Agbébọn jí èèyàn mẹ́ta ní Osun, bèèrè mílíọ̀nù márùn-ún náírà owó ìtúsílẹ̀

Aworan awọn agbebọn

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn agbebọn kan ti ji ẹniyan mẹta gbe ni ilu Iwo ti o wa ni ijọba ibilẹ Iwo ni ipinlẹ Osun.

Ti  Wọn si ti beere fun miliọnu marun naira idasilẹ wọn.

 Awọn agbebon na ni won ṣiṣẹ ijinigbe naa lọjọ eti  to koja yii, oruko awọn ti wọn jigbe gẹgẹ bi ọlọpa ipinlẹ Osun ti so ni Hamzat Ibrahim, Deere Ibrahim ati okunrin eni odun mejidinlogoji (38) ti won ko tii da oruko e.

 A gbo pe wọn ji wọn gbe ni inu oko wọn to wa ni agbegbe Ologun nijoba ibile iwo.

 Okan lara awon ode ni ipinle naa nigba to n ba awon onkoroyin soro ni Osogbo so pe, “Fulani ni awon ti won ji gbe, oko ni won wa nigba ti awon ajinigbe naa de.” Ode na so pe awon ajinigbe naa ti kan si awon molebi ti won si beere fun milliọnu marun naira.

  Nigba ti o n fidi isẹlẹ naa mulẹ, agbenusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Iyaafin Yemisi Opalola, sọ pe Hamidat Ibraheem kan lo fi isẹlẹ naa to ile ise  ọlọpaa ni ipinlẹ naa.

 O ni, “Awon agbebon naa ji Hamzat Ibrahim, Deere Ibrahim ati okunrin eni odun mejidinlogoji (38) gbe. 

Yemisi ni awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ Ọlọpa ati awọn  ode ati awọn ile-iṣẹ to risi  aabo agbegbe miiran n ṣajọ igbo lati dola ẹmi  awọn ti wọn jigbe naa.