K1 rawọ́ ẹ̀bẹ́ ránṣẹ́ sí Tinubu lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho

Wasiu Ayinde Marshall ati Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Collage

Gbajumọ akọrin Fuji, Wasiu Ayinde Marshal ti ọpọ mọ si K1 the Ultimate ti ke si aarẹ orilẹede Naijiria, Bọla Ahmed Tinubu pe ko jawe orijin lori ọrọ Oloye Sunday Igboho.

Sunday Igboho to jẹ ọkan gboogi lara awọn aṣiwaju ẹgbẹ to n pe fun ominira ilẹ Yoruba ti wa latipo lorilẹede Benin Republic lati oṣu keje ọdun 2021.

Sunday Igboho sa kuro ni Naijiria, pẹlu ero gba ati lọ si orilẹede Germany lẹyin ti ijọba apapọ labẹ Aarẹ ana, Muhammadu Buhari fi ẹsun kan oun at’awọn ọmọlẹyìn rẹ pe wọn n gbero ati fi ipa doju ijọba bolẹ labẹ iboju Yoruba Nation.

https://www.bbc.com/yoruba/afrika-54363735

Lẹyin eyi ni ọwọ awọn agbofinro to tẹ Igboho ni orilẹede Benin

K1, ẹni to tun jẹ Mayegun ti ilẹ Yoruba rawọ ẹbẹ yii ninu orin kan to kọ eyi to fi n fọnrere alaafia lorilẹede Naijiria.

Ipe ti K1 pe yii jẹ eyi ti ọpọ karamasiki pupọ julọ nitori ajọṣepọ to wa laarin oun ati aarẹ tuntun lorilẹede Naijiria, Bọla Ahmed Tinubu.

Ni ọjọ kini oṣu keje ọdun 2021 ni awọn agbofinro ileeṣẹ DSS lorilẹede Naijiria kọlu ile Sunday Igboho ni ilu Ibadan nibi ti wọn ti ko ọpọ awọn ọmọlẹyìn rẹ, ṣugbọn ti Igboho funrararẹ sa asala.