Ìjọba àpapọ̀ díde ìrànlọ́wọ́ fún àwọn tó fara gbá nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi Kwara

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu

Aarẹ Bola Tinubu ti ba ijọba ipinlẹ Kwara kẹdun lẹyin ijamba ọkọ oju omi to mu ẹmi eeyan to le lọgọrun lọ nibẹ.

Tinubu tun ti paṣẹ ki wọn ko nnkan iranwọ lọ fun awọn to moribọ ninu iṣẹlẹ naa atawọn mọlẹbi awọn to di oloogbe.

Atẹjade kan lati ọọfisi agbẹnusọ Aarẹ, Abiodun Oladunjoye, sọ pe ijamba ọhun ba Aarẹ ninu jẹ gidi.

Aarẹ ti wa paṣẹ fun ijọba ipinlẹ kwara lati ṣe iwadii ohun to ṣokunfa ijamba naa ni kankan.

Iroyin ni ibi ayẹyẹ kan lawọn eeyan ọhun ti n bọ ni ijọba ibilẹ Patigi ṣaaju iṣẹlẹ ọhun.

Lara awọn to ba iṣẹlẹ naa kan ni ọkunrin kan to wa pẹlu awọn ọmọ rẹ mẹrin, ko si sẹni to mọ ipo ti wọn wa bayii.

Aarẹ tun ṣeleri lpe ijọba apapọ yoo ṣe iwadii nipa irianjo oju omi ni Naijiria lati ri daju pe awọn to n wa ọkọ oju omi naa ṣe bẹẹ ni ilana to ba ofin mu ati eyii ti ko ni fi ẹmi araalu ṣofo.

Èèyàn 150 kú lásìkò tí wọ́n n bọ̀ láti ibi ayẹyẹ ìgbeyàwó ní Kwara

Awọn to ni ijamba ọkọ oju omi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba ipinlẹ Kwara ti fidirẹmulẹ pe aadọjọ eeyan lo kú ninu ijamba ọkọ oju omi kan to waye ni owurọ ọjọ Aje, ni ijọba ibilẹ Patigi.

Ọkọ oju omi naa ni iroyin sọ pe o gbe ọọdunrun ero to n bọ̀ lati ibi ayẹyẹ igbeyawo kan , ko to o di pe ọkọ wọn danu sinu omi ni nnkan bi aago mẹta oru.

Wọn ni ijamba naa waye nitori bi ẹnjinni ọkọ oju omi naa ṣe bajẹ lori omi.

Abule Egbu, ni ijọba Patigi ni ijamba naa ti waye, amọ abule Egboti ni ipinlẹ niger ni awọn eeyan naa ti lọ ṣe igbeyawo.

Emir ilu Patigi, Alhaji Ibrahim Umar Bologi, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe eeyan mẹtalelaadọta ni wọn ri doola, aadọjọ kú, aadọrun si di awati.

Abule Ebu, Dzakan, Kpada, Kuchalu ati Sampi, ti gbogbo rẹ wa ni ijọba ibilẹ Patigi, ni awọn eeyan to wa ninu ijamba naa n gbe.

Alhaji Bologi sọ pe awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi ṣi n wa awọn eeyan to sọnu.

Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe waye?

Kwara boat accident

Oríṣun àwòrán, @DonaldRex

“Gẹgẹ bii iroyin ti a gbọ, ẹrọ ọkọ oju omi naa ti nnkan bii ọọdunrun eeyan wa ninu rẹ lo ṣadede kọṣẹ.”

“A ti bẹrẹ si n ṣe ilanilọyẹ fun awọn eeyan wa bayii lati mọ iye ero to yẹ ko wa ninu ọkọ oju omi lẹẹkan ṣoṣo, a tun n rọ ijọba ki wọn fun wa ni awọn aṣọ to le mu eeyan lefo sori omi.”

Ijọba Kwara kẹdun awọn to jade laye

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Kwara ti ba awọn eeyan ipinlẹ naa kẹdun lẹyin iṣẹlẹ laabi yii.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ gomina AbdulRahman AbdulRazaq, iyẹn rafiu Akajaye fi lede, o ni iṣẹlẹ naa ba ijọba ninu jẹ gidi.

O ni “Inu gomina bajẹ gidi nipa ijamba ọkọ oju omi to danu eyii ti ọpọ eeyan wa ninu rẹ, paapaa awọn eeyan Ebu, Dzakan, Kpada, Kuchalu, ati Sampi, ti gbogbo wọn jẹ eeyan Patigi.”

“Gomina ba awọn eeyan agbegbe ọhun kẹdun, to fi mọ awọn mii ti ọrọ naa kan lati ipinlẹ miran.”