmọ́ gbogbo àwọn ìṣòro tó rọ̀ mọ́ lọ yé òun.

Omo kan ni kilaasi

Oríṣun àwòrán, Jean Chung

Ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń kó ìrònú bá èèyàn

Jungyeon ati ọmọ re

Oríṣun àwòrán, Jean Chung

Ní ìlú Daejon, Jungyeon Chun ní òun nìkan ni òun dá tọ́ àwọn ọmọ nínú ìgbéyàwó òun. Lẹ́yìn tó bá ti mú àwọn ọmọ tán ní ilé ẹ̀kọ́, wọ́n máa ń lọ ṣeré ní ọggbà káàkiri títí tí ọkọ̀ rẹ̀ ma fi dé láti ibi iṣẹ́.

Jungyeon ní òun rò wí pé òun ma tètè lè padà sí ẹnu iṣẹ́ lẹ́yìn tí òun bá ti bímọ tán ni àmọ́ ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ nítorí ọkọ rẹ̀ kìí tètè délé láti ràn-án lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ilé àti ọmọ títọ́.

Láti bíi àádọ́ta ọdún sẹ́yìn ni àyípadà ti ń bá ètò ọrọ̀ ajé Korea èyí tó ń mú kí àwọn obìnrin máa kàwé si àti láti túnbọ̀ máa lékún iṣẹ́ wọn.

Jungyeon ní nígbà tí òun ri pé òun nìkan kọ́ ni inú òun kò dùn lórí ọ̀rọ̀ ọmọ títọ, ni òun tó mọ̀ pé ìṣòro àwùjọ àwọn ni.

Jungyeon atawọn ọmọ re

Oríṣun àwòrán, Jean Chung

Ó ṣàlàyé pé èyí lo mú òun láti máa fi àwọn ìrírá àtàwọn nǹkan tó bá ń wá sí òun lọ́kàn ya àwòrán tí òun sì ń fi sórí ayélujára.

Ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin orílẹ̀ èdè rẹ̀ ló mọ rírì àwọn nǹkan tó fi ń ya àwòrán, tó sì ti ṣe ìwé mẹ́ta jáde.

Ó ní òun ti la ipele tí inú ti máa ń bí òun kọjá, tó sì máa ń wu òun pé òun mọ̀ nípa àwọn nǹkan tí ọmọ bíbí máa fa àti pé kí ní àwọn nǹkan tó yẹ kí ìyá ọmọ máa ṣe tipẹ́tipẹ́ ṣáájú àkókò yìí.

Ó fi ku ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìdí tí àwọn obìnrin ko fi fẹ́ bímọ ni pé wọ́n ti ní ìgboyà láti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ àmọ́ ó ní ó ṣeni láàánú pé àwọn obìnrin náà kò ní mọ adùn tó wà nínú jíjẹ́ òbí nítorí àwọn ìṣòro tí wọ́n máa kojú lẹ́yìn ìbímọ.

Mo lè bí ọmọ mẹ́wàá tó bá ṣeeṣe

Padà ní ilé Yejin, lẹ́yìn oúnjẹ ọ̀sán, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ń dá ìwé rẹ̀ padà fun àtàwọn ẹrù rẹ̀ míì.

Yejin ní òun ti pinnu láti kúrò ní Korea lọ sí New Zealand nítorí ìgbé ayé Korea ti sú òun àti pé kò sí ẹni tó ní kí òun máa gbé Korea ní dandan.

Ó ṣàlàyé pé nígbà tí òun ṣe ìwádìí àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n ń ṣe dédé láàárín akọ àti abo ni òun ri pé New Zealand ló lé téńté, tó sì jẹ́ pé iye kan náà ni wọ́n máa ń san fún ọkùnrin àtobìnrin níbẹ̀.

Akọ̀ròyìn BBC ní òun bèèrè lọ́wọ́ Yejin àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ bóyá wọ́n le yí ìpinnu rẹ̀ padà lórí ọmọ bíbí, Minsung fèsì pé ó wu òun láti bímọ àmọ́ òun jẹ́ ẹni tó máa ń ní ìbálòpọ̀ abosábo.

Minsung, Yeijin ati ore won miiran

Oríṣun àwòrán, Jean Chung

Ìgbéyàwó akọsákọ tàbí tàbí abosábo jẹ́ ohun tó lòdì sí òfin South Korea, tí kò sí fààyè gba àwọn obìnrin láti gba àtọ̀ ọkùnrin láti fi lóyún.

Minsung ní òun lérò pé òfin náà yóò yípadà lọ́jọ́ kan, tí òun yóò lè ṣègbéyàwó pẹ̀lú ẹni tí òun nífẹ̀ẹ́, tí òun yóò sì lè bí ọmọ tòun.

Àwọn ọ̀rẹ́ Yejin ní ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin tí wọ́n fẹ́ bí ọmọ ni òfin orílẹ̀ èdè àwọn kò fi ààyè sílẹ̀ fún láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Àmọ́ ó jọ wí pé ìjọba ti ń rí bí ọ̀rọ̀ ọmọ bíbí náà ṣe ti burú tó.

Ààrẹ South Korea, Yoon Suk Yeol ní gbogbo àwọn ìgbésẹ̀ àti ìlànà tí àwọn gbé láti kojú ìṣòro náà ni kò so èso rere àti pé ó nílò àmójútó tó péye.

Ó ní àwọn máa kojú ìṣòro náà lọ́nà mìíràn àmọ́ àwọn kò ì tíì mọ ọ̀nà tí àwọn máa gbe gbà.